Jump to content

Festus Keyamo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Festus Keyamo ní Mojeec International 2020
Festus Keyamo


Festus Keyamo (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kíní ọdún 1970) jẹ́ agbẹjọ́rò àti alágbàwí àgbà (SAN) ọmọ ilẹ̀ Naijiria, alátakò, àti alámùṣẹ ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn.[1][2] Ní oṣù keje ọdún 2017, Ì̀gbì̀mọ̀ tí ó ní anfaani sí iṣẹ́ òfin ti ilẹ̀ Naijiria, (Legal Practitioner Privilege Committee) dárúkọ Keyamo gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò ọmọ ilẹ̀ Naijiria tí ó dáyàtọ̀ láti fún ní ipò SAN. Bayi, Festus wà lára mínísítà Muhammadu Buhari. Keyamo àti àwọn miiran tí wọ́n dárúkọ nínú àkójọpọ̀ orúko fún ipò SAN ní ọdún 2017 ni wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ wọn sinu àjùmọ̀ṣe gíga ti àwọn alágbàwí àgbà Naijiria (SAN) ní oṣù kẹsan ọdún 2017[3] Ní ọdún 2017 bakanna, ìgbìmọ̀ alákòso àgbáyé ti America tí ó wà ní Washington tún fún Keyamo ní àmì ẹ̀yẹ ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn ti àgbáyé fún àwọn akitiyan rẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn lórí ti ìdáábòbò àti ìgbéga ti ẹ̀tọ́ ẹ̀dá ènìyàn àti ipolongo fún ìjọba Naijiria tí yíò ṣe ìsírò iṣẹ́ rẹ.[4] Ní oṣù kẹrin ọdún 2018, wọ́n yan Keyamo gẹ́gẹ́ bí olùdarí fún ìbáráẹnisọ̀rọ̀ (agbẹnusọ òṣìṣẹ́) fún àtúnyàn sípò ìbò ọdún 2019 ti aarẹ orílẹ̀ èdè Naijiria.[5]

A bí Festus kayamo ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kíní ọdún 1970 ní Ughelli, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Delta ní guusu Naijiria ṣùgbọ́n baba rẹ wá láti Effurun, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Delta bakanna.[6] Keyamo kọ́ ẹ̀kọ́ onípele kini rẹ ní ilé-ìwé alakobere ti Model àti ẹ̀kọ́ onípele keji ní ilé-ìwé gíga ti ìjọba tí ó wà ní Ughelli níbití Ó ti gba ìwé ẹ̀rí oniwe mẹwa (West African School Certificate) ní ọdún 1986.[7] Lehinna, Ó lo sí Yunifásítì Ambrose Alli tí ó wà ní EkpomaÌpínlẹ̀ Ẹdó, guusu Naijiria níbití Ó ti gba oyè àkọ́kọ́ nínú ìmọ̀ òfin ní ọdún 1992. Ó sì gba ìpè sí pẹpẹ amọ̀fin ti orílẹ̀ èdè Naijiria ní oṣù kejìlá [8] ọdún 1993.[9]

Festus Keyamo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òfin rẹ̀ ní ọdún 1993 ní ilé iṣẹ́ òfin ti Gani Fawehinmi tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó, guusu Naijiria. Lẹ́hìn tí Ó lo ọdún méjì ní ilé iṣẹ́ òfin ti Gani Fawehinmi, Ó kúrò níbẹ̀ láti lọ ṣe ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ òfin Festus kayamo.[10]

Keyamo jẹ́ agbẹjọ́rò fún Mujahid Dokubo-Asari, ẹni tí ó jẹ́ olórí fún Niger-Delta Peoples Volunteer Force, nígbàtí wọ́n pee lẹ́jọ́ fún dídalẹ̀ ìlú. Ò un tún ni olórí agbẹjọ́rò fún Ralph Uwazuruke, olórí fún ẹgbẹ́ ajàjàngbara láti jẹ́ kí ìdádúró Ìpínlẹ̀ Biafra wásí ìmúṣẹ (MASSOB),[11] nígbà ìpẹ̀jọ́ rẹ fún dídalẹ̀ ìlú. Keyamo tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò fún ikú Bọla Ige.[12]

Ńi ọdún 2008, Ó gbé ìjọba àpapọ̀ ilẹ Naijiria lọ sí ilé-ẹjọ́ lórí yíyàn àwọn olórí iṣẹ́ lọ́nà tó lòdì sí òfin.[13]

