Lateef Adegbite

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Lateef Adegbite
Ọjọ́ìbí 20 Oṣù Kẹta 1933 (1933-03-20) (ọmọ ọdún 86)
Aláìsí 28 September 2012[1]
Orílẹ̀-èdè Nigerian

Lateef Adegbite. (Ojo ibi, ogunjo osu keta odun 1933. O si di oloogbe ni ojo kejidinlogbon osu kesan odun 2012). Nigba aye re, o je agbejoro kan ti o di Attorney gbogboogbo (Attorney General) ti apa iwo oorun ile Naijiria ki o to wa di akowe gbogboogbo ti igbimo giga fun amojuto oro Islam.

Ibi ati eto-ẹkọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Abdul-Lateef Oladimeji Adegbite ni a bi ni Ogunjo osu keta odun 1933 sinu ebi Musulumi Egba ti o muna ni ilu Abeokuta, Ipinle Ogun. Gege bi akosile kan, o lo si ile-iwe Methodist Abeokuta sugbon O so funrare pe O un koko lo si ile-eko Arabi lehinna ni O un wo ile-eko alakobere ti Paulu Mimo (St Paul) ni Igbore, Abeokuta ni odun 1942. Nigbati Adegbite di omo odun mesan ni O gba iwe-eko sikolashipu lati lo si ile-iwe giga ti Oba (King's College) ni Eko nibiti o ti je okanlara ajo oludasile ati aare orile akoko fun awujo akeko musulumi ti orile ede Naijiria. O pari ile-eko ni odun 1956.

Ni ọdun 1959, asaju ekun ti iwo oorun ni Naijiria, Oloye Obafemi Awolowo fun Adegbite ni sikolashipu kan lati rin irin-ajo lo si ilu geesi lati lo keeko gboye nipa ofin labe ero ti oloye FRA Williams. Adegbite lo si yunifasiti ti Southhampton, O si kawe gboye lori imo ofin ni osu keje odun 1962. Lehinna, O kawe ni ile-iwe giga ti ofin fun awon asoju , enubode Lancaster ni ilu London ati lehinna ni ile Grey's inn (1963-1965) O tun gba sikolashipu ti Commonwealth fun ikeko gboye oni pele keji ni ile geesi. O bere ise Oluko imo ofin ni yunifasiti ti eko ti O si di ipo yi mu titi ti O fi lo da ise adani tire sile ninu osu kesan odun 1976.

Ise Igbami[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni odun 1971 won yan Adegbite gege bi koomisoanna fun ijoba agbegbe ati ti oro oye ni ekun iwo oorun ti Nigeria lakoko ijoba ologun ti ogagun Christopher Oluwole Rotimi. Lehinna, won tun yan an gege bi koomisoanna fun idajo ati Attorney-Gbogboogbo ti ekun iwo oorun ni odun 1973. Ni osu kewa odun 1976, O se idasile ajo ile-ise ofin ti Lateef Adegbite ti O un funrare si je olori alajosepo eyi ti ofiisi akoko won wa ni Eko ati eka kan ni Abeokuta. Ofin owo ati ajo (Commercial and Corporate Law ) ni o je pataki ise won. Eka ofiisi ti Abeokuta wa ni Ago-Oba. Adegbite je okan lara awon ti won da egbe amuludu ti Abeokuta sile ni odun 1972.

Adegbite je aare igbimo ti Olympic ti ile Nigeria lati odun 1972 si odun 1985. O je olori-asiwaju ati alaga ti igbimo isakoso Yunifasiti ti Maiduguri lati odun 1984 si odun 1990. O di omo egbe igbimo alase igbimo okoowo ti ipinle Eko. Lehinna O di oga agba ti ise ati iseduro. Won fi oye alakoso ti o ga julo ni ile Nigeria(Commander of the order of the Niger (CON)) da Adegbite lola. O tun je awon oye ibile bi i seriki ti ile Egba ati Baba Adini ti Musulumi Egba. Ni ojo kesan osu keta odun 2011, Aare Goodluck Jonathan yan an gege bi alaga igbimo lori akosile imo lori aabo ati ati ojuse abele (Chairman, Presidential Committee on Public Awareness on Security and Civic Responsibilities) .

Dokita Lateef Adegbite je arakunrin si oloogbe olokiki ati ogbontarigi akaitan ojogbon Saburi Biobaku (1918-2001), eni ti o ti je giwa Yunifasity ti Eko tele.

Olori Musulumi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ni ijo constituent ni odun1976, Adegbite jiyan nipase ojurere pe ki won se agbekale ile ejo apetunpe ti Islam si awon Ipinle ti o wa ni gusu ile Nigeria. O so wipe awon Musulumi ni eto lati pe ki a se idajo won ni ibamu si ofin Sharia. O se e lalaye pe "Awon Musulumi ko ni ofin ati ilana miran yato si eyi ti Sharia ti gbe kale. Sharia gege bi ofin mimo yori ju gbogbo ofin ilu ati ti ihuwasi lo."Adegbite fe se atilehin fun akitiyan M.K.O. Abiola lati se agbekale Sharia si awon Ipinle gusu ni ibere awon odun 1990. O tun fi ipo yii mule ni osu kejila odun 2002 ni akoko ariyanjiyan ti o gbooro larin awon kristiani ati awon musulumi. Adegbite je alaga igbimo awon arinrin ajo mimo ni Ipinle Ogun ati omo egbe igbimo awon arinrin ajo ti orile. Nigbati Ibrahim Dasuki di Sultan ti Sokoto ni odun 1988 ati Aare-Gbogboogbo fun igbimo giga ti Naijiria fun oro Islam ni Naijiria (NSCIA), Adegbite ni won yan gege bi Akowe-Gbogboogbo fun igbimo naa. Labe akoso Adegbite ati Dasuki ni NSCIA, eyi ti won fi idi re mule ni odun 1974, di eyi ti o tun bo n sise pelu itara.

Ni ipari odun 2002 ati ibere odun 2003, Adegbite se ariyanjiyan ti gbogbo eniyan pelu onkowe gba ebun Nobel, Wole Soyinka, eni ti o fi esun kan awon oludari musulumi pe won ru iwa-ipa soke lehin rudurudu ti o sele ni ilu Kaduna ti o mu ki opolopo emi sofo. Ibere ote yi ni atako ti o waye lati odo awon Musulumi pe ki won se idaduro idije arewa Odobinrin Agbaye (Miss World) ni Naijiria. Rogbodiyan yi tun bo gberu si nitori o un ti awon musulumi ka si gege bi gbolohun odi ni iroyin ti oniroyin, Isioma Daniel ko sinu iwe iroyin ti kristiani kan pe ti o ba je wipe Woli ba lo si ibi isele arewa Odobinrin Agbaye yi ni, ko ba ti mu okan ninu awon oludije yi fi se iyawo. Lehinna ni won so wipe igbakeji gomina ti Ipinle Zamfara, Mamauda Aliyu Shinkafi so oro gbangba pe o le je ofin fun Musulumi lati ta eje Isioma Daniel sile. Lesekese ni Adegbite ti lodi si oro yi, niwon igbati akoroyin yi kii se Musulumi ati wipe iwe iroyin yi ti toro gafara ni gbangba.

Adegbite so ninu iwe iroyin article ti osu kewa odun 2003 pe ti won ba le yi ile America ati awon alajosepo re lokan pada lati gba pe gbogbo ipaya ti o nmule kakiri agbaye yio dinku ti idajo ododo ba le fi ese mule ni aarin ila-oorun. E fun awon ara Palestini ni ile won pada, ko si ni si aye fun Osama bin Ladens ti aye yi lati gberi. Lai si idajo ododo,ko le si alaafia. Nigba ti UNESCO se eto apero lori oro awonesin ni Abuja ni osu kejila odun 2003, won pe Adegbite lati soro lori ipa ti awon oludari esin nko lati dekun rogbodiyan.

Iku[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dokita Adegbite ku si ilu Eko ni ojo kejidinlogbon, osu kesan odun 2012.

  1. Adebowale, Yemi (20 March 1933). "Nigeria: Foremost Islamic Scholar Lateef Adegbite Dies at 79". allAfrica.com. Retrieved 29 September 2012.