Jump to content

Kunqu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A scene from The Peony Pavilion

Kunqu (Àdàkọ:Zh), tí a tún mọ̀ sí Kunju (崑劇), K'un-ch'ü, Kun opera tàbí Kunqu Opera, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin ìbílẹ̀ ìgbàanì tí àwọn China. Ó jẹ́ ẹ̀yà orin ìbílẹ̀ China tí ó yà láti ara orin Kunshan, tí ó sìn wá di gbajúmọ̀ nínú àwọn eré-oníṣe tí àwọn China láti nǹkan bí i sẹ́ńtúrì 16 sí 18. Ẹ̀yà orin yìí ṣẹ̀ láti inú àṣà àwọn ẹ̀yà Wu. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn gbajúmọ̀ àṣà àjogúnbá tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí àjọ UNESCO láti ọdún 2001.[1] Bẹ́ẹ̀ náà, ìwé-ìròyìn iṣẹ́-ọ̀nà olóṣooṣù kan láti orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, TeRra Magazine gbà pé Kunqu jẹ́ ọ̀kan lára eré-oníṣe tó gbajúmọ̀ jùlọ.[2]

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gu Jian, allegedly a transmitter of the Kunshan music in the Yuan dynasty
A Kunqu performer's portrayal of Hu Sanniang

Ìṣọ̀wọ́ kọrin Kunqu ni wọ́n ṣàlàyé pé ó ṣẹ̀ wá láti ìran Ming láti ọwọ́ Ọ̀gbẹ́ni Wei Liang Fu láti etídò Taicang, ṣùgbọ́n tí wọ́n fi wé àwọn orin ẹ̀bá ìlú Kunshan.[3] Kíkọ orin Kunqu fẹ́ fara jọ àwọn orin eré-oníṣe China bí i Peking opera|, tí ó fara jọ orin Kunqu lọpọlọpọ. Ìdásílẹ̀ eré-oníṣe chuanqi, tí wọ́n sáàbà máa ń kọrin Kunqu sí ní wọ́n ṣàlàyé pé ó jẹ́ sáà kejì tí ó dára nínú eré-oníṣe tí àwọn ẹ̀yà China. Ní nǹkan bí i sẹ́ńtúrì mọ́kàndínlógún ni àwọn ẹlẹ́gbẹ́ orin Kunqu kò fi bẹ́ẹ̀ tà mọ́, tí òkìkí wọn sìn ń wálẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di sẹ́ńtúrì okòó, àwọn ìlúmọ̀ọ́ká afowóṣàánu kan tún bẹ̀rẹ̀ sí ní gbé orin Kunqu lárugẹ gẹ́gẹ́ bí eré-oníṣe tí wọ́n ń ṣe káàkiri, tí ìjọba Orílẹ̀-èdè China sìn ń ṣe ẹ̀dínwó rẹ̀ fún àwọn èrò-ìwòran. Bí àwọn orin ìbílẹ̀ yòókù, Kunqu náà ni ìfàsẹ́yìn pàápàá jùlọ ní àsìkò àtúnṣe àṣà ìbílẹ̀ àti lásìkò gbígbawèrè àṣà ìlẹ̀ òkèrè. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, orin Kunqu tún gbìnàyá ju ti àtẹyìnwá lọ nínú mìlẹ́níọ́nù tuntun. Lónìí, orin Kunqu jẹ́ gbajúmọ̀ orin àkọtà ní àwọn gbajúmọ̀ ìlú méje ni orílẹ̀ èdè China,àwọn ìlú náà ni: Beijing (Northern Kunqu Theater), Shanghai (Shanghai Kunqu Theater), Suzhou (Suzhou Kunqu Theater), Nanking (Jiangsu Province Kun Opera), Chenzhou (Hunan Kunqu Theater), Yongjia County/Wenzhou (Yongjia Kunqu Theater) àti Hangzhou (Zhejiang Province Kunqu Theater), bẹ́ẹ̀ náà ní Taipei. Bẹ́ẹ̀ náà wọ́n ń kọ ọ́ tà ní àwọn ìlú kéréje-kéréje mìíràn ní China àti òkè-òkun.

Àwọn eré-oníṣe mìíràn náà tún gbajúmọ̀ láyé òde òní nítorí wọ́n ń ṣe àmúlò orin Kunqu nínú eré wọn, lára wọn ni The Peony Pavilion àti The Peach Blossom Fan. Ní àfikún, púpọ̀ nínú àwọn gbajúmọ̀ ìwé eré-oníṣe àti ìwé ìtàn China bí i Romance of the Three Kingdoms, Water Margin àti Journey to the West ni wọ́n ti lò ó fún orin eré-oníṣe.

Lọ́dún 1919, àwọn gbajúmọ̀ olórin Kunqu Mei Lanfang àti Han Shichang rìnrìn àjò lọ sí Jápán láti lọ ṣeré. Bẹ́ẹ̀ náà ni nnkan bí àwọn ọdún 1930, Mei lọ kọrin Kunqu ní Amẹ́ríkà àti Russia, tọ̀yàyà tọ̀yàyà ni wọ́n sìn gbà á.[4]

Ohùn orin Kunqu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohùn orin tó dára jù lọ nínú àwọn ohun orin ìbílẹ̀ China

Lọ́dún 2006, Zhou Bing ṣe olóòtú àti adarí orin ìbílẹ̀ Kunqu. Bẹ́ẹ̀ náà, ó gba àmì ẹ̀yẹ ti Outstanding Documentary Award of 24th China TV Golden Eagle Awards; àti àmì ẹ̀yẹ ti Award of TV Art Features of 21st Starlight Award lọ́dún 2006.

Àwọn àṣàyàn orin Kunqu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn eléré-oníṣe Kunqu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn olorin Kunqu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kun Qu Opera". UNESCO Cultural Sector - Intangible Heritage.
  2. "Kunqu, The elegant entertainment for an Chinese Empress | TeRra Magazine" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-06-15. Archived from the original on 2021-03-05. Retrieved 2021-03-06. 
  3. according to Southern Lyrics Sung Correctly (南詞引正) by Wei Liangfu, a famous musician of the Ming Dynasty
  4. "Kunqu | Chinese theatre". Encyclopedia Britannica (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2021-05-06.