Jump to content

Instagram

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Instagram

Original author(s)Kevin Systrom, Mike Krieger
Developer(s)Facebook, Inc.
Initial releaseOṣù Kẹ̀wá 6, 2010; ọdún 13 sẹ́yìn (2010-10-06)
Operating systemiOS, Android, Windows
Size123.8 MB (iOS)[1]
40.76 MB (Android)
Available inEnglish, Croatian, Czech, Danish, Dutch, Finnish, French, German, Greek, Hindi, Hungarian, Indonesian, Italian, Japanese, Korean, Malay, Norwegian Bokmål, Polish, Portuguese, Romanian, Russian, Simplified Chinese, Slovak, Spanish, Swedish, Tagalog, Thai, Traditional Chinese, Turkish, Ukrainian and Vietnamese.
LicenseProprietary software with Terms of Use
WebsiteInstagram.com

Instagram tí wọ́n tún máa ń pè ní kúkúrú ní IG tàbí Insta[2]) jẹ́ ìkànnì ayélujára abánidọ́rẹ̀ẹ́ aláwòrán àti fídíò tí ilé iṣẹ́ Facebook ní tí ó gúnwà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà . Ọ̀gbẹ́ni Kevin Systrom àti Mike Krieger ní wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ lọ́dún 2010 kí ilé iṣẹ́ Facebook tó wà rà á lọ́wọ́ wọn. Orí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká tí ó ní èròjà ayélujára Áńdọ́rọ́ídì ní wọ́n tí máa ń lo Instagram. Àwòrán àti fídíò ni àwọn ènìyàn máa ń ṣáfihàn àti dọ́rẹ̀ẹ́ lé ní ìkànnì Instagram.[3] Instagram jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú àwọn ìkànnì ayélujára abánidọ́rẹ̀ẹ́ tí ó gbajúmọ̀ jùlọ. Àwọn ènìyàn jàǹkọ̀jàǹkọ̀, pàápàá jùlọ àwọn eléré ìdárayá, agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá, àwọn olórin ni wọ́n atẹ̀lé jùlọ lórí Instagram. Cristiano Ronaldo, gbajúmọ̀ ìlúmọ̀ọ́kà agbábọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ló ní atẹ̀lé jù ní Instagram. [4] [5]


Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]