Jump to content

Joan Onyemaechi Mrakpor

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Joan Oyemaechi Mrakpor
Senato ẹ̀kùn Aniocha South
In office
2007–2015
ConstituencyAniocha South
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí7 Oṣù Keje 1966 (1966-07-07) (ọmọ ọdún 58)
Delta, Nigeria
Ọmọorílẹ̀-èdèNigerian
Ẹgbẹ́ olóṣèlúPeople's Democratic Party (PDP)
(Àwọn) olólùfẹ́Peter Mrakpor
Àwọn ọmọ5
ResidenceNigeria
ProfessionTelevision Envagelist

Joan Onyemaechi Mrakpor (tí a bi ní ọjọ́ keje oṣù keje, ọdun 1966) je Ajihinrere Onigbagbo Kristieni àti olósèlú omo orile-ede Naijiria. Ó se asojú ekùn Aniocha North-Aniocha, South-Oshimili àti North-Oshimili South ní ilé ìgbìmò asojú ní odun 2015 labe egbé oselu People's Democratic Party(PDP). Ṣaaju kí wón tó diboyan sí ilé ìgbìmò asojú orílè-èdè, Onyemaechi ṣiṣẹ gẹgẹbi asoju Aniocha South ni House of Assembly ti ìpínlè Delta láti odun 2007 titi di odun 2015.[1]

Onyemaechi bẹ̀rẹ̀ èkó rè ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Ubulu ó sì gba ìwé ẹ̀rí àkọ́kọ́ ní ilé-ìwé náà ní 1976. O lọ si ile-iwe Itoshan Grammar ti ìlú Benin nibiti o ti gba Iwe-ẹri Sekondiri in 1982. Lẹhinna o tẹsiwaju ní Yunifasiti ti Jos, o gba àmì-èye Bachelor of Art(B.A) ni ọdun 1992. O tun gba ìwé-èrí giga Postgraduate (PgD) lati Ile-ẹkọ Iroyin(Nigerian Institute of Journalism) ti orílè-èdè Nàìjíríà léyìn odun meji. Laarin 2004 sí 2005, Onyemaechi tún kàwé si ní Ile-ẹkọ giga Thames Valley ati Ile-iwe Iṣowo ti Manchester, àwon mejeji wà ní UK [2]

A dibo yan sí ile igbimo asofin ti ipinle Delta ní odun 2007 lati soju agbegbe Aniocha South. A tún yan ni ọdun 2011 ati ni ọdun 2015 si ilé ìgbìmò asoju labe egbé oselu People's Democratic Party. Lọwọlọwọ, oun ṣoju Aniocha North-Aniocha South-Oshimili North-Oshimili South constituency.

Joan fé Peter Mrakpor, eni tó jé agbejoro àti Commissioner of Justice ti ipinle Delta.[3]

  1. "Joan Onyemaechi Mrakpor". Academic Influence. Retrieved 2022-05-27. 
  2. "MRAKPOR, Hon Joan Onyemaechi". Biographical Legacy and Research Foundation. 2017-10-18. Retrieved 2022-05-27. 
  3. "Ex-Delta State AG, Mrakpor Divorces Wife, Alleges Cruelty, Thuggery". Urhobo Today. 2021-08-11. Retrieved 2022-05-27.