Jump to content

Fisayo Ajisola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Fisáyọ̀ Ajíṣọlá
Ọjọ́ìbíOluwafisayo Ajibola Ajisola
Ìpínlẹ̀ Èkó, Nàìjíríà
Iṣẹ́Osere, Akọrin.
Ìgbà iṣẹ́2011 – lọwọlọwọ
Websitejef.org.ng

Fisáyọ̀ Ajíṣọlá , tí a tún mọ̀ sí Freezon, [1] jẹ́ òṣèré lorí ẹrọ amóhùnmáwòrán àti òṣèré sinima àgbéléwò àti akọrin. Ó di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú eré oníṣe aláwòtúnwò kan tí wọ́n pè ní Jenifa's Diary, pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Funke Akindele. Ó tún di gbajúmọ̀ fún ipa rẹ̀ tí ó kó nínú àwọn eré oníṣe bíi This Life, Nectar, Shadows, Burning Spear, Circle of Interest àti The Story of Us .[2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Biokemisitiri níle ẹ̀kọ́ Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB), ní Ìpínlẹ̀ Ògùn.[1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Fisáyọ̀ jọ ọmọ bibi ìlú Ayédùn ní ìpínlẹ̀ Èkìtì, ní apá a gúúsù ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[3] Fisáyọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ń kópa nínú àwọn eré ọlọkan-ò-jọ̀kan ní ilé-ẹ̀kọ́ oníwèé mẹ́wàá ti Federal Government College tí ó wà ní ìlú Òdogbòlú ní ìpìnlẹ̀ Ògùn. Ó forúkọ sílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ eré tíátà ní ilè-ẹ̀kọ́ PEFTI tí ò wà nílú Èkó ní ọdún 2010.[3] Ó kópa nìnú eré Nnena and Friends Show.[3] Ó ṣe àgbékalẹ̀ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba (NGO) tí ó pè ní Jewel Empowerment Foundation, pẹ̀lú ìrètí láti fi ṣe ìrònilágbára fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé.[4]

Fisayo bẹrẹ iṣẹ oṣere rẹ ni ọdun 2011, pẹlu awọn ipa ninu awon ere tẹlifisiọnu Naijiria bii “Tinsel”, “Spear Burning” ati “Circle of interest”. O gba isinmi kuro nibi ere ṣiṣe ni Oṣu Kẹsan, ọdun 2011 nigbati o ri igbawole si Ile-ẹkọ giga. Ajisola ṣe ifilọlẹ iṣẹ ṣiṣe fiimu re ni ọdun 2016[1] pẹlu sise fiimu Road to Ruin ni ifowosowopo pẹlu ipilẹ rẹ, Jewel Empowerment Foundation (JEF)[3] pẹlu ero lati gba ijọba niyanju lati gbe igbese fun ipese awọn iṣẹ fun awọn ọdọ Naijiria.[5] Oṣere Raphael Niyi Stephen, ti o kopa ninu fiimu naa, ti sọ pe: "Fiimu naa jẹ ọna lati jẹ ki awon eniyan mọ ohun ti n ṣẹlẹ si awọn ọmọde ati lati tun tele ohun ti ijọba n ṣe nipa ikiri oja, lati jẹ ki awọn eniyan mọ pe ikiri oja ko ni n ti o kan fun awon omo wa".[6]

Odun Akole Ipa Agberejade/Aludari Afikun
2011 Tinsel Alajose Tope Oshin Ogun ere Telifisonu Mnet
2011 Burning Spear Asiwaju Akin Akindele ere Telifisonu
2011 Circle of Interest Alajose Kalu Anya ere Telifisonu
2012 Shadows Asiwaju Tunde Olaoye ere Telifisonu
2014 Nectar Alajose Sola Sobowale ere Telifisonu
2015 This Life Ipa atilẹyin Wale Adenuga ere Telifisonu
2016 Jenifa's Diary Alajose Funke Akindele ere Telifisonu alawada