Jump to content

Katung Aduwak

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Katung Aduwak
Ọjọ́ìbíMarch 21, 1980
Zonkwa, Nàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaDigital Film Academy, New York
Iṣẹ́Olugbere-jade; Adari ere; Onkotan
Ìgbà iṣẹ́2006 - present
Gbajúmọ̀ fúnWinner of the Big Brother Nigeria premier edition
Olólùfẹ́Raven Taylor-Aduwak
Àwọn ọmọ1

Katung Aduwak tí wọ́n bí ní ọjọ́ kọkànlélógún oṣù Kẹta ọdún 1980 jẹ́ ẹni tí ó jáwé olúborí nínú ìdíje Big Brother Nigeria ní ọdún 2006.[1][2][3] Wọ́n bi ní ìlú Zonkwa, ní Ìpínlẹ̀ Kaduna, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà[4] Ó jẹ́ ònkọ̀tàn, olùgbéré-jáde àti olùdarí eré orí-ìtàgé.[2][5] as well as a graduate of Political Science.[6]Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ kan ní ilé-ẹ̀kọ́ okòwò "Harvard Africa Business School Forum", tí ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alámòójútó àgbà ní ilé-iṣẹ́ MTV Base, Ó tún jẹ́ adarí àgbà ní ilé-iṣẹ́ "VIACOM", ó sì tún jẹ́ adarí àgbà ní ilé-iṣẹ́ ìgbórinjáde ti Chocolate City. Òun ni aláṣẹ àti olùdarí ilé-iṣẹ́ One O Eight Media and African Partner for Campfire Media.[7]

Aduwak gba àmì-ẹ̀yẹ ti Michelle Dede àti Olisa Adibua gbé kalẹ̀ nígbà tí́ ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ní ọdún 2006 pẹ̀lú iye owó tí ó tó $100,000.[2] Lẹ́yìn ọdún mọ́kànlá, ó fi léde wípé láti gbégbá orókè nínú ìdíje báyí, àwọn olùkópa nílò ọgbọ́n àti ọpọlọ gidi.[8]

Lẹ́yìn ìdíje Big Brother Nigeria

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lẹ́yìn ìdíje, Aduwak gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè New York láti tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ Digital Film Academy, tí ó dara pọ̀ mọ́ ṣíṣe sinimá lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀.[2]

Gbígbé eré jáde rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Eré tí kò bá jẹ́ eré tí ó yẹ kị́ ó gbé Aduwak jáde ni Heaven's Hell.[7][9] Ọjọ́ tí wọ́n kéde wípé àwọn yóò gbé eré náà jáde jẹ́ ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kíní ọdún 2015,[10] àmó wọn kò gbé eré náà jáde títí di ọjọ̣́ Kẹwàá oṣù Karùn ún ọdún 2019. Aduwak darí eré kan tí ó ṣàfihàn rúkè rúdò ti ó ṣẹlẹ̀ láàrín àwọn ọmọ ilè Áfíríkà tí wọ́n tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà bákan náà àti àwọn ọmọ ilẹ̀ Àfíríríkà tí wọ̣́n ń gbé ní ìlú òkèrè gbogbo ní ọdún 2020 tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní Not Supposed to be Here.[11]

Aduwak ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Raven Taylor-Aduwak, wọ́n sì bí ọmọ ọkùnrin kan ní ọjọ́ Kẹtàlá oṣù Kẹrin ọdún 2018.[4][12]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Unwanted Guest (2011)
  • PUNEET!TV (2012)
  • When Love Happens (2014)[13]
  • Heaven's Hell (2019)
  • Not Supposed to Be Here (2020)

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Augoye, Jayne (April 14, 2018). "#BBNaija: Where are the 2006 housemates?". Premium Times. Retrieved October 5, 2020. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 Akinyoade, Akinwale (July 19, 2020). "BBNaija 2020: Past Winners And Where They Are Now". The Guardian. Archived from the original on October 9, 2020. Retrieved October 6, 2020. 
  3. Nwabuikwu, Onoshe (September 30, 2020). "As Laycon wins BBN lockdown, will he do better than Efe?". The Cable. Retrieved October 6, 2020. 
  4. 4.0 4.1 Bella, Adaobi (October 1, 2020). "Katung Aduwak The Winner Of The Big Brother Season One, 2006: Katung Aduwak Winner of BBNaija 2006". Azure Voice. Archived from the original on October 11, 2020. Retrieved October 6, 2020. 
  5. Christian, Eastwood (August 1, 2020). "BBNaija: Four winners and ten most popular housemates in 14 years". AB-TC news. Archived from the original on January 19, 2021. Retrieved October 6, 2020. 
  6. "Big Brother 1 Nigeria: Katung". World of Big Brother. Archived from the original on February 16, 2020. Retrieved October 6, 2020. 
  7. 7.0 7.1 Anazia, Daniel (May 11, 2019). "Katung Aduwak debut movie, Heaven's Hell in the cinemas". The Guardian. Archived from the original on October 9, 2020. Retrieved October 6, 2020. 
  8. "Why Big Brother Naija Was Created – Katung Aduwak". Sundiata Post. March 26, 2017. Retrieved October 6, 2020. 
  9. Udoh, Esther (May 9, 2013). "Interview: Katung on himself & Heaven's Hell". DStv. Archived from the original on December 30, 2014. Retrieved October 6, 2020.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  10. "FilmOne to open 2015 with Heavens Hell, Gone Too Far, The Department". The Sun Newspaper. December 28, 2014. Retrieved October 6, 2020. 
  11. Stein, Frankie (July 13, 2020). "Not Supposed to be Here". Film Daily. Archived from the original on November 30, 2021. Retrieved October 6, 2020. 
  12. "Katung Aduwak The Winner of the first Big Brother Naija Show welcomes son". Nigerian Pilot News. April 16, 2018. Archived from the original on January 28, 2020. Retrieved October 6, 2020. 
  13. "Katung Aduwak". Flixander. Archived from the original on June 7, 2022. Retrieved October 7, 2020.