Esther Igbekele

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Esther Igbekele jẹ́ gbajúmọ̀ olórin ẹ̀sìn ọmọ-lẹ́yìn-Jésù Ọmọ bíbí ìlú Ifọ́n, ìjọba ìbílẹ̀ Ọsẹ́Ìpínlẹ̀ Òndó lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1] Ó jẹ́ ọmọ bíbí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, Olúwafẹ́mi Ìgbẹ́kẹ̀lé, ṣùgbọ́n tí ó gbé lọ́dọ̀ òjíṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn tí orúkọ wọn ń jẹ́ Àpọ́sítélì J. A. Bánkọ́lé.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ lọ́dún 1996,[3] bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọmọ ọdún mẹ́rin ni ó ti nífẹ̀ẹ́ sí orin kíkọ. Ó tí gba àmìn-ẹ̀yẹ nínú iṣẹ́ orin yìí.

Ìgbésí ayé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Esther sí Orílé-ÌgànmúÌpínlẹ̀ Èkó, sí ìdílé Olùṣọ́ Àgùntàn, Olúwafẹ́mi Ìgbẹ́kẹ̀lé àti aya rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ nípa dídara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin ilé-ìjọsìn wọn nígbà tí ó wà ní ọmọdún mẹ́fà. Ọdún 1996 gan-an ní ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin ní àkọ̀tun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwo orin sìn ní ó ti gbé jáde.

Esther bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ní ilé-ìwé Central Primary school, ní Orílé-Ìgànmú ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Bákan náà, ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Lagos African Church Grammar School, ní Ìfàkọ̀-Ìjàyè ní Ìpínlẹ̀ Èkó bákan náà. [4]

Àtòjọ àwọn àṣàyàn orin rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • We Give You Praise
  • Praise Medley
  • There Is Sense in Nonsense
  • MO jí í re lónìí
  • Àpáta Ayérayé
  • Olorun Ayérayé
  • Agbára Mi Kọ́
  • Mo Mọ̀ Pé ẹ tún Lè Ṣe é
  • Èdìdí. [5]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Minister Esther Igbekele Biography, Life History". GM Lyrics. 2019-12-13. Retrieved 2020-11-06. 
  2. Punch Newspaper, 18 August, 2018 People love secular music because gospel is bitter — Esther Igbekele
  3. "I Joined Senior Choir At Seven —Musician Igbekele". P.M. News. 2014-06-27. Retrieved 2020-11-06. 
  4. "Gospel Singer Esther Igbekele Biography: Marriage, Husband, State Of Origin, Life History". NaijaGists.com. 2019-01-10. Retrieved 2020-11-06. 
  5. "List Of Songs By Esther Igbekele". Believers Portal. 2016-10-12. Retrieved 2020-11-06.