Fatima Meer
Fatima Meer | |
---|---|
Fáìlì:Fatima Meer.jpeg | |
Ọjọ́ìbí | Durban, Natal, South Africa | 12 Oṣù Kẹjọ 1928
Aláìsí | 12 March 2010 Durban, KwaZulu-Natal Province | (ọmọ ọdún 81)
Resting place | Brook Street Cemetery, Durban |
Iléẹ̀kọ́ gíga | University of Natal |
Iṣẹ́ | Writer and academic |
Notable work | Higher Than Hope |
Title | Professor |
Olólùfẹ́ | Ismail Chota Meer |
Àwọn ọmọ | 3, including Shehnaz |
Fatima Meer (tí wọ́n bí ní 12 August 1928 – tí ó sì kú ní 12 March 2010) jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè South African, ọ̀mọ̀wé, òǹkọ̀tàn àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn.
Ìgbésí ayé ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fatima Meer ni a bi ni Awọn opopona Grey ti Durban, South Africa, sinu idile idile ti mẹsan-an, nibiti baba rẹ Moosa Ismail Meer, olootu iwe iroyin ti Awọn iwo India, ti gbin sinu mimọ ti iyasoto ti ẹda. ti o wa ni orilẹ-ede naa. Iya rẹ ni Rachel Farrell, iyawo keji ti Moosa Ismail Meer. Iya rẹ jẹ alainibaba ati ti Juu ati Portuguese. O gba esin Islam o si yi oruko re pada si Amina. [1] Nigbati o jẹ ọmọ ọdun 16 ni ọdun 1944, o ṣe iranlọwọ lati gbe £ 1 000 fun iderun iyan ni Bengal, India. O pari ile-iwe rẹ ni Durban Indian Girls High School . Nigbati o jẹ ọmọ ile-iwe o kojọpọ awọn ọmọ ile-iwe lati wa Igbimọ Resistance Palolo Ọmọ ile-iwe lati ṣajọ owo fun ipolongo atako palolo ti agbegbe India lati 1946 si 1948. Igbimọ naa mu u lati pade Yusuf Dadoo, Monty Naicker, ati Kesaveloo Goonam . Lẹhinna o lọ si Ile-ẹkọ giga ti Witwatersrand fun ọdun kan nibiti o ti jẹ ọmọ ẹgbẹ ti ẹgbẹ Trotskyism kan ti o ni ibatan si Isokan Isokan ti kii-European (NEUM). O lọ si Ile-ẹkọ giga ti Natal, nibiti o ti pari alefa Apon ati alefa Masters ni Sociology .
Ajàjàgbara Òṣèlú
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Meer àti Kesaveloo Goonam di obìnrin àkọ́kọ́ láti dìbò gẹ́gẹ́ bí alásẹ ti Natal Indian Congress (NIC) ní ọdún 1950. Ó ṣe ìrànlọ́wọ́ láti ṣe ìdásílẹ̀ Àjùmọ̀se Àwọn Obìnrin Durban àti Agbègbè ní ọjọ́ kẹrin Oṣù Kẹwàá Ọdún 1952 gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn obìnrin àádọ́rin.. Àjọ yìí bẹ̀rẹ̀ láti lè jẹ́ kí àjọṣepọ̀ wà láàárín àwọn ọmọ Áfíríkà àti àwọn ará India nítorí àbájáde ìjà ẹ̀yà láàárín àwọn ẹgbẹ́ méjì ní ọdún 1949. Bertha Mkhize di alága nígbà tí Meer sì di akọ̀wé àjọ náà . Àjọ náà ṣe iṣẹ́ bíi ṣíṣe ètò ìtọ́jú ọmọdé àti pínpín mílíìkì ní Cato Manor . Àjọ náà tún gba owó fún àwọn olùfaragbá ìjì líle kan ní àwọn orísun omi níbi tí àwọn ọmọ Áfíríkà ti di aláìnílé lórí, wọ́n sì ṣàṣeyọrí nípa gbígba £4000 fún àwọn olùfaragbá omíyalé Sea Cow Lake.
