Ebute Metta

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Máàpù 1962 tí ó ń ṣe àfihàn Ebute Metta ní Gúúsù.
Ìjúwe ọ̀nà ní Ebute Metta
Ilé tí wọ́n kọ sí Ebute Metta.

Ebute Metta jẹ́ agbèègbè ìlú èkó, ní Ìpínlẹ̀ Èkó, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Orúkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ebute Metta jẹ́ ọ̀rọ̀ Yorùbá fún ibi tí ó jẹ́ etí òkun mẹ́ta.[1] Ebute túmọ̀ sí etí òkun tí meta sì túmọ̀ sí mẹ́ta

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n mọ Ebute Metta sí ṣíṣètò oúnjẹ àti àwọn aṣọ. Ó jẹ́ ibìkan ní ìlú èkó tí ó ti wà tipẹ́,ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé tí ó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti kọ́ ní ìgbà ìletò àkọ́kọ́, tí wọ́n sì kọ́ àwọn ilé tí ó wà níbẹ̀ bi èyí tí ó wà ní orílẹ̀ èdè Brazil. Àwọn àyíká rẹ̀ ni ilé ìjọsìn St Jude àti ilé ìwé African Salem School àti ilé ìjọsìn Salvation Army. Gbọ̀gán Lisabi  jásí àyíká Okobaba àti ọ̀sà.

Àwọn ilé tí ó wà níbẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ebute Metta ní àwọn ilé tí ó lókìkí àti olúilé iṣẹ́ Nigerian Railway Corporation, ilé ìfìwé ránṣẹ́, ilé ìjọsìn St Paul's Catholic, ọjà òyìngbò Oyingbo, ibùdó ọkọ̀, Foucos Secondary School (ilé ìwé tí mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ tẹ́lẹ̀ kọ́), St. Saviour's School,[2] Junior Strides Academy, Ajayi Memorial Hospital, Ebute Metta Health Centre,[3][4] àti àwọn ilé ìtajà oríṣiríṣi. Ebute Metta pín sí méjì: Ìlà-oòrùn àti ìwọ oòrùn.

Ìgbòkègbodò ọkọ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ebute Metta jẹ́ ọ̀nà kan tí ó jásí erékùṣù mẹ́ta tí  Victoria, Ikoyi àti  erékùṣù èkó. Ó tún jẹ́ ọ̀nà kan tí ó já sí àwọn agbègbè kan bí ènìyàn bá ń wa ọkọ̀ láti Iddo.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Aderinto, S.; Osifodunrin, P. (2013). The Third Wave of Historical Scholarship on Nigeria: Essays in Honor of Ayodeji Olukoju. Cambridge Scholars Publisher. p. 312. ISBN 9781443847124. https://books.google.co.uk/books?id=FscwBwAAQBAJ&pg=PA312. Retrieved 2015-12-01. 
  2. AVANTVIEW Solutions Limited - www.avantview.com. "St. Saviour's School, Ebute Metta, Lagos". stsavioursebutemetta.org. Retrieved 2015-12-01.  More than one of |accessdate= and |access-date= specified (help)
  3. "Ebute Metta Health Centre". lagosstateministryofhealth.com. Archived from the original on 2015-12-08. Retrieved 2015-12-01.  More than one of |accessdate= and |access-date= specified (help)
  4. "Anxiety mounts over healthcare delivery at FMC Ebute Metta...Union insists on CMD’s removal - Vanguard News". vanguardngr.com. Retrieved 2015-12-01.  More than one of |accessdate= and |access-date= specified (help)

Àwọn ìjápọ̀ látìta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ibi tí ó ní ṣe pẹ̀lú Ebute Metta ní Wikimedia Commons