Eku Edewor
Eku Edewor | |
---|---|
Edewor during a photo shoot for Genevieve magazine in July 2014 | |
Ọjọ́ìbí | Georgina Chloe Eku Edewor-Thorley 18 Oṣù Kejìlá 1986[1] London, United Kingdom |
Orílẹ̀-èdè | British Nigerian |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nigerian British |
Ẹ̀kọ́ | Warwick University, New York Film Academy |
Iṣẹ́ | Actress, television presenter, model |
Ìgbà iṣẹ́ | 2007-present |
Àwọn ọmọ | 1 |
Parent(s) | Juliana Edewor (mother) Hugh Thorley (father) |
Georgina Chloe Eku Edewor-Thorley, tí a mọ̀ sí Eku Edewor (ọjọ́ìbí: 18 Oṣù Kejìlá, Ọdún 1986), jẹ́ òṣèrébìnrin, atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù àti afẹwàṣiṣẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì. Ó gbajúmọ̀ fún iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi atọ́kùn ètò tẹlifíṣọ̀nù kan táa pè ní 53 Extra, èyí tí ó maá n jẹ́ gbígbé sáfẹ́fẹ́ lóri ìkànnì Africa Magic .
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Edewor àti ìkejì rẹ̀ Kessiana ní Ilé-ìwòsàn Portland ní Ìlú Lọ́ndọ̀nù. Ìyá rẹ̀ tí n ṣe Juliana Edewor jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà.[2] Bàbá rẹ̀ náà tí orúkọ rẹ̀ n ṣe Hugh Thorley, jẹ́ ará Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sí.[3] Àwọn òbí Edewor kọrawọn sílẹ̀ nígbàtí ó wà lọ́mọdé, àwọn méjèjì sì tún ìgbeyàwó ṣe pẹ̀lú ẹlòmíràn. Ọkọ tí ìyá rẹ̀ padà fẹ́ ti di olóògbé.[4]
Edewor dàgbà ní Nàìjíríà àti Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì. Ó gbé ní ìlú Èkó títí ó fi pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, níbi tí ó ti ní ètò-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti ilé-ìwé St. Saviour's School àti ilé-ìwé Grange School.[5] Lẹ́hìn náà Edewor padà sí Ilẹ̀gẹ̀ẹ́sì, níbi tí ó ti lọ sí ilé-ìwé Benenden School for Girls.
Edewor gba oyè-ẹ̀kọ́ ní ọdún 2008 nínu ìmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti eré ìtàgé láti Warwick University tó wà ní ìlú Coventry.[6] Lẹ́hìn náà, ó kẹ́kọ̀ọ́ eré fíìmù ṣíṣe fún oṣù mẹ́ta ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga New York Film Academy ní ọdún 2009.[7]
Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Edward kọ́kọ́ ṣàfihàn nínu tẹlifíṣọ̀nù ní ọdún 2006 nígbà tí ó fi díje níbi Britain’s Next Top Model.[8] Ó kópa nínu àwọn sinimá àgbéléwò ní àkókó ìgbà tí ó n kàwé lọ́wọ́.Ó kópa nínu fíìmù ọdún 2010 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Sex & Drugs & Rock & Roll.[9]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2017-04-17. Retrieved 2020-11-22.
- ↑ Okon, Anna. "My Style Changes Daily - Eku Edewor." Punch. 10 February 2013. 24 September 2014. "Archived copy". Archived from the original on 1 September 2014. Retrieved 24 September 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Okafor, Onnaedo. "5 Things You Didn't Know About Eku Edewor." Pulse.ng. 29 August 2014. 1 December 2014.
- ↑ "Eku Edewor: Nigerian men are very good at making big romantic statements." Nigeria News. 13 December 2013. 1 December 2014.
- ↑ Okon, Anna. "My Style Changes Daily - Eku Edewor." Punch. 10 February 2013. 24 September 2014. "Archived copy". Archived from the original on 1 September 2014. Retrieved 24 September 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Okon, Anna. "My Style Changes Daily - Eku Edewor." Punch. 10 February 2013. 24 September 2014. "Archived copy". Archived from the original on 1 September 2014. Retrieved 24 September 2014. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Eku Edewor." Africa Magic. 24 September 2014
- ↑ Omionawele, Joan. "The kind of man I want is...-Eku Edewor." Nigerian Tribune. 1 March 2014. 24 September 2014. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 26 October 2014. Retrieved 22 November 2020. .
- ↑ Sex & Drugs & Rock & Roll Full Cast & Crew. IMDb. 24 September 2014.