Jùmọ̀kẹ́ Akíndélé
Jùmọ̀kẹ́ Akíndélé | |
---|---|
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015 | |
Constituency | Ẹkùn ìdìbò Òkìtì-pupa II tí Ìpínlẹ̀ Òndó |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Ìpínlẹ̀ Òndó Nàìjíríà |
Ọmọorílẹ̀-èdè | Ọmọ Naijii |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | People's Democratic Party |
Residence | Òkìtì pupa |
Occupation | Òṣèlú |
Jumoke Akindele jẹ́ agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ agbẹnusọ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Òndó.[1]
ìgbésí-ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Jùmọ̀kẹ́ ní ìlú Òkìtì-Pupa, ní Ìpínlẹ̀ Òndó lápá ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà.[2] Ó kàwé àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní St. John’s Primary School ní Òkìtì-pupa kí ó tó tẹ̀ síwájú ní St. Louis Girls Secondary School, Òndó fún ẹ̀kọ́ gíga àti ìwé-ẹ̀rí West Africa School Certificate in 1981.[3] Ó kàwé gboyè nínú ìmọ̀ òfin láti Ọbáfẹ́mi Awolọ́wọ̀, ní Ile Ife tí ó sìn ṣiṣẹ́ amọ̀fin fún ìgbà díẹ̀ kí ó tó di òṣèlú lọ́dún 2006.[4]
Ìṣèlú rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Jùmọ̀kẹ́ díje dípò ẹkùn ìdìbò Òkìtì-pupa II, ṣùgbọ́n kò wọlé.[5] Ó tún díje padà lọ́dún 2011, orí bá a ṣe é, ó sìn wọlé. Àsìkò yìí ló jẹ́ Agbẹnusọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Òndó.[6]Wọ́n yàn án ní Agbẹnusọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Òndó lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2015,lẹ́yìn ikú agbẹnusọ àná, Samuel Adesina tí ó kú lójijì.[7] Ó kọ̀wé fìpò náà sílẹ̀ lógúnjọ oṣù kẹta ọdún 2018.[8] Jùmọ̀kẹ́ ni obìnrin àkọ́kọ́ tí ó jẹ agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ìpínlẹ̀ Òndó.[9]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Kayode Alfred. "Jumoke Akindele calls the shots in Ondo Assembly". The Nation.
- ↑ Leadership Newspaper (27 May 2014). "Ondo House Of Assembly Elects First Female Speaker". Nigerian News from Leadership News.
- ↑ "Politics changed my style – Jumoke Akindele". The Punch - Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 2014-12-21. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ naijamayor. "Jumoke Akindele Emerges First Female Speaker Of Ondo House of Assembly". NIGERIA ENTERTAINMENT. Archived from the original on 2015-11-19. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "Jumoke Akindele Emerges First Female Speaker Of Ondo House of Assembly". Naij.com. Retrieved 21 April 2015.
- ↑ "Ondo Assembly Elects First Female Speaker, Articles - THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2015-04-22. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Yinka Oladoyinbo. "As ondo assembly gets first female speaker". tribune.com.ng.
- ↑ Oluwole, Josiah (20 March 2017). "Embattled Ondo Assembly speaker, Jumoke Akindele, resigns". Premium Times. Retrieved 22 June 2019.
- ↑ "Ondo: Speaker’s Election Settles Row over Mimiko’s Deputy, Articles - THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 22 April 2015. Retrieved 7 November 2020.