John Cabess

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
John Cabess
Ọjọ́ìbí1640s tàbí 1650s
Aláìsí1722
Komenda
Orúkọ mírànJohn Kabes or John Cabes
Iṣẹ́Prominent merchant in Komenda

John Cabess (tí àwọn míràn ma ń kó bi John Kabes tàbí John Cabes) (c. 1640s – 1722) jẹ́ oníṣòwò ọmọ orílẹ̀ èdè Áfíríkà tí ó gbajúmọ̀ nígbà ayé rẹ̀, ìlú Komenda, ara àwọn ìlú ìjọba Eguafo, ni ó ti ṣòwò. Ó jẹ́ ọ̀rẹ́ orílẹ̀ èdè Britain, ó sì ń ta ọjà fún ilé iṣẹ́ Royal African Company. Gẹ́gẹ́ bi oníṣòwò, ó gbajúmọ̀ ní ìlú Komenda ní àwọn ọdún 1700s, ó kó ipa gbòógì ní ogun Komenda, ìdìde ìjọba Ashanti, ìtàn kálẹ̀ ìjọba Britain ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà, àti Atlantic slave trade. Ó fi ayé sílẹ̀ ní ọdún 1722.