Jump to content

Hauwa Muhammed Sadique

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Hauwa Muhammed Sadique
Ọjọ́ìbíFebruary 6, 1969
Orílẹ̀-èdèNigeria
Ẹ̀kọ́Army command children school, Kaduna

Queen Amina college University of Maiduguri

Bayero university
OrganizationNigeria society of Engineers Society of Women engineers
Parent(s)Abubakar & Amina Muhammed

Hauwa Muhammed Sadique (tí wọ́n bí ní February 6, ọdún 1969) jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti Ààrẹ ẹ̀kẹrìnlá ti Association of Professional Women Engineers of Nigeria (APWEN).[1][2] Òun ni ẹni àkọ́kọ́ láti ilẹ̀ Àríwá tó jẹ Ààrẹ ẹgbẹ́ náà.[3]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Hauwa ní ọjọ́ kẹfà oṣù kejì ọdún 1969, sínú ìdílé Muhammed Abubakar, àti Amina Muhammed Shuwa.[4] Ó jẹ́ ọmọ ìlú Mafa, láti Ìpínlẹ̀ Borno, ní Nàìjíríà.[5]

Ó lọ sí ilé-ìwé alákọ̀ọbẹ̀rẹ̀ Army Command Children School ní ipinle Kaduna ní ọdún 1976. Ó sì tún lọ sí Queen Amina College, ní Kakuri fún ìwé girama. Ó gba national diploma nínú ẹ̀kọ́ Agricultural Engineering Technology, ó sì tún padà gba B.Eng ní ọdún 1994, láti University of Maiduguri.[5] Ní ọdún 2005, ó gba M.Sc nínú ẹ̀kọ́ Economics láti Bayero University.

Hauwa bẹ̀rè gẹ́gẹ́ bí i olùkọ́ ní Airforce Primary School ní Kano. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Family Economic Advancement Programme (FEAP) nínú ọdún 1999. Wọ́n padà fi sí ẹ̀ka ẹ̀rọ ti Federal Ministry of Agriculture àti Water Resources. Ó padà di chief engineer ní dams and reservoir operations department ní Kano.

Òun ni ààrẹ ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá ti Association of Professional Women Engineers ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, (APWEN) àti ààrẹ àkọ́kọ́ ti ẹgbẹ́ àwọn tó wà ní apá Àríwá. Wọ́n yàn án sípò ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kejì, ọdún 2016. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí i financial secretary, general secretary, ex-officio àti vice-president fún ẹgbẹ́ náà.

Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ Nigerian Society of Engineers, Society of Women Engineers, National Institute of Cost àti Appraise Engineers, àti Council for the Regulation of Engineering ní Nàìjíríà.[6][7]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "14th Apwen President | APWEN". www.apwen.org. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  2. "Female engineers storm Wilson Group Nsukka factory". The Sun Nigeria. 31 August 2016. 
  3. Tofa, Aysha (18 February 2017). "The story behind Startup Kano's Women Founders Conference". She Leads Africa. Archived from the original on 2 April 2023. Retrieved 7 February 2024. 
  4. "Page 211". My Engineers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-29. 
  5. 5.0 5.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named :0
  6. "We shall leave no stone unturned as we project more Women to professional limelight- Engr. (Mrs.) Hauwa Sadique". My Engineers. 4 March 2016. 
  7. "Who is Engr Hauwa Muhammed Sadique, the new Nigerian Women Engineers' President?". My Engineers. 7 February 2016.