Jump to content

Fífún ọmọ lọ́yàn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ọmọ tí ó ń mu (omi) oyàn lọ́wọ́.
Fíìmù nípa fífún ọmọ lọ́yàn

Fífún ọmọ lọ́yàn, tàbí fífún ọmọ lọmú túmọ̀ sí fífún ọmọdẹ́ tàbí ọmọ jòjòló ní omi ọ̀yàn gẹ́gẹ́ bíi oúnjẹ.[1] O le jẹ́ fífún ọmọ ní omi oyàn láti inu oyàn tàbí fífún ọmọ ní omi oyàn tí a ti fi owó fún jáde láti inú oyàn. Àjọ World Health Organization (WHO) pa á ní arowà pé kí ìfún ọmọ lọ́yàn bẹ̀rẹ̀ láàrin wákàtí kan lẹ́yìn tí ọmọ titun bá làjú sáyé, kí ìyá sì tesiwaju títí di ìgbà tí ọmọ bá pé ọmọdún méjì.[2]

Àwọn àjọ tí ó ń rí sí ètò ìlera, pẹ̀lú àjọ WHO, gbà á ní ìyànjú láti fún ọmọ titun ní omi oyàn nìkan fún oṣù mẹ́fà àkókò ayé rẹ̀.[3][4][5] Èyí túmọ̀ sí pé òbí ò gbudọ̀ fi oúnjẹ tàbí omi mìíràn fún ọmọ yàtò sí omi oyàn àti vitamin fún oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́.[6] Àjọ WHO pàrọwà fún ìyá láti fi omi oyàn nìkan fún ọmọ ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́, pẹ̀lú omi oyàn àti àwọn ounjẹ tí ó tó mìíràn fún ó kéré jù, ọdún méjì àkọ́kọ́ ọmọ titun.

Fifunnomo lọ́yàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ànfàní fún ìyá àti ọmọ.[4][7] Fífún ọmọ lọ́yàn ma ń ran àwọn Ọlọ́pa ara ọmọdé lọ́wọ́ láti dojú kọ àwọn aarun tí ó le fẹ́ pa ọmọdé lára[8][9]

  1. "Breastfeeding and Breast Milk: Condition Information". National Institute of Child Health and Human Development. National Institutes of Health (NIH), U.S. Department of Health and Human Services. 19 December 2013. Archived from the original on 27 July 2015. Retrieved 27 July 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. "Infant and young child feeding Fact sheet N°342". WHO. February 2014. Archived from the original on 8 February 2015. Retrieved 8 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Infant and young child feeding Fact sheet N°342". World Health Organization (WHO). 9 June 2021. Archived from the original on 8 February 2015. Retrieved 8 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. 4.0 4.1 "Breastfeeding and the use of human milk". Pediatrics 129 (3): e827–e841. March 2012. doi:10.1542/peds.2011-3552. PMID 22371471. http://pediatrics.aappublications.org/content/129/3/e827.long. 
  5. "Optimal duration of exclusive breastfeeding". The Cochrane Database of Systematic Reviews 2012 (8): CD003517. August 2012. doi:10.1002/14651858.CD003517.pub2. PMC 7154583. PMID 22895934. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=7154583. 
  6. "Breastfeeding". 
  7. "A summary of the Agency for Healthcare Research and Quality's evidence report on breastfeeding in developed countries". Breastfeeding Medicine 4 (Suppl 1): S17–S30. October 2009. doi:10.1089/bfm.2009.0050. PMID 19827919. 
  8. The Little Green Book of Breastfeeding Management for Physicians & Other Healthcare Providers (7 ed.). Madison, WI: The Institute for the Advancement of Breastfeeding and Lactation Education. 2020. ISBN 978-0-9987789-0-7. 
  9. "Breastfeeding in the 21st century: epidemiology, mechanisms, and lifelong effect". Lancet 387 (10017): 475–490. January 2016. doi:10.1016/s0140-6736(15)01024-7. PMID 26869575.