James Wilson Robertson

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:EngvarB


James Wilson Robertson

Fáìlì:James Wilson Robertson.jpeg
Portrait by Walter Bird, 1965
2nd Governor-General of Nigeria
In office
15 June 1955 – 16 November 1960
AsíwájúJohn Stuart Macpherson
Arọ́pòNnamdi Azikiwe
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1899-10-27)27 Oṣù Kẹ̀wá 1899
Broughty Ferry, Dundee, Scotland
Aláìsí23 September 1983(1983-09-23) (ọmọ ọdún 83)
United Kingdom
EducationMerchiston Castle School
Alma materBalliol College, Oxford
OccupationCivil servant
Military service
Branch/service British Army
Unit

Ẹni-ọwọ̀ James Wilson Robertson jẹ́ òṣìṣẹ́-ìjọba ọmọ orílẹ̀-èdè tí ó ṣojú ìjọba Bíríkò lórílẹ̀-èdè Nigeria láti ọdún 1955 sí 1960.

Ìgbésí-ayé rẹ̀ láti èwe àti ìkẹ́kọ̀ọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ìwé Merchiston Castle School ní ìlú Edinburgh àti Balliol College, Oxford. Ó ṣiṣẹ́ sin ìjọba Bìrìtìkó lẹ́kà tó ń mójú tó àwọn ológun, British Army pẹ̀lú ẹ̀ka ọmọ-ogun Gordon Highlanders àti Black Watch. Wọ́n dá a lọ́lá oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ - òfin, Doctor of Laws láti University of Leeds lọ́dún 1961.[1]

Iṣẹ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn Oxford, ó dara pọ̀ mọ́ iṣẹ́ òṣèlú Sudan, Sudan Political Service ní ọdún 1922 sí 1953, bẹ́ẹ̀ náà ó ṣiṣẹ́ ní àgbègbè ìṣèjọba Blue Nile, White Nile, Fung, àti Kordofan, bákan náà ó jẹ́ akọ̀wé ilé-ìṣẹ́ ìjọba láti ọdún 1945 sí 1953. Ní àkókò yìí ni Akọ̀wé-yànyàn àwọn orílẹ̀-èdè tí ìjọba Bìrìtìkó ń ṣàkóso, Ọ̀gbẹ́ni Oliver Lyttelton rán-an sí British Guiana lóṣù kìíní ọdún 1954 láti ṣe àkọsílẹ̀ ìjábọ̀ èsì Robertson Commission láti ṣe ìwádìí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ nígbà náà látàrí ìdìbò tí ó gbé ẹgbẹ́-òṣèlú People's Progressive Party, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn lásìkò náà pé wọ́n ti ń bá àwọn elétò ìṣèjọba aláṣepọ̀,Communist tí wọ́n ṣokùnfà fífagilé òfin fún ìgbà díẹ̀.[2][3][4]

Lẹ́yìn àṣeyọrí tó lóòrì tí ó ṣe, èyí ló mú wọn rán-an sí orílẹ̀-èdè Nigeria. Òun ni aṣojú ìjọba Bìrìtìkó, tí ó ṣojú Ààrẹ-bìnrin, Queen Elizabeth II ni Nigeria láti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹfà ọdún 1955 sí ọjọ́ kẹrìndínlógún, oṣù kọkànlá ọdún 1960.[5]

Mọ̀lẹ̀bí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àbúrò rẹ̀ ni Ian Robertson, Lord Robertson, tí ọmọ rẹ̀, Sally[6] fẹ́ Nick Kuenssberg Àdàkọ:P-n.[7] Ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Laura Kuenssberg jẹ́ oníròyìn.[8]. Ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ ni Anne Mueller.

Ìṣọ̀wọ́kọ̀wé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 1899 – 3 June 1931: James Wilson Robertson
  • 3 June 1931 – 1940: James Wilson Robertson MBE[9]
  • 1940–1941: His Excellency James Wilson Robertson MBE, Governor of Gerzira Province[10]
  • 1941 – 1 January 1948: James Wilson Robertson MBE
  • 1 January 1948 – 1 June 1953: Sir James Wilson Robertson KBE[11]
  • 1 June 1953 – 15 June 1955: Sir James Wilson Robertson KCMG, KBE[12]
  • 15 June 1955 – 1956: His Excellency Sir James Wilson Robertson KCMG, KBE, Governor-General and Commander-in-Chief, Federation of Nigeria
  • 1956 – 13 June 1957: His Excellency Sir James Wilson Robertson GCVO, KCMG, KBE, Governor-General and Commander-in-Chief, Federation of Nigeria
  • 13 June 1957 – 1 October 1960: His Excellency Sir James Wilson Robertson GCMG, GCVO, KBE, Governor-General and Commander-in-Chief, Federation of Nigeria[13]
  • 1 October – 16 November 1960: His Excellency Sir James Wilson Robertson GCMG, GCVO, KBE, Governor-General and Commander-in-Chief of the Independent Federation of Nigeria
  • 16 November 1960 – 1965: Sir James Wilson Robertson GCMG, GCVO, KBE
  • 1965–1983: Sir James Wilson Robertson KT, GCMG, GCVO, KBE

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]