Jump to content

Gambo Sawaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Hajia Gambo Sawaba tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kejì ọdún 1933, tí ó sìn ṣaláìsí lóṣù kẹwàá ọdún 2001 (15 February 1933 – October 2001) jẹ́ ajìjàǹgbara ẹ̀tọ́ obìnrin, afowóṣàánú àti òṣèlú ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.[1][2] Òun ni igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú Great Nigeria People's Party, tí wọ́n sìn tún yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn obìnrin nínú ẹgbẹ́ Northern Element Progressive Union (NEPU).[3]

Aáyan gẹ́gẹ́ bí òṣèlú àti ajàfẹ̀tọ́ọ̀ ènìyàn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti ọmọ ọdún méjìdínlógún ni Sawaba tí bẹ̀rẹ̀ òṣèlú. Lásìkò náà, ẹgbẹ́ òṣèlú Northern People's Congress ní ó gbajúmọ̀ jùlọ lápá àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, tí àwọn ọba wọ́n pẹ̀lú àwọn Aláṣẹ ìjọba Amúmisìn láti orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn nígbà náà, ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ó dára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò, Northern Element Progressive Union (NEPU). Ó jẹ́ olùpolongo tako gbígbé ọ̀dọ́mọbìnrin màjèsín ní ìyàwó, iṣẹ́-ipá àti aṣègbè ẹ̀kọ́ kíkà lápá àríwá Nàìjíríà.[4] Gambo, bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ nígbà tí ó bọ́ síta pẹ̀lú ìgboyà níbi ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ òṣèlú kan tí ó sìn sọ̀rọ̀ níbi ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ náà tí ó kún fún ọkùnrin ṣọ́ṣọ́.[4] Arábìnrin Fúnmiláyọ̀ Ransome-Kuti ní ó tọ́ ọ sọ́nà nígbà náà, tí ó sìn wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta lẹ́yìn ìgbà náà.[3] Òun obìnrin àkọ́kọ́ tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjàǹgbara àwọn obìnrin apá àríwá Nàìjíríà.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Kwewum, Rima (2004). THE GAMBO SAWABA STORY (second ed.). Abuja: Echo Communications Limited. pp. 52. ISBN 978-37305-0-9. 
  2. Paul, Mamza. "Nigeria's Unsung Heroes (10). Feminism As a Prowess: The Profile of Chief (Mrs.) Margaret Ekpo and Hajiya Gambo Sawaba". Gamji. Retrieved 19 September 2017. 
  3. 3.0 3.1 "Hajia Gambo Sawaba". NigeriaGalleria. Galleria Media Limited. Retrieved 19 September 2017. 
  4. 4.0 4.1 4.2 "A Brief History Of Hajiya Gambo Sawaba -The Fearless Politician Who Fought For The Freedom Of Northern Women In Spite Of Several Imprisonments". Women.ng. Archived from the original on 3 November 2017. Retrieved 19 September 2017.