Jump to content

Ibinabo Fiberesima

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ibinabo Fiberesima
Ibinabo Fiberesima
Ọjọ́ìbí13 Oṣù Kínní 1970 (1970-01-13) (ọmọ ọdún 54)
Port Harcourt, Rivers State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Ibadan
Iṣẹ́
Ìgbà iṣẹ́1997–present

Ibinabo Fiberesima (tí a bí ní 13 Oṣù kínní, Ọdún 1970) jẹ́ òṣèré orí-ìtàgé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti olùṣàkóso ìdíje ẹwà tẹ́lẹ̀rí[1] Ó ti fi ìgbà kan jẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ Actors Guild of Nigeria.[2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ibinabo sí ọwọ́ bàbá tí ó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ìyá tí n ṣe ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland. Ibinabo bẹ̀rẹ̀ ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbàtí ó forúkọsílẹ̀ ní Y.M.C.A Play Center, ní Ìlú Port Harcourt ṣááju kí ó tó lọ sí Federal Government Girls College ní Ìlú New Bussa, Ìpínlẹ̀ Niger fún ètò ẹ̀kọ́ girama rẹ̀. Ó ní oyè ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ Èdè Gẹ̀ẹ́sì, èyítí ó gbà láti Yunifásítì ìlú Ìbàdàn.[3]

Ibinabo kópa nínu ìdíje ẹwà Miss Nigeria ní ọdún 1991 níbi tí ó ti ṣe ipò kejì. Ṣáájú èyí, ó ti kópa tó sì jáwé olúborí níbi ti ìdíje Miss Wonderland ní ọdún 1990, ọdún yìí kan náà ni ó tún ṣe ipo keji níbi ìdíje Miss NUGA, èyítí ó wáyé ní Yunifásítì ìlú Calabar.[4]

Ní ọdún 1992, ó díje níbi ìdíje Most Beautiful Girl in Nigeria (MBGN) fún ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀, níbi tí ó ti ṣe ipò kẹẹ̀ta.[5] Ní ọdún 1997, ó tún díje nínu ti Miss Nigeria níbi tí ó ti ṣe ipò kejì lẹ́ẹ̀kan si ṣááju kí wọ́n tó wá de ládé fún ti ìdíje Miss Wonderful ní ọdún kan náà.[6] Ó tún ṣe ipò kẹẹ̀ta fún ìdíje Most Beautiful Girl in Nigeria ẹ̀dà ti ọdún 1998.[7]

Ibinabo kó ipa àkọ́kọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré nínu fíìmù Most Wanted kí ó tó wá ṣe ìfihàn nínu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn fíìmù Nàìjíríà míràn.[8]

Àkójọ àwọn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Most Wanted
  • The Ghost
  • St. Mary
  • The Twin Sword
  • Ladies Night
  • The Limit
  • Letters to a Stranger
  • '76
  • Rivers Between
  • A Night In The Philippines
  • Pastor's Wife
  • Camouflage "

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Wemimo, Esho (13 January 2015). "Newly wed actress turns year older". Pulse Nigeria. Archived from the original on 20 April 2016. https://web.archive.org/web/20160420225147/http://pulse.ng/celebrities/ibinabo-fiberesima-newly-wed-actress-turns-year-older-id3404469.html. 
  2. Olanrewaju, Olamide (9 September 2009). "Ibinabo Fiberesima:"My previous relationships didn't work because I wasn't patient enough"- AGN President, covers Genevieve Magazine". Pulse Nigeria. http://pulse.ng/fashion/ibinabo-fiberesima-my-previous-relationships-didnt-work-because-i-wasnt-patient-enough-agn-president-covers-genevieve-magazine-id3336012.html. 
  3. "Biography/Profile/History Of Nollywood Actress Ibinabo Fiberesima". Daily Mail Nigeria. 12 March 2016. Archived from the original on 22 January 2017. https://web.archive.org/web/20170122232712/http://dailymail.com.ng/biographyprofilehistory-nollywood-actress-ibinabo-fiberesima/. 
  4. "Incredible Lives of Ex-Beauty Queens". The Nigerian Voice. 17 April 2010. http://thenigerianvoice.com/news/19630/6/incredible-lives-of-ex-beauty-queens.html. Retrieved 8 June 2016. 
  5. "I Am A Destiny Child, Says Ibinabo Fiberesima". The Newswriter. 11 October 2012. http://www.thenewswriterng.com/?p=5147. Retrieved 8 June 2016. 
  6. Alhassan (21 December 2013). "Nigeria: I Was Destined to Be an Entertainer - Ibinabo Fiberesima". Daily Trust Newspaper. http://allafrica.com/stories/201312220167.html. Retrieved 10 April 2016. 
  7. "Ibinabo Fiberesima prepares for Miss Earth Nigeria 2013". Nigeria Entertainment Today. 20 April 2013. http://thenet.ng/2013/04/ibinabo-fiberesima-prepares-for-miss-earth-nigeria-2013/. 
  8. ""I have been drained and to some extent humiliated" Read Ibinabo Fiberesima's Story on her Journey so far". BellaNaija. 19 March 2016. http://www.bellanaija.com/2016/03/i-have-been-drained-and-to-some-extent-humiliated-read-ibinabo-fiberesimas-story-on-her-journey-so-far/.