Eniola Ajao
Eniolá Àjàó | |
---|---|
Ọmọ orílẹ̀-èdè | Nàìjíríà |
Iléẹ̀kọ́ gíga | Yunifásítì ìlú Èkó |
Iṣẹ́ | òṣeré tíátà |
Eniolá Àjàó jẹ ọmọ orilẹ-èdè Nàìjíríà , òṣeré tíátà ni, ìlú Ẹ̀pẹ́ ni ó ti wá, ó sì ti kópa nínú fíìmù tí ó lé ní márùndínlọ́gọ́rin ní iye. A dáa mọ̀ gẹ́gẹ́bí òṣeré nípa bí ó ṣe ma ń fi ọgbọ́n-inú àti òye hàn nígbà tí ó bá ń kópa nínú eré .[1]
Ìgbé ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹniọlá àti ìbejì rẹ̀ ni àbígbẹ̀yìn nínú àwọn ọmọ mẹ́fà tí àwọn òbí rẹ̀ bí. Nígbàtí o ń dàgbà, Ẹniọlá lọ sí Ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Máíkẹ́lì Mímọ́ ti Ìjọ Àǹgílíkàn, ati ilé-ẹ̀kọ́ girama tí àwọn Ológun ni ìlú Ẹ̀pẹ́. Gẹgẹbi Ẹniọlá ti sọ ọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wù ú láti mú orí àwọn òbí rẹ̀ wu, sibẹ̀, ìfẹ́ inú rẹ̀ ni láti jẹ́ òṣèré tíátà lati ìgbà èwe rẹ̀. Ẹniọlá tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbàtí ó lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ Ìmọ̀-ẹ̀rọ ní Yaba àti Ilé-ìwé -Yunifásítì ìlú Èkó níbi tí ó ti gboyè nínú imọ̀ Ìṣirò. [2] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ̀lọpọ̀ awuyewuye ti wáyé lórí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin Ẹniọlá àti Ọdúnladé Adékọ́lá, Ẹniọlá ṣàlàyé pé kò sí ìbáṣepọ̀ mìíràn láàrin òun àti Ọdúnladé Adékọ́lá lẹ́yìn ti iṣẹ́. [3]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "See 3 Popular Yoruba Actresses You Don’t Know Are Twins (Photos) » Naijaloaded". Naijaloaded | Nigeria's Most Visited Music & Entertainment Website. 2019-05-18. Retrieved 2019-10-27.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Kabir, Olivia (2018-12-17). "Top facts from biography of actress Eniola Ajao". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-10-27.
- ↑ Nigeria, Information (2018-03-19). "Actress, Eniola Ajao shares adorable photo with her “husband” (Photo)". Information Nigeria. Retrieved 2019-10-27.