Eleanor Nwadinobi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Eleanor Nwadinobi jẹ́ Dókítà alábẹ́rẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ajà fún ètò ìlera tó péye fún àwọn obìnrin.[1][2] Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tí a kọ́kọ́ yàn gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Medical Women International Association.[3][4]

Ìpìlẹ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bàbá Eleanor jẹ́ ọmọ Ìpínlẹ̀ Ábíá, Nàìjíríà, ìyá rẹ̀ sì wá láti orílẹ̀-èdè Jamaica. Àwọn méjèèjì pàdé ní London nígbà tí bàbá rẹ̀ ń kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ti àwọn ẹranko ní Yunifásítì ti London àti tí ìyá rẹ̀ ń kó nípa iṣẹ́ Núrsì.

Eleanor lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé nítorí iṣẹ́ tí bàbá rẹ̀ ń ṣe àti nítorí ìjà abẹ́lé Nàìjíríà. Ó lọ ilé ìwé Queen’s School, Enugu; Saint Louis Grammar School, Ibadan; àti International School, Yunifásitì ìlú Ibadan. Ó kàwé gboyè nínú ìmò ìṣègùn òyìnbó ní Yunifásítì ilẹ̀ Nàìjíríà. Ó tẹ̀síwájú láti gba àmì-ẹ̀yẹ master’s degree nínú ìmọ̀ ètọ́ ọmọ ènìyàn ní European Inter-University Centre, Venice, Italy.[5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Eleanor Nwadinobi, fighting for Nigerian women’s rights to health and protection". www.who.int (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-11. 
  2. Adegun, Aanu (2020-03-10). "Buhari receives president of international women organisation". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-11. 
  3. "Doctors protest stripping of colleague naked in Abuja". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-11. 
  4. Omotayo, Joseph (2020-03-09). "Nigerian Nwadinobi is head of 100-yr-old int'l group fighting for women's rights". Legit.ng - Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-11. 
  5. "I was charmed by my husband’s focus, humility–Nwadinobi, Medical Women’s International Association President-elect". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-03-11.