Lúwòó Gbàgídà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Lúwòó Gbàgídà jẹ́ Ọba obìnrin àti Ọọ̀ni akọ́kọ́ fún ìlú Ilé-Ifẹ̀ tí ó jẹ́ orírun gbogbo ọmọ kóòtù-oòjíire. [1]

Ìtàn rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lúwòó jