King's College

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
King's College
Address
Ojúlé kẹta ní Catholic Mission
Ìlú Èkó, Nàìjíríà
Information
Type Ilé è́kọ́ ti ìpínlẹ̀
Motto Spero Lucem
Established 20 Oṣù Kẹ̀sán 1909 (1909-09-20)
Principal Anthony Oluseyi Thomas
Grades JS1–SS3
Gender Àwọn ọkùnrin
Student:teacher ratio 15:1
Slogan Old school, new thinking
Website
Kings College, Lagos1

King's College, Lagos jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n dáa síle\̣ ní ọjọ́ ogún oṣù kẹsán ọdún 1909 pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ́ mẹ́wá ní Erékùṣù Èkó, lẹ́gbẹ́ Tafawa Balewa Square. Ìlé ẹ̀kọ́ yìí maa ń gba ọkùnrin nìkan, bíótilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn obìnrin díẹ̀díẹ̀ wà lára wọn (A Level) àwọn akẹ́kọ HSC kí wọ́n tó dá  Queen's College Lagos, sílẹ̀ tí a mọ̀ sí kọ́lẹ́jì obìrin. Báyìí, àwọn akẹ́kọ náà maa ń bá àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe ìdánwò  West African School-Leaving Certificate àti National Examinations Council.

Ìtàn nípa rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kings College, Lagos3

Ní ọdún  1908, alákóso ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Henry Rawlingson Carr gba Gómìnà Walter Egerton ní ìyànjú lórí ètò ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[1] Ìyànjú Carr àti àwọn ìmòràn rẹ̀ ní ó jẹ́ kí wọ́n dá King's College sílẹ̀. Carr jẹ́ kí àwọn London Board of Education ri wípé dídá ilé ìwé yìí sílẹ̀ maa mú ìtẹ̀síwájú bá ètò wọ́n nípa ẹ̀kọ́ ní àwùjọ.[1] Fún ìdí èyí, àwọn olùkọ̀wé kan maa ń pe Henry Carr ní "atukọ̀ King's College".[2][3] 

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]