Lẹ́hìn tí National Party ti gba agbára ní ọdún 1948 tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìmúse àwọn ìlànà wọn ti ìtako - ìyapa , ìjáfáfá Meer pọ̀ sí i àti nítorí àbájáde ìjàjàgbara rẹ̀ , ó ti kọ́kọ́ “ fífi òfin dè ” ní ọdún 1952 fún ọdún mẹta. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí ó dá sílẹ̀ ti Federation of South African Women (FEDSAW), tí ó di dídá sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹrin ọdún 1954 ní Hall Trades lórí Rissik Street, ní àárín Johannesburg, èyí tí ó ṣe olórí ìrìn-àjò àwọn obìnrin ìtàn ní àwọn ile Union, Pretoria, ní ọjọ́ kẹsàn-án Oṣù Kẹjọ Ọdún 1956. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùdarí ti Women's March ni ọdun 1956. Ní ọdún kan náà, ó ṣètò ìgbìmọ̀ kan láti ṣe àkójọ owó fún ìgbàsílẹ̀ àti àtìlẹyìn àwọn ìdílé ti àwọn olùdarí olóṣèlú Natal tí ó wà nínú ìdájọ́ ìsọ̀tẹ̀ .
Ní àkókò ọdún 1960, Meer ṣètò ìdárunmọ́jú alẹ́ láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn tako àtìmọ́lé ọ̀pọ̀ èèyàn ti àwọn ajàfitafita ẹlẹ́yàmẹ̀yà láìsí ìdánwò ní ìta túbú Durban. Ó tún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùsètò ti ìdárunmọ́jú ọlọ́sọ́ọ̀sẹ̀ ní Gandhi Settlement ní Phoenix . Olórí ti ìdárunmọ́jú ní Sushila Gandhi . Lákòókò ọdún 1970, Meer bẹ̀rẹ̀ láti gba èrò báyéserí ìtagírí Àwọ̀ Dúdú pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ South Africa (SASO) tí Steve Biko ṣe adarí fún.
Ní ọdún 1975, Meer jẹ́ ara olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ Àjọ Àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú (BWF) pẹ̀lú Winnie Mandela . Meer di Ààrẹ àkọ́kọ́ ti àjọ náà. Lẹ́yìn ọdún kan, ó tún di fífi òfin dè ní àkókò kan fún ọdún márùn-ún. Àṣẹ fífi òfin dè náà wá lẹ́hìn tí ó lọ sí ìpàdé ti Ètò Ìjìnlẹ̀ Dúdú níbi tí ó jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ pàtàkì kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan tí a pè ní “Ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ti Òfin Ẹlẹ́yàmẹ̀yà”. Ní oṣù Òkudù ọdún 1976, lẹ́hìn Soweto Uprisings, àwọn obìnrin mọ́kànlá láti BWF ni wọ́n mú tí wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé lábẹ́ Abala kẹfà ti Òfin ìwà jàǹdùkú. Wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ àdáwà ní ẹ̀wọ̀n Fort ní Johannesburg . Ó jàjà bọ́ lọ́wọ́ agbanipa ní kété tí wọ́n fi sílẹ̀ láti àtìmọ́lé ní ọdún 1976 nígbà tí wọ́n yìn ọn fún un ní ilé mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ní Durban, ṣùgbọ́n tí kò pa á lára. Ọmọkùnrin rẹ̀, Rashid, lọ sí ìdáwà ní ọdún kan náà. Wọ́n tún ṣe ìkọlù sí i lẹ́ẹ̀kan si, ó sì dẹ̀bi ìkọlù kejì lè ìgbésẹ̀ báyéserí Àwọ̀ Dúdú àti Inkatha Freedom Party.
Ó jẹ́ alátìlẹyìn tí ó lágbára ti Ìyípo Iran àti pé ó pa ìrìn-àjò Salman Rushdie si South Africa jẹ́ ní ọdún 1998, tí ó sọ pé olùsọ̀rọ̀ òdì ni. Ó kópa nínú àwọn ẹ̀hónú lòdì sí ìrẹ́jẹ àti ìkọlù tí àwọn ènìyàn Palestine àti ìkọlù Amẹ́ríkà ti Afiganisitani. Òun ni olùdásílẹ̀ Jubilee 2000 láti ṣe ìpolongo fún ìfagilé gbèsè Àgbáyé Kẹta. [2]
Iṣẹ́ ọrẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó ṣe àtẹ̀jáde ìwé rẹ̀ tí a pè ní Portrait of Indian South Africa ní ọdún 1969 ó sì ṣe ìtọrẹ gbogbo owó tí ń wọlé láti títa ìwé náà sí Gandhi Settlement fún àwọn ìwúlò láti kọ́ Ilé ọnà Gandhi àti Ilé-ìwòsàn. Ó ṣe ìrànlọ́wọ́ iṣẹ́ abẹ kan láti gba àwọn oluùfaragbá ìṣàn omi India 10000 sílẹ̀ ní Tin Town èyí tí ó wà ní bèbè Odò Umgeni . Meer kọ́ ilé ìgbé òní ìgbà díẹ̀ nínú àgọ́ kan àti ṣètò oúnjẹ ìdẹ̀rùn àti aṣọ. Lẹ́yìn náà, ó ṣàṣeyọrí sísọ̀rọ̀ àtúnṣe pípẹ́ títí fún wọn ní Phoenix . Meer tún ṣe ìdásílẹ̀ ó sì di olùdarí Natal Education Trust èyí tí ó gba owó láti àwùjọ India láti kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ní Umlazi, Port Shepstone àti Inanda .
