Foluke Adeboye
Foluke Adeboye | |
---|---|
Image of Foluke Adeboye | |
Ọjọ́ìbí | Foluke Adenike Adeyokunnu 13 Oṣù Keje 1948 Ọwá Obòkun Oji ní Ìjẹ̀ṣà, Ìpínlẹ̀ Òṣun. |
Olólùfẹ́ | Enoch Adejare Adeboye |
Àwọn ọmọ | mẹ́rin |
Website | Official website |
Foluke Adenike Adeboye jẹ́ ọmọ bíbí Jacob Adelusi Adeyokunnu, tí wọ́n bí ní ọjọ́ Ìsẹ́gun,oṣù kèje, odún 1948. Ó ma jẹyọ pé Bàbá Foluke(Jacob Adeyokunnu), ó jẹ́ ọmokùnrin àkọ́kọ́ bàbá ti ẹ̀, tí ó sì tan mọ́ ìdílé oyè, Ọwá Obòkun Oji, ti ilẹ̀ Ìjèṣà. Èyí fi hàn pé ọmọọba ni Foluke jẹ́. Olùkọ́ ìwé àti olùkọ́ ẹ̀sìn kìrìtíẹ́nì onílànà-ìdáhùn-àti-ìṣèbéèrè ni bàbá Foluke jẹ́.[1]
A tún mọ Foluke gẹ́gẹ́ bí i Mummy G.O. olùṣọ́-àgùntàn ni ó jẹ́, ajíhìnrere lórí ẹ̀rọ amóhùnwáwòrán, agbọ̀rọ̀sọ ní ibi àpèjọ, òǹkọ̀wé, àti aya Enoch Adejare Adeboye, tí ó jẹ́ alábójútó gbogbogbò ìjọ Redeemed Christian Church of God.[2]
Ìwé-kíkà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé-ìwé alákọ̀óbẹ̀rẹ̀ Methodist-Oke Eshe-Iléṣà, àti Methodist Girls School- Agurodo-Iléṣà ni Foluke ti kàwé, kí ó tó lọ ìwé-ẹ̀rí olùkọ́ ti ipele II ní United Missionary College-Ìbàdàn, àti ìwé-ẹ̀rí nípa ẹ̀kó( Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ àti Ìṣirò) ní Kọ́lẹ̀èjì ti Ẹ̀kọ́, Yunifásítì ìlú Èkó.[3]
Àwon Ìtọkasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìkọ kedere
- ↑ "The Official Website of Pastor Foluke Adenike Adeboye". The Official Website of Pastor Foluke Adenike Adeboye. 1948-07-13. Retrieved 2022-05-22.
- ↑ "Foluke Adeboye". Wikipedia. 2021-02-16. Retrieved 2022-05-22.
- ↑ "Foluke Adeboye". Wikipedia. 2021-02-16. Retrieved 2022-05-22.