Isioma Daniel

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Isioma Daniel
Ọjọ́ìbíIsioma Nkemdilim Nkiruka Daniel
1981
Nigeria
Ẹ̀kọ́journalism and politics at University of Central Lancashire
Iṣẹ́Newspaper journalist
Notable credit(s)Newspaper journalist whose column became the catalyst for religious violence in Nigeria, and who subsequently had to flee the country.

Isioma Nkemdilim Nkiruka Daniel (bíi ni 1981) jẹ́ oniroyin ọmọ Nàìjíríà. Ó fi èsì sì ìròyìn nípa Obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ni àgbáyé, èyí ló fà tí àwọn kí àwọn Mùsùlùmí fi sọ wípé kí wọn pá. Isioma lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga tí University of Central Lancashire níbi tí ó tí gboyè nínú ìròyìn àti òṣèlú ni ọdún 2001.[1][2] Ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìròyìn ni ThisDay tí ó ń ṣe ìwé ìròyìn jáde ní ìpínlè Èkó. Ní ọjọ́ kẹrin dínlógún oṣù kọkànlá ọdún 2002, ó fi èsì sì ìtàkò àwọn Mùsùlùmí nípa ìdíje obìnrin tí ó rẹwà jùlọ ni àgbáyé tí wọn fẹ ṣe ni ọdún yẹn.[3] Ó sọ wípé àwọn Mùsùlùmí sọ wípé kò dára kí wọn kó àwọn obìnrin méjìlélọ́gọ́run papọ̀ láti wo ẹni tí ó dára jù lọ, ó ní pe ká ní Mohammed wá láyé ní, ó má mú ìkan lára àwọn obìnrin náà fi ṣe aya. Ọ̀rọ̀ yi lọ fà ìjà ẹ̀ṣìn tí ó pá ẹ̀yán tó lè ní igbá,[4] tí àwọn ẹgbẹ̀rún eyàn sì farapa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn eyàn sì pàdánù ilé wọn.[5] Wọn dáná sì Ilé iṣẹ́ ThisDay ni ìpínlè Kaduna lẹ́yìn tí ilé iṣẹ́ náà tí bẹ̀bẹ̀.[6] Daniel fi ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn náà sílẹ̀ ni ọjọ́ kejì, ó sì lọ sí orílẹ̀ èdè Benin. Ní ọjọ́ kẹrindínlọ́gbọ́n oṣù kọkànlá ọdún 2002, ìjọba Mùsùlùmí sọ wípé kò sì ẹ̀sẹ̀ tí ẹnikẹ́ni bá pa Isioma Daniel. Igbá kejì gómìnà tí ìpínlè Zamfara, Mamuda Aliyu Shinkafi sọ wípé tí Mùsùlùmí kàn bá rí Isioma Daniel, pé kí wọn pá, pé iṣẹ́ ẹ̀ṣìn ni wọ́n ṣe pé kò sí ẹ̀sẹ̀ níbè. Ijoba Nàìjíríà sọ wípé ìdájọ́ naa ko ba òfin mu.[7] Akọwe àgbà tí Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs, Lateef Adegbite sọ wípé kí wọn má tẹ̀lé ìdájọ́ pé kí wọn pá Daniel, nítorí kò kín ṣe Mùsùlùmí, bẹẹni ilé iṣẹ́ igberoyin jáde náà tí bẹ̀bẹ̀.[8]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]