Jump to content

Iyọ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Iyọ̀

Iyọ̀ jẹ́ àlùmọ́ọ́nì afáralókun tó jẹ́ àkópò sódíọ́mù oníkilorínì tó ṣé pàtàkì fún ìgbádún ẹranko, ṣùgbọ́n tí ó lè léwu nígbà míràn fún ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gbìn orílẹ̀. Iyọ̀ wà lára àwọn nǹkan tí wón ń fi sí oúnjẹ kí ó le dùn, èyí mú kí iyọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn ń lò jù láti mú kí oúnjẹ dùn. Ìdáyọ̀bò ni ọ̀nà tí a ń lò láti fi oúnjẹ pamọ́.

Iyọ̀ ti ènìyàn ń jẹ le wá láti oríṣiríṣi ọ̀nà: iyọ̀ àìmó (bi iyo okun), iyọ̀ mímọ (iyọ̀ oúnjẹ), àti iyọ̀ oníayodínì. A lè rí iyọ̀ láti inú omi òkun tàbí àwọn òkúta ilẹ̀.

Àwọn ioni inú iyọ̀ bi Kilorínì àti sódíọ́mù, ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè gbogbo ohun ẹ̀dá alààyè. Iyọ̀ ń kópa nínú àmójútó omi inú ara, bí ó tilè jẹ́ wípé jíjẹ iyọ̀ jù lé fa àìlera fún ara, ó le fa Ẹ̀jẹ̀ ríru[1].


  1. "Blood Pressure UK". Blood Pressure UK. Retrieved 2023-02-02.