Ó dá Tembalishe Tutorial College sílẹ̀ ní ilẹ̀ Gandhi's Phoenix láti kọ́ awọn aláwọ̀ dúdú ní ìmọ̀-ọ́n se akọ̀wé ní ọdún 1979. Ilé-iṣẹ́ iṣẹ́ ọnà tún di dídá sílẹ̀ ní Settlement láti kọ́ ẹ̀kọ́ títẹ ìbòjú, mansínìnnì ìsẹ̀sọ́ àti híhun fún àwọn aláìnísẹ́, Àti ilé-ẹ̀kọ́ olùkọ́ni àgbà àti ilé-iṣẹ́ ọnà ti wà ní títìpa ní ọdún 1982 lẹ́yìn àtìmọ́lé Fatima fún ìrúfin àṣẹ ìdínàmọ́ rẹ̀ tí ó fa ti àbójútó iṣẹ́ ní ìta ààlà Durban. [3] Lákòókò ọdún 1980, ó ṣètò àwọn ìwé ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ mẹ́wàá láti lọ sí Amẹ́ríkà ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún “ÌGBÌMỌ̀ GBA ILÉ WA LÀ” èyí tí ó jẹ́ dídá sílẹ̀ láti ọwọ́ àwùjọ aláwọ̀ ti Sparks Estate láti wá ìdájọ́ òtítọ́ fún àwọn tí wọ́n di híhalẹ̀ mọ́ nípasẹ̀ Agbègbè Durban tí ó fẹ́ láti gba àwọn ilé wọn. Wọ́n ṣe àṣeyọrí gba ìsanpadà fún iṣẹ́ náà. Nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Indira Gandhi, ó ṣètò ìwé ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ South Africa láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ ìsègùn àti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ olóṣèlú ní India. IBR ṣe àwọn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ láti mú ìlọsíwájú ìmúdójú òṣùwọ̀n màtíríìkì kékeré àti pé Phambili High di dídá sílẹ̀ ní ọdún 1986 fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà. [2]
Ní ọdún 1992, (ọdún méjì ṣáájú ìdìbò ìjọba tiwantiwa àkọ́kọ́ ) Fatima Meer se ìdásílẹ̀ Clare Estate Environment Group gẹ́gẹ́ bí ìdáhùn sí àwọn ìwúlò tí àwọn olùgbé ahéré àti àwọn aṣíkirí ìgbèríko. Wọn kò ní ẹ̀tọ́ ní àwọn ìlú tó lajú wọ́n sì nílò omi mímọ́, ìmọ́tótó àti ìpinnu tó dára. [4] Iṣẹ́ àkànṣe ilé-ẹ̀kọ́ Khanyisa jẹ́ dídá sílẹ̀ ní ọdún 1993 gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹ̀kọ́ ìgbáradì fún àwọn ọmọdé Áfíríkà tí kò ní àǹfààní ṣáájú kí wọ́n tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gangan. Ó tún ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìmọ̀-ọ́nse Àwọn Obìnrin Khanya ní ọdún 1996, èyí tí ó kọ́ àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú àádọ́jọ ní gígé-asọ, mansínìnnì ìránsọ , ẹ̀kọ́ àgbà àti ìṣàkóso ìsòwò. [5]
Ìgbésí ayé ara ẹni
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fatima Meer fẹ́ ìbátan rẹ̀ àkọ́kọ́ ní ọdún 1950, Ismail Meer . Èyí kì í ṣe nǹkan tó jẹ́ tuntun ní agbègbè Sunni Bhora níbi tí ó ti dàgbà. Ismail Meer jẹ́ agbẹjọ́rò olókìkí àti ajàjàgbara -ẹlẹ́yàmẹ̀yà . Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ti ilé-ìgbìmọ aṣòfin agbègbè KwaZulu-Natal ANC. Ní ọdún 1960, ó di mímú fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀tẹ̀, pẹ̀lú Nelson Mandela, àti àwọn ajàjàgbara mìíràn. Ní ọdún 1995, Rashid ọmọ Fatima Meer kú nínú ìjàm̀bá ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Ọmọbìnrin méjì Shehnaz ló kú, adájọ́ ilé ẹjọ́ ẹ̀tọ́ ilẹ̀, àti Shamim, olùbàdámọ̀ràn ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àwùjọ kan.
