Grace Oladunni Taylor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Grace Oladunni Taylor
Ọjọ́ìbíGrace Oladunni Lucia Olaniyan
24 Oṣù Kẹrin 1937 (1937-04-24) (ọmọ ọdún 86)
Efon-Alaiye, Ekiti State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Orúkọ mírànOladunni Olaniyan-Taylor
Iṣẹ́Biochemist
Ìgbà iṣẹ́1970–2004
Olólùfẹ́Ajibola Taylor
AwardsL'Oréal-UNESCO Awards for Women in Science

Grace Oladunni Taylor (tí a tún mọ̀ sí Grace Oladunni Lucia Olaniyan-Taylor; tí a bí ní ọjọ́ 24 oṣù kẹrin, ọdún 1937)[1] jẹ́ biochemist, ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn nígbà kan rí. Òun ni obìnrin ẹlẹ́ẹ̀kejì tí wọ́n máa gbà wọlé sí Nigerian Academy of Science àti obìnrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ láti gba àmì-ẹ̀yẹ̀ L'Oréal-UNESCO Award for Women in Science.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìlú Efon-Alaiye, ní ipinle Ekiti,ni a bí Grace Oladunni Lucia Olaniyan sí, sínú ìdílé Elizabeth (née Olatoun) àti R. A. W. Olaniyan. Láàárín ọdún 1952 àti 1956, ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ìwé Queen's School ní EdeÌpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.Ó forúkọ wọlé sí ilé-ìwé gíga ní ọdún 1957 ní Nigerian College of Arts and Science ní Ìpínlẹ̀ Ẹnúgu, ní ọdún 1959, wọ́n gbe lọ sí Yunifásitì College of Ibadan (tí ó wá di Yunifásítì ìlú Ìbàdàn báyìí). Olaniyan kẹ́kọ̀ọ́ gboyè pẹ̀lú èsì tó dá ní ọdún 1962, pẹ̀lú ìwé-ẹ̀rí nínú ẹ̀kọ́ chemistry.[2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Adetunji Akinyotu (1989). Who's who in Science and Technology in Nigeria. Federal University of Technology. ISBN 978-978-2475-00-8. https://books.google.com/books?id=ojEJAQAAIAAJ. 
  2. "Emeritus Professor G. Oladunni Olaniyan-Taylor, FAS". Ibadan, Nigeria: Association of Clinical Chemists of Nigeria. Retrieved 5 November 2015.