Estrogen
Estrojíínì tàbí oestrogen jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn hòmónù ìbálòpọ̀ tí tí wọ́n ń ṣisẹ́ ìdàgbà-sókè àti ìfètò sí ẹ̀yà ara ìbímọ lára àwọn obìnrin àti ìṣesí ìbálòpọ̀ lára obìnrin. [1][2] Ìpín mẹ́rin ni a lè pín estrogen si látàrí ìṣesí àti iṣẹ́ wọn nínú ara obìnrin. Àwọn náà ni: estrone (E1), estradiol (E2), àti estriol (E3).[1][3] Estradiol, tí ó tún ń jẹ́ estrane, ni ó lágbára jùlọ tí ó sì wòpọ̀ jùlọ pẹ̀lú. [1] Bákan náa ni estrogen tí wọ́n ń pè ní estetrol (E4) ni ó ma ń jáde nígbà tí obìnrin bá wà nínú oyún. Gbogbo ẹranko elégungun àti àwọn kòkòrò abìyẹ́ ni wọ́n ma ní estrogen lára[4].[5] Tí a bá ní ká fòye mọ̀ọ́, lílọ bíbọ̀ estrogen nínú ará ọkùnrin àti obìnrin kìí fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.[6] Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé estrogen kìí fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ púpọ̀ lára ọkùnrin tó bí ó ṣe wa lára obìnrin, síbẹ̀, ó ní iṣẹ́ pàtàkì tí ó ń ṣe lára ọkùnrin.[7] Gẹ́gẹ́ bí àwọn steroid hormone ti ń ṣiṣẹ́ ni estrogens náà rin tàbí pàráàro inú àgọ́ ara tí ó fi mọ́ inú àwọn sẹ́ẹ́lì ara. Ní kété tí estrogen bá ti wọ inú sẹ́ẹ́lì ara ni ó ma ń ròpọ̀ tí ó sì ma ń jí ohun tí wọ́n ń pè ní estrogen receptor (ERs) sílẹ̀ ní èyí yóò ma ṣiṣẹ́ ààtò ìtakìjí àwọn jíínì ara lọ́kan-ò-jọ̀kan .[8] Láfikún, estrogen tún ma ń ṣiṣẹ́ ìjísílẹ̀ àwọn ohun tí wọ́n ń pe ní membrane estrogen receptors (mERs),[9][10] gẹ́gẹ́ bí GPER (GPR30).[11]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 Understanding Pathophysiology. Elsevier Health Sciences. 2019. p. 767. ISBN 978-0-32-367281-8. https://books.google.com/books?id=oF2yDwAAQBAJ&pg=PA767. "Estrogen is a generic term for any of three similar hormones derived from cholesterol: estradiol, estrone, and estriol."
- ↑ Pharmacology and Pharmacotherapeutics. Elsevier Health Sciences. 2017. p. 943. ISBN 978-8-13-124941-3. https://books.google.com/books?id=f9LQDwAAQBAJ&pg=PA943. "The natural estrogens are steroids. However, typical estrogenic activity is also shown by chemicals which are not steroids. Hence, the term 'estrogen' is used as a generic term to describe all the compounds having estrogenic activity."
- ↑ "Estrogen". StatPearls [Internet]. StatPearls Publishing. December 20, 2021. PMID 30855848. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/books/NBK538260/. "Estrogen is a steroid hormone associated with the female reproductive organs and is responsible for the development of female sexual characteristics. Estrogen is often referred to as estrone, estradiol, and estriol. ... Synthetic estrogen is also available for clinical use, designed to increase absorption and effectiveness by altering the estrogen chemical structure for topical or oral administration. Synthetic steroid estrogens include ethinyl estradiol, estradiol valerate, estropipate, conjugate esterified estrogen, and quinestrol."
- ↑ "Biochemistry of aromatase: significance to female reproductive physiology". Cancer Research 42 (8 Suppl): 3342s–3344s. August 1982. PMID 7083198.
- ↑ "Estrogens in insects". Cellular and Molecular Life Sciences 40 (9): 942–944. September 2005. doi:10.1007/BF01946450.
- ↑ "Androgen production in women". Fertility and Sterility 77 (Suppl 4): S3–S5. April 2002. doi:10.1016/S0015-0282(02)02985-0. PMID 12007895.
- ↑ "Estrogens and health in males". Molecular and Cellular Endocrinology 178 (1–2): 51–55. June 2001. doi:10.1016/S0303-7207(01)00420-8. PMID 11403894.
- ↑ Endocrinology: an integrated approach. Oxford: BIOS: Taylor & Francis. 2001. ISBN 978-1-85996-252-7. PMID 20821847. https://www.ncbi.nlm.nih.gov/books/bv.fcgi?call=bv.View..ShowTOC&rid=endocrin.TOC&depth=10.
- ↑ "Membrane estrogen receptors - is it an alternative way of estrogen action?". Journal of Physiology and Pharmacology 64 (2): 129–142. April 2013. PMID 23756388.
- ↑ "Membrane estrogen receptor regulation of hypothalamic function". Neuroendocrinology 96 (2): 103–110. 2012. doi:10.1159/000338400. PMC 3496782. PMID 22538318. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3496782.
- ↑ "GPR30: A G protein-coupled receptor for estrogen". Molecular and Cellular Endocrinology 265-266: 138–142. February 2007. doi:10.1016/j.mce.2006.12.010. PMC 1847610. PMID 17222505. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=1847610.