Stella Damasus
Stella Damasus | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | 24 Oṣù Kẹrin 1978 Ilu Benin, Naijiria |
Iṣẹ́ | Osere, Akorin |
Website | www.stelladamasus.com |
Stella Damasus (tí a bí ní Oṣù Kẹẹ̀rin Ọjọ́ 24, Ọdún 1978) [1] jẹ́ òṣèré àti akọrin ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [2] Ó ti rí yíyàn fún Òṣèré tí ó dára jùlọ ní Ipa Aṣáájú níbi ayẹyẹ Africa Movie Academy Awards ní ọdún 2009. Ó gba àmì ẹ̀ye fún ti òṣèré tó dára jùlọ níbi ayẹyẹ Nigeria Entertainment Awards ní ọdún 2007.[3] Bákan náà, ní ọdún 2012 ó tún gba àmì ẹ̀yẹ fún òṣèré tí ó dára jùlọ fún ti fíìmù Two Brides àti A Baby níbi ayẹyẹ Golden Icons Academy Awards ní ìlú Houston, Texas .
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Stella Damasus ni a bí ní Ìlú Benin, Ìpínlẹ̀ Edó ní Nàìjíríà. Ó ní àwọn tẹ̀gbọ́ntàbúrò obìnrin mẹ́rin. Ó dàgbà ní Ìlú Benin níbití ó ti parí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ètò-ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.[4] Ní ọmọ ọdún 13, Stella kó lọ sí Asaba ní Ìpínlẹ̀ Dẹ́ltà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ níbití ó ti parí ẹ̀kọ́ mẹ́wa rẹ̀.[5]
Iṣẹ́ ìṣe
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Damasus bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi akọrin ní ìlú Èkó níbi tí ó ti n ṣe akọrin ní ilé ìṣiṣẹ́ Klink Studios tí ó jẹ́ ti Kingsley Ogoro. Níbẹ̀ ló ti dá sámúsámú gẹ́gẹ́ bi akọrin kí ó tó wá tẹ̀síwájú láti ṣe àwọn orin fún àwọn ìpólówó ọjà lóri rédíò áti tẹlifíṣọ̀nù ní ìlú Nàìjíríà ní àkókò náà.
Damasus jẹ́ akẹ́ẹ̀kọ́-gboyè níbi ìmọ̀ eré ìtàgé láti Yunifásitì ti Èkó. Ó kọ́kọ́ farahàn nínu fíìmù Abused ní ọdún 1992.[6] [7] Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbajúmọ̀ lẹ́hìn kíkópa nínu ẹ̀kejì fíìmù rẹ̀, Breaking Point láti ọwọ́ Emem Isong tí Francis Agu sì ṣe olùdarí rẹ̀. Fíìmù náà mú kí ìràwọ̀ rẹ̀ tàn ká gbogbo Nàìjíríà. Ní ọdún 2006, ó rí yíyàn fún àmì ẹ̀yẹ “òṣèrè tí ó dára jùlọ ní ipa Aṣáájú” níbi ayẹyẹ African Movie Academy Awards fún iṣẹ́ rẹ̀ nínu fíìmù "Behind closed doors". Ó tún rí yíyàn fún àmì ẹ̀yẹ “òṣèrè tí ó dára jùlọ ní ipa Aṣáájú” níbi ayẹyẹ African Movie Academy Awards bákan náà nípasẹ̀ kíkópa nínu fíìmù "Widow" ní ọdún 2008, àti ní ọdún 2009 nípasẹ̀ fíìmù "State of the Heart". Ó ti ṣàfihàn ní àwọn fíìmù tó lé ní Àádọ́rin, [8] ó sì ti jẹ́ olùdásílẹ̀ àjọ ti "I2radio" àti atọ́kùn ètò méjì kan tí n ṣe "undiluted with stella damasus" àti "when women praise."
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Adetu, Bayo (24 April 2012). "At 34, Stella Damasus Has No Regrets". http://pmnewsnigeria.com/2012/04/24/at-34-stella-damasus-has-no-regrets/. Retrieved 1 February 2013.
- ↑ Ayakoroma, Barclays Foubiri. Trends in Nollywood: A Study of Selected Genres UPCC book collections on Project MUSE. https://books.google.com/books?id=Ll66CAAAQBAJ&pg=PA92&dq=Stella+damasus+nigerian+actress+film&hl=en&sa=X&ved=0ahUKEwiE5-juxbDYAhVEKcAKHeRVBDsQ6AEIMTAE#v=onepage&q&f=false.
- ↑ "Nigeria Entertainment Awards 2007". Archived from the original on 24 October 2019. Retrieved 1 June 2017.
- ↑ "Biography at OnlineNigeria.com". Archived from the original on 5 October 2018. Retrieved 25 November 2009.
- ↑ Clifford, Igbo. "Stella Damasus Biography, Age, Early Life, Family, Education, Career, Net Worth And More". Information Guide Africa. Retrieved 2020-04-26.
- ↑ "Quick Fact: Stella Damasus first appeared in ‘Abused’ in 1992". http://thenet.ng/quick-fact-stella-damasus-first-appeared-in-abused-in-1992/.
- ↑ "Damasus-Aboderin's first movie". Archived from the original on 18 September 2009. Retrieved 25 November 2009. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "List of movies by Stella Damasus-Aboderin at the Internet Movie Database". Retrieved 25 November 2009.