Kayode Oyebode Adebowale
Kayode Adebowale | |
---|---|
13th Vice-Chancellor of the University of Ibadan | |
Lọ́wọ́lọ́wọ́ | |
Ó gun orí àga 14 October 2021 | |
Asíwájú | Abel Olayinka |
Deputy Vice-Chancellor of the University of Ibadan | |
In office June 2018 – October 2021 | |
Asíwájú | Emilolorun Ambrose Aiyelari |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Kayode Oyebode Esuoso 11 Oṣù Kínní 1962 |
Alma mater |
|
Profession | Industrial Chemist |
Website | sci.ui.edu.ng/content/koadebowale/content/koadebowale |
Káyọ̀dé Oyèbọ̀dé Adébọ̀wálé FRSC (tí a bí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kìíní ọdún 1962) jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àti onímọ̀ ìjìnlè sáyẹ́nsì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ó sì jẹ́ Gíwá kẹtàlá ilé ẹ̀kọ́ ti Yunifásitì Ìbàdàn[1]. Ní Oṣù Kẹwàá Ọdún 2021 o di Gíwá ti Yunifasiti Ibadan, [2] tí ó ti ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́bí igbákejì Gíwá (ìṣàkóso) ti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti Ìlú Ìbàdàn, àti díìnì ìmọ̀ ẹ̀kọ́ sáyẹ́nsì.
Ìgbà Èwe àti Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ kọkànlá oṣù kìíní ọdún 1962 ni wọ́n bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Káyọ̀dé Adébọ̀wálé ó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ògùn ní ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà . Ó gba oyè ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ St. Marks, Oke-Ijaga, Ìjẹ̀bú Igbó láàárín ọdún 1967 sí ọdún 1972 nígbà tí ó sì ká ilé ẹ̀kọ́ girama ní ilé ẹ̀kọ́ girama Ayédáadé, Ìkirè láàárín ọdún 1973 àti ọdún 1978. Ọdún 1984 ni ó gba B.Sc ní Kẹ́místrì ní Yunifasiti ti Ibadan ní ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n. Ó gba oyè másítáàsì ati Ph.D láti ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan náà ní ọdún 1986 àti ọdún 1991 lẹ́sẹsẹ. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùrànlọ́wọ́ Akẹ́kọ̀ọ́ ní Yunifásítì ti Ìbàdàn ó sì di ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀kọ́ kẹ́místrì ní ilé iṣẹ́ ní ọdún 2006.
Ìgbésí ayé Ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ó jẹ́ olùkọ́ nígbà kan ní Federal University of Technology. Ó jẹ́ Igbákejì Gíwá (Ìṣàkóso), Yunifásítì Ìbàdàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Adébọ̀wálé, MNI, FRSC, FAS, FAvH, FCSN, FSAN, FPIN ni Gíwá Yunifásítì Ìbàdàn kẹtàlá.
Ni Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlá Oṣù Kẹwàá Ọdún 2021, Alága Ìgbìmọ̀ àti Pro-Chancellor ti Yunifásítì Ìbàdàn, Olóyè Dr. John Odigie-Oyegun, kéde ìpinnu tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayode Adebowale gẹ́gẹ́ bí Gíwá kẹtàlá ti Yunifásitì Ìbàdàn.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "(BREAKING): Professor Adebowale Emerges New Vice Chancellor Of University Of Ibadan". https://tribuneonlineng.com/breaking-professor-adebowale-emerges-new-vice-chancellor-of-university-of-ibadan/.
- ↑ "Kayode Adebowale emerges new UI Vice Chancellor". https://punchng.com/breaking-kayode-adebowale-emerges-new-ui-vice-chancellor/.