John Okafo
John Okafor | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | John Okafor Enugu State |
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Orúkọ míràn | Mr. Ibu |
Iṣẹ́ | actor, comedian |
John Ikechukwu Okafor, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Mr. Ibu, jẹ́ gbajú-gbajà òṣèré sinimá àti aláwàdà ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Okafor jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèré apanilẹ́rín ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó múṣẹ́ rẹ̀ lọ́kùnkúndùn tí ìṣe rẹ̀ sì ma ń kún fún ìwà òmùgọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.[3]
Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Okafor jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Enugu ní ìjọba ìbílẹ̀ Nkanu West . Lẹ́yìn tí ó parí ilé-ẹ̀kó alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1974, ó lọ ń gbé pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ìlú Sápẹ́lẹ́ ní Ìpínlẹ̀ Delta lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀. Ó ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́pẹ̀pẹ́ láti lè fi tọ́jú ara rẹ̀ àti ẹbí rẹ̀. Ó kọ́ iṣẹ́ irun gígẹ̀, ó kọ́ iṣẹ́ fọ́tò yíyà , ó sì tún ṣiṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe kírétì ẹyin. Ó tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nígbà tí ó wọ ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́ni àwọn olùkọ́ ti Ìpínlẹ̀ Yola lẹ́yìn ẹ̀kọ́ girama. Àmọ́ ó fagilé ètò-ẹ̀kọ́ yí látàrí àìlówó tó. Ó tún wọ ilé-ẹ̀kọ́ Institute of Management and Technology (MIT) nígbà tí ó ní owó tí ó lè lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́.[4]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Okafor ti kópa nínú eré tí ó tó igba ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lára àwọn eré tí ó ti kópa ni: Mr.Ibu (2004), Mr.Ibu in London (2004), Police Recruit (2003), 9 Wives (2005), Ibu in Prison (2006) and Keziah (2007).[5][6][7]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Mr Ibu And The Magic Million Dollars". www.modernghana.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-09-15.
- ↑ "Nollywood star Mr Ibu reportedly suffers stroke". www.myjoyonline.com. Retrieved 2019-05-19.
- ↑ "Professionally, I am an IDIOT - Mr Ibu, Xclusive Interview". Xclusive.ng. 15 November 2015. Archived from the original on 14 November 2021. Retrieved 27 October 2020.
- ↑ Udeze, Chuka (2014-04-28). "John Okafor (Mr Ibu) Biography, Wife, Family, 10 Lesser Known Facts". BuzzNigeria - Famous People, Celebrity Bios, Updates and Trendy News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-07.
- ↑ ""Homosexualism is the biggest virus in Nollywood", John Okafor. By Osamudiamen Ogbonmwan". Modernghana.com. 12 November 2013.
- ↑ NF. "John Okafor: Biography, Career, Movies & More" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2019-05-19.
- ↑ "Most Popular Movies and TV Shows With John Okafor". IMDb. Retrieved 2020-05-07.