Gideon Okeke
Gideon Okeke jẹ́ òṣèrékùnrin ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, gbajúmọ̀ àti olóòtú ètò lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán.[1][2][3] Ó di gbajúmọ̀ ní ọdún 2006, nígbà tí ó kópa nínú ìdíje ti Big Brother Nigeria. Ní ọdún 2008, Gideon dara pọ̀ mọ́ àwọn akópa ti fíìmù M-NET tí wọ́n máa ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, ìyẹn Tinsel.[4]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gideon jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo tí àwọn òbí rè bí, ó sì dàgbà sí Ajegunle, èyí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó kún fún jàgídíjàgan ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[5] Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Nnamdi Azikiwe University, níbi tí ó ti kọ́ nípa applied bio-chemistry. Lẹ́yìn náà ni ó forúkọ sílẹ̀ ní Lee Strasberg Institute, ní New York, níbi tí ó ti gba ẹ̀kọ́ nípa eré ṣíṣe.[5]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lẹ́yìn tó farahàn nínú ìdíje Big Brother Nigeria Àkọ́kọ́, Gideon darapọ̀ mọ́ àwọn akópa eré Tinsel, èdá-ìtàn Phillip Ade Williams, sì ló ṣe.[6][7] Gideon ti farahàn nínú fíìmù ilẹ̀ South Africa kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Jacobs cross.[7] Ní ọdún 2014, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Bernard nínú fíìmù irokotv kan, tí àkọ́lé rè ń jẹ́ Poisoned Bait, èyí ti Leila Djansi darí. Bákan náà, Gideon ni olóòtú ètò DSTV kan tó ń jẹ́ Money Drop.[8]
Eré Àgbéléwò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eré Àgbéléwò àkọ́kọ́ tí Gideon máa ṣe ní Agbo Òseèré Nàìjíríà kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Relentless, ní ọdún 2010. Lára àwọn akópa mìíràn tí wọ́n jìjọ ṣe fíìmù náà ni Jimmy Jean-Louis àti Nneka Egbuna.[9] Fíìmù ẹ̀kejì rẹ̀ ni fíìmù ọdún 2014 kan, tó jẹ́ mọ́ ìwá̀-ọ̀daràn, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ A Place in the Stars. INí ọdún kan náà, ó ṣe ẹ̀dá-ìtàn Tobena, nínú fíìmù ajẹmọ́fẹ̀ẹ́ kan, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ When Love Happens. Àwọn fíìmù mìíràn tí ó ṣe ni Gbomo Gbomo Express, àti 93 Days.[10][11]
Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Eré orí-ìtàgé
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Title | Role | Ref |
---|---|---|---|
Fractures | |||
Fela... Arrest the Music | Fela | ||
Saro the Musical 2 | Azeez |
Eré orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Title | Role |
---|---|---|
2007 | Big Brother Naija | Himself |
2008–present | Tinsel | Phillip Ade Williams |
Jacob's cross | ||
2014 | Poisnned Bait | |
Money Drop | Host |
Fíìmù àgbéléwò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Title | Role |
---|---|---|
2006 | Relentless | Obi |
2014 | A Place in the Stars | Kim Dakim |
...When Love Happens | Tobena | |
2016 | 93 Days | Morris-Ibeawuchi |
Gbomo Gbomo Express | Francis | |
2021 | Loving Rona | Benny Ramsey |
2022 | Obsession (2022 film) |
Àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Award | Category | Work | Result | Ref |
---|---|---|---|---|---|
2022 | Africa Magic Viewers' Choice Awards | Best Actor in A Comedy | Loving Rona | Iṣẹ́ ń lọ lórí ẹ̀ | [12] |
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Gideon Okeke is Dapper & Outspoken in the New Fratres Styleman Series - "Africa is more elegant than sack cloth, animal skin or loin clothing" - BellaNaija". www.bellanaija.com.
- ↑ Izuzu, Chidumga. "Gideon Okeke: 7 things you probably don"t know about talented "Tinsel" actor". Archived from the original on 2017-08-10. Retrieved 2024-04-16.
- ↑ Olowolagba, Fikayo (2022-03-09). "Don't envy us, we earn peanuts in Nollywood - Gideon Okeke". Daily Post Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-07-20.
- ↑ NJOKU, BENJAMIN. "I’m an ambitious actor – Gideon Okeke, of Tinsel fame".
- ↑ 5.0 5.1 "How Tinsel changed my story –Gideon Okeke". 12 October 2013.
- ↑ "Africa Magic Official Website". Africa Magic Official Website.
- ↑ 7.0 7.1 Izuzu, Chidumga. ""Tinsel": Show celebrates 1500th episode". Archived from the original on 2017-08-02. Retrieved 2024-04-16.
- ↑ "Gideon Okeke hosts the Money drop Nigeria - Vanguard News". 12 January 2013.
- ↑ Okoi-Obuli, Wendy. "Review – Andy Okoroafor’s ‘Relentless’ (Arthouse Exploration Of Contemporary Nigeria) - IndieWire". www.indiewire.com.
- ↑ Izuzu, Chidumga. "Gideon Okeke: Actor is "Morris Ibeawuchi" in Steve Gukas" upcoming film "93 Days"".[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "93 Days Top AMVCA Award Nominations List". Archived from the original on 2021-11-09. Retrieved 2024-04-16.
- ↑ "2022 Africa Magic Awards Nominees don land- See who dey list". BBC News Pidgin. https://www.bbc.com/pidgin/tori-60818021.