Jude Dibia
Jude Dibia (tí wọ́n bí ní 5 January 1975 ní Ìpínlẹ̀ Èkó, ní Nàìjíríà) jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1] Ní ọdún 2007, ó gba ẹ̀bù ti Ken Saro-Wiwa fún ìwé ìtàn-àròsọ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Unbridled.
Ètò-ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Dibia kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní Yunifásítì ìlú Ìbàdàn, ó sì gboyè B.A. nínú ẹ̀kọ́ Modern European Languages (German).
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìwé-ìtàn àròsọ Jude ni wọ́n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí i èyí tó jẹ mọ́ onígboyànínú àti àríyànjiyàn láti ọẃ àwọn òǹkàwé àti alárìíwísí ìwé náà káàkiri ilẹ̀ Africa. Walking with Shadows ni wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìwẹ́ ìtàn-àròsọ ilẹ̀ Nàìjíríà àkọ́kọ́ tó máa ní ọkùnrin tó jẹ́ géè nínú, tí ó sì tún jẹ́ olú-ẹ̀dá-ìtàn. Unbridled, náà, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àríwísí àti àríyànjiyàn; ó jẹ́ ìtàn tó dojú ìkà kọ àwọn tó ń fìyà jẹ obìnrin, tí ó ti ní ìrírí mọ̀lẹ́bí tí ń bánilòpọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjìyà lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin.[2]
Wọ́n ti ṣàfihàn àwọn ìtàn kékeré Dibia lórí ẹ̀rọ-ayélujára bí i AfricanWriter.com àti Halftribe.com. Ọ̀kan lára àwọn ìtàn kékeré rẹ̀ ni One World: tó jẹ́ àkójọpọ̀ ìtàn kékeré bí i ti Chimamanda Ngozi Adichie àti Jhumpa Lahiri.[3]
Ìtúpalẹ̀ àwọn ìwé Jude Dibia
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Sesan, Azeez Akinwumi. Sexuality, Morality and Identity Construction in Jude Dibia's Walking with Shadows. Ibadan Journal of English Studies 7 (2018): 453–468.
- Sotunsa, Ebunoluwa Mobolanle & Festus Alabi. The Portrayal of Homosexuality in Jude Dibia's Walking with Shadows. Ibadan Journal of English Studies 7 (2018):437-452.
Àtòjọ àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Winner for the 2007 Ken Saro-Wiwa Prize for Prose for Unbridled[4]
- Finalist for the 2007 Nigeria Prize for Literature award for Unbridled
Àwọn iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Onyeka Nwelue, "Interview: Walking Shadows with Jude Dibia" Archived 2014-02-03 at the Wayback Machine., Nigeria Village Square, 22 July 2006.
- ↑ "Constant Reader - Short Stories: "Among Strangers" by Jude Dibia Showing 1-4 of 4". www.goodreads.com. Retrieved 2022-08-09.
- ↑ 引越しするなら|アリさんマークの引越社の評判は? Archived 2017-09-20 at the Wayback Machine. (in Japanese)
- ↑ "Jude Dibia, Author at AfricanWriter.com". AfricanWriter.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-09.
- ↑ ""Love Holds Things Together": Jude Dibia | Sampsonia Way Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-05-27.