Keira Hewatch

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Keira Hewatch
Ọjọ́ìbíKeira Hewatch
8 Oṣù Kọkànlá 1985 (1985-11-08) (ọmọ ọdún 38)
Calabar, Cross River, Nigeria.
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iṣẹ́Actress, Singer, Songwriter and Writer
Ìgbà iṣẹ́2009 - Present
Gbajúmọ̀ fúnPeace Nwosu in Lekki Wives

Keira Hewatch, (tí a bí ní 8 Oṣù Kọkànlá, Ọdún 1985) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, akọrin, àti ònkọ̀wé, tó gbajúmọ̀ fún ipa rẹ gẹ́gẹ́ bi 'Keche' nínu fíìmù Two Brides and a Baby, àti fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi 'Peace Nwosu' nínu eré tẹlifíṣọ̀nù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Lekki Wives.[1] Hewatch ti gba àmì ẹ̀yẹ Best of Nollywood (BON) ní ọdún 2011, ó sì tún ti rí yíyàn lẹ́ẹ̀mejì rìí fún àwọn àmì ẹ̀yẹ Golden Icon Academy Awards (GIAMA). .

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Keira ní Ìlú Calabar, Ìpínlẹ̀ Cross River. Elizabeth Hewatch tí n ṣe ìyá rẹ̀ jẹ́ olùkọ́ tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ajẹ́ṣẹ́ àjíyìnrere, èyí tó mú kí ìyá rẹ̀ máa dánìkan ṣe ẹ̀tọ́ lóri rẹ̀.[2] Nígbà tí iṣẹ́ gbé ìyá rẹ̀ lọ sí Ìlú MìnnàÌpínlẹ̀ Nígèr, ó mú Keira ọmọ ọdún mọ́kànlá náà dání pẹ̀lú rẹ̀. Keira àti àwọn ẹbí rẹ̀ padà kó lọ sí orílè-èdè Ghánà ní ọdún 2005, níbití ó ti forúkọsílẹ̀ ní ilé-ìwé gíga kan láti kẹ́kọ̀ọ́ ìṣàkóso Ìrìn-àjò àti Ìgbàlejò. Ní ọdún 2006 lẹ́yín ìparí ẹ̀kọ́ rẹ̀, Keira pinnu láti lépa ìrètí ọkàn rẹ̀ fún iṣẹ́ òṣèré ṣíṣe

Ó lo ọdún kan si ní orílẹ̀-èdè Ghánà ní ìgbìyànjú láti ráyè lágbo eré ìdárayá ti Ghánà ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipa tí ó rí nílò sísọ èdè ilẹ̀ Gháná. Ní ọdún 2007, ó padà sí Nàìjíríà láti tẹ̀síwájú lílépa ìrètí ọkàn rẹ̀ fún iṣẹ́ òṣèré ṣíṣe.[3]

Iṣẹ́ ìṣe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nígbà tí keira bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré rẹ̀ ní Nollywood, ọ̀pọ̀lọpọ̀ n ṣe àpèjúwe ìlànà ṣíṣe eré rẹ̀ láti jọ ti òṣèré akẹgbẹ́ rẹ̀ Mercy Johnson.[4][5] Àkọ́kọ́ ipa keira wáyé nínu eré tẹlifíṣọ̀nù Cross Roads tí Emeka Ossai ṣe. Ní ọdún 2010, ó kó ipa aṣáájú pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Desmomd Elliot nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Kajola,[6] eré tí Níyì Akínmọláyàn darí. Fíìmù náà kọ̀ láti rí ìtẹ́wọ́gbà ní agbo eré sinimá ti Nàìjíríà.

Ní ọdún 2011, ó tẹ̀síwájú láti kópa aṣáájú gẹ́gẹ́ bi 'Keche', nínu eré Two Brides and a Baby pẹ̀lú àjọṣepọ̀ OC Ukeje, Stella Damasus-Aboderin, Chelsea Eze àti Okey Uzoeshi. Ní ọdún 2012, wọ́n yàán fún àmì ẹỳẹ òṣèré tuntun tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ ti Golden Icon Academy Awards (GIAMA).[7]

Àkójọ àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún Fíìmù Ipa Àwọn àkọsílẹ̀
2010 Kajola Police Chief Yetunde with Desmond Elliot
2011 Two Brides and a Baby Ketche with Stella Damasus-Aboderin
2012 Lekki Wives Season 1 Peace Nwosu TV series with Kiki Omeili
2013 In The Music Ihuoma Ugu with Omawumi, Chelsea Eze
2013 Murder at Prime Suites Agent Hauwa Uthman with Joseph Benjamin (actor), Chelsea Eze
2013 Lies Men Tell Jackie with Uche Jombo, Desmond Elliot
2014 Lekki Wives Season 2 Peace Nwosu with Kiki Omeili
2014 After The Proposal Lisa with Uche Jombo
2014 The Perfect Plan Beatrice with Ini Edo, Joseph Benjamin (actor)
2014 Couples Game Lina Dike with Seun Akindele
2015 Lekki Wives Season 3 Peace Nwosu with Kiki Omeili
2015 In The Name of Trust Joy Omorogbe with IK Ogbonna, Deyemi Okanlawon

Fifty Kate

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "So Much More Drama as 'Lekki Wives' Returns with Season 3 - Watch the BTS!", Bellanaija.com, 2 February 2015. Retrieved on 4 January 2016.
  2. "Keira Hewatch: 5 Things You Probably Don't Know About 'Lekki Wives' Actress", Pulse.ng, 9 November 2015. Retrieved on 4 January 2016.
  3. "Why I'm still single - Keira Hewatch", Topcelebritiesng.com, Nigeria, 25 February 2015. Retrieved on 4 January 2016.
  4. "I am not like Mercy Johnson", Nigerianfilms.com, Nigeria, 2 December 2011. Retrieved on 4 January 2016.
  5. "Actress Keira Hewatch Opens Up on Controversial Story Involving Her and Mercy Johnson", Informationng.com, Nigeria, 20 October 2015. Retrieved on 4 January 2016.
  6. "So 2059! Nigerian Cinema goes Sci-Fi as futuristic movie KAJOLA gets set to premiere in July", Bellanaija.com, Nigeria, 29 June 2010. Retrieved on 4 January 2016.
  7. "My journey has been satisfying, frustrating… – Keira Hewatch", Vanguardngr.com, Nigeria, 14 March 2014. Retrieved on 4 January 2016.