Ibiyinka A. Fuwape

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ibiyinka A. Fuwape
Ọjọ́ìbí18 Oṣù Kejìlá 1962 (1962-12-18) (ọmọ ọdún 61)
Occupation(s)Ọ̀mọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmò Físísì

Ibiyinka A. Fuwape (tí a bí ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1962) jẹ́ ọ̀mọ̀wé àti ọ̀jọ̀gbọ́n Físísì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Òun ni ẹni èkejì láti di adarí Yunifásitì Michael and Cecilia Ibru, Yunifásitì aládàáni kan ní Nàìjíríà.

Ìpìlẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Ibiyinka Fuwape ní ìpínlẹ̀ Èkó ní ọjọ́ kẹjọ oṣù Kejìlá ọdún 1962 sínú ìdílé David Ademokun.[1] Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Reagan Memorial Baptist Girls Primary School, Yaba, Ìpínlẹ̀ Èkó, ibẹ̀ ni ó ti parí ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.[2] Ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Methodist Girls High School níbi tí ó ti gba ìwé ẹrí O Level kí ó tó tẹ̀síwájú ní Queen's College Yaba láàrin ọdún 1979 to 1981.[2] Ní ọdún 1984, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Science (B.Sc.) nínú ìmọ̀ Físísì Yunifásítì ìlú Ìbàdàn[3] ó sì ṣin ilẹ̀ bàbá rẹ̀ láàrin ọdún 1984 sí 1985.[2] Ní Yunifásitì kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Master of Science (M.Sc.) ní[2] ọdún 1986 àti àmì ẹyẹ Dókítà(PhD) nínú ìmọ̀ Físísì ní ọdún 1989.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Office of the Vice Chancellor". vc.futa.edu.ng. Retrieved 2021-01-15. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 "The Vice-Chancellor – MCIU". www.mciu.edu.ng. Archived from the original on 2018-04-13.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "The Vice-Chancellor – MCIU" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 28 May 2018. Archived from the original on 2019-04-17. Retrieved 2019-04-17.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)