EkoEXCEL
Ìrísí
EkoEXCEL jẹ́ ìlànà ètò Ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun tí Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́dún 2020 nípa lílo ẹ̀rọ Ìléwọ́ kọ̀m̀pútà fún ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ìwé àkóbẹ̀rẹ̀. [1]. Ó jẹ́ ètò ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìṣèjọba Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó, Babájídé Olúṣọlá Sanwó-Olú ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ lọ́dún 2020. Nínú ìlànà Ekoexcel yìí, gbogbo àwọn olùkọ́ ni ilé ìwé àkóbẹ̀rẹ̀ ni Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó tí pín ẹ̀rọ Ìléwọ́ kọ̀m̀pútà fún láti kómọ lẹ́kọ̀ó.[2] Nínú ẹ̀rọ yìí, gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti ìlànà bí wọn yóò ti kọ́ wọn ti wà nínú rẹ̀.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ekoexcel: We’ll continue massive investments in education sector – Sanwo-Olu". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2020-01-26. Retrieved 2020-01-27.
- ↑ "The A,B,C of EkoEXCEL - The Nation Newspaper". The Nation Newspaper (in Èdè Latini). 2019-12-12. Retrieved 2020-01-27.
- ↑ "EKO EXCEL: Lagos begins training of 2,400 primary school teachers". P.M. News. 2019-12-09. Retrieved 2020-01-27.