Jump to content

King Ampaw

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
King Ampaw
Ọjọ́ìbí25 Oṣù Keje 1940 (1940-07-25) (ọmọ ọdún 84)
Kukurantumi, Eastern Region, Ghana
Orílẹ̀-èdèGhanaian
Ọmọ orílẹ̀-èdèGhanaian
Iléẹ̀kọ́ gígaHochschule für Fernsehen und Film München (HFF Munich)
Iṣẹ́Actor, filmmaker, producer
Ìgbà iṣẹ́1972–present
Notable workThey Call it Love (1972)

King Ampaw jẹ́ òṣèrẹ́kùnrin ti orílẹ̀-èdè Ghana, tí wọ́n bí ní Kukurantumi, èyí tí ó wà ní apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ Ghana. Ó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú fíìmù Cobra Verde (1987) èyí tó jùmọ̀ ṣàgbéjáde. Ó jùmọ̀ ṣe àgbéjáde fíìmù African Timber (1989), èyí tí Peter F. Bringmann jẹ́ olùdarí fún.[1] Ó ti ní ìyàwó pẹ̀lú ọmọ méjì.[2]

Wọ́n bí King Ampaw ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù keje ọdún 1940, ní ìlú Kukurantumi, èyí tí ó wà ní apá Ìlà-oòrùn ilẹ̀ Ghana. Ó lọ sí Academy of Film ní Potsdam, Germany ní ọdún 1965. Ní ọdún 1966, ó forúkọ sílẹ̀ láti lọ Academy of Music and Performing Arts ní Vienna, Austria àti Hochschule für Fernsehen und Film München, ní Germany (HFF Munich) láti ọdún 1967 wọ ọdún 1972, níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú Werner Herzog àti Wim Wenders. Ó kẹ́kọ̀ọ́ jáde gẹ́gẹ́ bí olùdarí fíìmù pẹ̀lú fíìmù rẹ̀ akọ́kọ́, tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ They Call it Love.

Nígbà tí ó padà sí ìlú Ghana, ó di olùdarí àgbà ní Ghana Broadcasting Corporation (GBC) láti ọdún 1979 wọ ọdún 1982 tí ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ láti lọ ṣe ìdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ tirẹ̀, ìyẹn Afro movies Ltd. King Ampaw kọ ìtàn, ṣiṣẹ́ olùdarí, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ṣe àgbéjáde àwọn fíìmù tirẹ̀, bíi Kukurantumi, Road to Accra (1983), Juju (1985) àti No Time to Die (2006).[3] Púpọ̀ nínú àwọn fíìmù rẹ̀ rí owó láti ṣàgbéjáde láti ilé-iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àjọ mìíràn bíi European Union àti Ìjọba ilẹ̀ Faransé.[4] Àwọn fíìmù rẹ̀ ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbóríyìn fún, tí ó sì ti gba ọ̀pọ̀ àmì-ẹ̀yẹ ní àgbáyé, bíi àmì-ẹ̀yẹ Film Critics Award fún Kukurantumi, Road to Accra ní FESPACO, Input Film Award fún JujuCzech Republic àti Talifa Film Festival Award ní Spain fún No Time to Die.

Òun ní aṣagbátẹrù fíìmù àkọ́kọ́ tó máa gba àmì-ẹ̀yẹ ní Africa Movie Academy Awards (AMAA) ní Nigeria. Ní NAFTI Film Lectures ti ọdún 2012, ó gba àmì-ẹ̀yẹ̀ fún ìlọ́wọ́sí rẹ̀ sí ilé-iṣẹ́ ìgbé-fíìmù-jáde àti ìfìbọ̀nú àṣà Ghana àti Germany pọ̀.[5] Bákan náà ni ó gba àmì-ẹ̀yẹ mìíràn: Lifetime Achievement Award ní ọdún 2013 ní Accra International Film Festival.[6] Ó jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ FEPACI (African Filmmakers’ Union), FESPACO, Ghana Academy of Film and Television Arts (GAFTA) àti Directors’ Guild of Ghana (DGG).

King Ampaw ń ṣiṣẹ́ lórí fíìmù "The Son and Sun of Africa", lọ́wọ́lọ́wọ́, èyí tó dá lórí ìgbésí-ayé Kwame Nkrumah, tí ó sì máa jẹ́ fíìmù tó ma ṣe kẹ́yì.

Àtòjọ àwọn fíìmù rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • They Call it Love (1972)[7]
  • Kukurantumi, Road to Accra (1983)[7]
  • Juju (Nana Akoto) (1985)[8]
  • No Time to Die (2006)[9]

Àtòjọ àwọn àmì-ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún, King Ampaw gba àmì-ẹ̀yẹ "Òṣèrẹ́kùnrin tó dára jù ní African Film Festival of Tarifa ẹlẹ́ẹ̀kẹrin ní Spain. Ní ọdún 2008, ó gba àmì-ẹ̀yẹ ńbi ayẹyẹ ìkogún ti "Pan-African Film and Arts Festival ní Georgia, Atlanta. Ó gba àmì-ẹ̀yẹ Film Critics Award fún Kukurantumi ní Fespaco ní Ouagadougou àti Input Film Award fún Nana AkotoCzechoslovakia. Òun náà ni ó jáwé olúborí láti gba àmì-ẹyẹ ní Africa Movie Academy Awards (AMAA), ní Nàìjíríà. Bákan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Lifetime Achievement Award ní Accra International Film Festival (AIFF) ní ọdún 2013.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "African Timber". www.african-archive.com. Retrieved 26 February 2015. 
  2. "African Film festival: New York". www.africanfilmny.org. Retrieved 26 February 2015. 
  3. "Ghana: King Ampaw to Premier "No Time to Die" in Atlanta". allafrica.com. Retrieved September 25, 2020. 
  4. "'No Time to Die' - King Ampaw's Latest Film". www.modernghana.com. Retrieved 26 February 2015. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  5. "Government votes GHc 2m for creative Industry". thechronicle.com.gh. Retrieved 26 February 2015. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  6. "King Ampaw receives lifetime achievement award". www.gbcghana.com. Retrieved 26 February 2015. 
  7. 7.0 7.1 "Filmmaker King Ampaw turns 80". www.graphic.com.gh. Retrieved September 25, 2020. 
  8. "King Ampaw Biography, Born 1987 among others". africanfilmny.org. Retrieved September 25, 2020. 
  9. "'No Time To Die' - King Ampaw's Latest Film". MyJoyOnline.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2007-01-27. Archived from the original on 2020-12-09. Retrieved 2020-08-07.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)