Ní ọdún 2017, arábìnrin Stephanie Otobo, akọrin kan tí ó fi ìlú Canada ṣe orísun, fi ẹ̀sùn kan Aposteli Suleman Johnson látipasẹ̀ Festus Keyamo, ẹnití nṣe agbẹjọ́rò rẹ, pé Aposteli Suleman kùnnà láti mú ìlérí Ìgbéyàwó tí Ó ṣe pẹ̀lú òun ṣẹ lẹ́hìn ìgbà tí ó ti bá òún ní ìbálòpò lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà.[14] Keyamo tún jẹ́ agbẹjọ́rò fún àwọn olókìkí olórin ọmọ ilẹ̀ Naijiria tí wọ́n npè ní Duo of Psquare àti laarin àríyànjiyàn fidio tí o nlọ kákààkiri èyí tí ó ṣe àfihàn àwọn arákùnrin mejeeji yi níbití wọ́n ti nbu ara wọn tí wọ́n tún nkan ara wọn ní ẹ̀ṣẹ́. Lẹ́hìn èyí ni Festus Keyamo ṣe àgbéjáde ìlòdì sí fidio yi tí Ó sì see lálàyé pé fidio yi ko ti ilé-iṣẹ́ ofin oun jáde.

Yíyàn sínú òṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Festus wa lára àwọn mínísítà tí a yàn fún ìṣàkóso ìjọ́ba ẹlẹ́ẹ̀kejì ti Aarẹ Muhammadu Buhari.[15]

Lẹ́hìn tí wọ́n ti yan, ilé Ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ṣe àyẹ̀wò rẹ.[16] ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2019. Títí di ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsan ọdún 2019, wọ́n yan keyamo gẹ́gẹ́ bi mínísítà Ìpínlẹ̀ fún Niger Delta, kí ó tó di wípé Aarẹ Muhammadu Buhari yan pada sí ilé iṣẹ́ ìjọba ti o nrisi ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ àti Ìgbanisíṣẹ́,[17] laarin oṣù kan sí ìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ yan ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣú kẹjọ ọdún 2019.

Àwọn Ìtọ́kasí

  1. https://www.premiumtimesng.com/features-and-interviews/175521-interview-president-jonathan-joke-festus-keyamo.html
  2. https://www.premiumtimesng.com/features-and-interviews/175521-interview-president-jonathan-joke-festus-keyamo.html
  3. "Committee announces Keyamo, 29 others Senior Advocates of Nigeria". P.M. News. 2017-07-06. Retrieved 2020-01-27. 
  4. Akinwale, Funsho (2017-12-16). "Festus Keyamo gets human rights award in US - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Archived from the original on 2020-02-04. Retrieved 2020-02-04. 
  5. "Keyamo appointed spokesman for Buhari’s 2019 campaign – Punch Newspapers". Punch Newspapers – The most widely read newspaper in Nigeria. 2015-12-15. Retrieved 2020-02-04. 
  6. "Meet Festus Keyamo, Minister of State for Niger Delta Affairs". Vanguard News. 2019-08-21. Retrieved 2020-02-04. 
  7. Ebhota-Akoma, Eseohe (2019-07-23). "What you need to know about Buhari's ministerial nominee: Festus Keyamo – Daily Trust". Daily Trust. Archived from the original on 2020-02-04. Retrieved 2020-02-04. 
  8. "Keyamo shares first picture in office as minister". P.M. News. 2019-08-22. Retrieved 2020-02-04. 
  9. "Meet Festus Keyamo, Minister of State for Niger Delta Affairs". Vanguard News. 2019-08-21. Retrieved 2020-02-04. 
  10. "Home". Home. 1970-01-21. Archived from the original on 2020-02-17. Retrieved 2020-02-04. 
  11. "Festus Egwarewa Adeniyi Keyamo - Profile". Africa Confidential. 2020-02-04. Retrieved 2020-02-04. 
  12. "CLEARCALLERS". CLEARCALLERS. 2014-02-20. Retrieved 2020-02-04. 
  13. "Court Declares Exclusive Appointment Of Service Chiefs By President Illegal". Sahara Reporters. 2013-07-01. Retrieved 2020-02-04. 
  14. "Sex Scandal: Apostle Suleiman, Keyamo in war of words over Stephanie Otobo". Premium Times Nigeria. 2017-03-11. Retrieved 2020-02-04. 
  15. "Full list of Buhari’s ministerial nominees". Punch Newspapers. 2015-12-15. Retrieved 2020-02-04. 
  16. Published (2015-12-15). "Ministerial screening: Drama as Melaye tells Keyamo to recite national anthem". Punch Newspapers. Retrieved 2020-02-04. 
  17. "Keyamo redeployed to labour ministry, swaps post with Alasoadura - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2019-09-25. Retrieved 2020-02-04. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]