Ọ̀mọ̀wé àti òǹkọ̀wé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Meer di olùkọ́ni ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àwùjọ àti ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Natal láti ọdún 1956 sí 1988. Ó jẹ́ ènìyàn àkọ́kọ́ tí kì í ṣe aláwọ̀ funfun láti di ipò yẹn mú. Ó tún jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àbẹ̀wò ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mélòó kan nílẹ̀ òkèèrè. Meer di akẹgbẹ́ ti London School of Economics, ó sì gba oyè ìfidánilọ́lá mẹ́ta. Ní àkọ́kọ́, ó gba oyè ìfidánilọ́lá ní Philosophy láti Swarthmore College (1984) àti ní Humane Letters láti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Bennet ní Amẹrika (1994). Nígbà mìíràn,ó gba oyè ìfidánilọ́lá ní imọ̀-ìjìnlẹ̀ Àwùjọ láti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Natal ní South Africa (1998). [6]
Ó ṣe ìdásílẹ̀ Institute for Black Research (IBR), èyí tí ó di ìwádìí ati ilé-iṣẹ́ àtẹ̀jáde àti NGO ètò -ẹ̀kọ́ ní ọdún 1972 [4]
Àwọn iṣẹ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìwé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Òǹkọ̀wé eré oníṣe ìbòjú, The Making of Mahatma, fíìmù Shyam Benegal kan tí ó dá lórí ìwé rẹ̀ The Apprenticeship of a Mahatma ; India àti South Africa ni ó ṣe fíìmù náà.
Ìfidánilọ́lá, àwọn ohun ọ̀sọ́, àwọn ẹ̀bùn ati àwọn ìyàtọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Ẹ̀bùn Àpéjọ Àwọn oníròyìn South Africa (1975)
- Àmì ẹ̀yẹ Abdullah Haroon fún ìgbóguntì sí Ìrẹ́jẹ àti Ìyàtọ̀ Ẹ̀yà (1990)
- Àmì ẹ̀yẹ Vishwa Gurjari fún ìlọ́wọ́sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn (1994)
- Àwọn Obìnrin ọgọ́rùn-ún tí ó mi Àkójọ South Africa (1999)
- </img> Pravasi Bharatiya Samman (2003)
- #45  Àwọn ọgọ́rùn-ún ará ìlú South Africa (2004)
- Àṣẹ Orilẹ-èdè South Africa: Bèêrè fún Iṣẹ́ Iṣeduro ní fàdákà (2009)
- Ìlànà ti Luthuli ni Silver (2017)
Ikú àti ogún
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fatima Meer kú ní St Augustine's Hospital ní Durban ní ọjọ́ Kejìlá Oṣù Kẹta ní ọdún 2010, ẹni ọdún ọọ́kànlélọ́gọ́rin , láti inú ìkọlù kan èyí tí ó jìyà ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn . Àkójọpọ̀ àwọn ìwé ìṣèlú àti ti ilé ẹ̀kọ́ Fatima Meer tí ó ní àkọlé Voices of Liberation ni a tẹ̀jáde ní 2019. Awọn kíkùn àti àwòrán rẹ̀ ti jẹ́ ìfihàn ní Constitutional Hill láti Oṣù Kẹjọ ọdún 2017.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ The spirit of freedom : South African leaders on religion and politics. Berkeley. https://publishing.cdlib.org/ucpressebooks/view?docId=ft4p3006kc&chunk.id=d0e6228&toc.depth=1&toc.id=d0e6228&brand=ucpress.
- ↑ 2.0 2.1 Vahed, Goolam. Muslim portraits : the anti-apartheid struggle. Durban, South Africa. https://www.sahistory.org.za/sites/default/files/muslim_portraits_goolam_vahed_0.pdf.
- ↑ Rajab DM (9 May 2011). "Women: South African's of Indian Origin". Jacana Media. https://issuu.com/jacanamedia/docs/women_book/23.
- ↑ 4.0 4.1 "Fatima Meer, A Giant Social Reformer". POST. 31 August 2016. https://www.pressreader.com/south-africa/post-south-africa/20160831/281736973883317. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name ":4" defined multiple times with different content - ↑ "Meer A Resilient Freedom Fighter". The Mercury. 14 August 2017. https://www.pressreader.com/south-africa/the-mercury-south-africa/20170814/281500751355402.
- ↑ Empty citation (help)