Diana Yekinni

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Diana Yekinni
Ọjọ́ìbíDiana Yekinni
London, Peckham England, U.K
Orílẹ̀-èdèBritish Nigerian
Iléẹ̀kọ́ gíga
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́2009–present

Diana Yẹ̀kínnì jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ọmọ orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì tó gbajúmọ̀ jùlọ fún àwọn ipa rẹ̀ nínu fíìmù bíi Ije àti Lunchtime Heroes. Diana tún gbajúmọ̀ fún kíkó ipa Genevieve nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Jenifa's Diary ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Fúnkẹ́ Akíndélé.[1] Ní ọdún 2014, wọ́n yàán fún àmì ẹ̀yẹ ti "Òṣèré tí ó ní ìlérí jùlọ" níbi ayẹyẹ Golden Icons Academy Movie Awards ti ọdún 2014.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Diana Yẹ̀kínnì, ó sì dàgbà sí Ìlú Lọ́ndọ̀nù, Ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì.[3] Ó gba oyè-ẹ̀kó láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga American Academy of Dramatic Arts, èyí tí ó wà ní ìlú Los Angeles, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ti kọ́kọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ eré ìtàgé tẹ́lẹ̀rí ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga BRIT School for Performing Arts and Technology.[4]

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òsèré rẹ̀ ní ọdún 2009 nígbà tí ó fi kópa nínu eré tẹlifíṣọ̀nù ti Amẹ́ríkà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Medium. Ní ọdún 2010, ó kópa gẹ́gẹ́ bi Libby nínu fíìmù Ijé àti gẹ́gẹ́ bi Odele nínu fíìmù Mosa. Ní ọdún 2012, Yẹ̀kínnì kópa tó sì jáwé olúborí nínu ẹ̀dà àkọ́kọ́ ti ìdíje GIAMA Screen Icon Search tí ó wáyé ní ìlú Houston, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.[5] Ó gbéra láti wá máa gbé ní Nàìjíríà ní ọdún 2012. Láti ìgbà náà ló ti wá ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eré tẹlifíṣọ̀nù àti sinimá àgbéléwò ti Nàìjíríà, lára wọn ni A New You, All That Glitters, Saro: The Musical, Jenifa's Diary, Lagos Cougars àti Lunch Time Heroes.[1][6][7]

Àkójọ àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fíìmù
Ọdún Fíìmù Ipa Àwọn àkọsílẹ̀
2016 DRAFTS as Molly Stage drama
2015 Lunch Time Heroes as Banke Adewummi Feature film
Jenifa's Diary as Genevieve Television series
2014 For Coloured Girls Who Have Considered Suicide as Lady in blue Stage drama
London Life, Lagos Living as Cast
Secret Lives of Baba Segi's Wives as Nurse
2013 A New You as Chantelle Film
Lagos Cougars
2010 Ijé as Libby Feature film
Mosa as Odele Film
2009 Medium as Jane Doe appeared in Episode 5.11 & 5.12

Àwọn ìyẹ́sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Ayẹyẹ Àmì ẹ̀yẹ Èsì Ìtọ́kasí
2014 2014 Golden Icons Academy Movie Awards Most Promising Actress Wọ́n pèé [8]
2014 City People Entertainment Awards Most Promising Act of the Year Wọ́n pèé [9]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "Diana Yekinni: 5 things you probably don't know about actress". Pulse Nigeria. 28 August 2015. http://pulse.ng/movies/diana-yekinni-5-things-you-probably-dont-know-about-actress-id4113047.html. Retrieved 2 August 2016. 
  2. "GHANAIAN STARTS NOMINATED FOR GOLDEN ICONS ACADEMY MOVIE AWARDS". H&F Magazine. 8 August 2014. Retrieved 2 August 2016. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  3. "I will still act at age 85 - Nollywood actress". Ghana Web. 12 July 2016. Retrieved 2 August 2016. 
  4. "Diana Yekini: Playing a raised game in Nollywood". 9 July 2016. http://m.guardian.ng/saturday-magazine/diana-yekini-playing-a-raised-game-in-nollywood/. Retrieved 2 August 2016. 
  5. "Biography/Profile/History Of Nollywood Actress Diana Yekinni". Daily Mail. 17 March 2016. http://dailymail.com.ng/biographyprofilehistory-nollywood-actress-diana-yekinni/. Retrieved 2 August 2016. 
  6. "Sodas & Popcorn – Movie Review: Lagos Cougars". BellaNaija. 18 December 2013. https://www.bellanaija.com/2013/12/sodas-popcorn-movie-review-lagos-cougars/. Retrieved 2 August 2016. 
  7. "Diana Yekini, Dakore Akande, Omoni Oboli in new movie titled "Lunch Time Heroes"". Ebonylife TV. 31 August 2015. http://ebonylifetv.com/2015/08/31/diana-yekini-dakore-akande-omoni-oboli-in-new-movie-titled-lunch-time-heroes/. Retrieved 2 August 2016. 
  8. "GHANAIAN STARTS NOMINATED FOR GOLDEN ICONS ACADEMY MOVIE AWARDS". H&F Magazine. 8 August 2014. Retrieved 2 August 2016. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  9. Oyewusi, Siji (24 June 2014). "Who won what at City People Entertainment Awards 2014". Nigerian Entertainment Today. http://thenet.ng/2014/06/who-won-what-at-city-people-entertainment-awards-2014/. Retrieved 2 August 2016.