Jump to content

Geography of the Democratic Republic of the Congo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 

Democratic Republic of the Congo (DRC) jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó tóbi jùlọ ní ihà ìsàlẹ̀ Sahara Africa, tí ó gba díẹ̀ nínú 2,344,858 square kilometres (905,355 sq mi). Púpọ̀ jùlọ ti orílẹ-èdè náà wà láàrin agbami ńlá ti Odò Congo. Agbègbè gbùngbùn tí ó gbòòrò, tí ó wà ní ìsàlẹ̀ jẹ́ agbada omi kan tí ó ní ìrísí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó rọ̀ síhà ìwọ̀-oòrùn, tí igbó kìjikìji bò, tí àwọn odò sì ń sọdá. Àárín igbó náà wà ní àyíká àwọn ilẹ̀ olókè ní ìwọ̀ oòrùn, tí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ ń dàpọ̀ mọ́ àwọn ilẹ̀ koríko ní gúúsù àti gúúsù ìwọ̀ oòrùn. Àwọn ilẹ̀ koríko tí ó nípọn gbòòrò kọjá Odò Congo ni àríwá. Àwọn òkè gíga ti Ruwenzori Range (díẹ̀ nínú wọn ga ju 5,000 metres (16,000 ft) lọ) wà ní àwọn ààlà ìla-òòrun pẹ̀lú Rwanda ati Uganda (wo àwọn igbó Albertine Rift montane fún àpèjúwe agbègbè yìí).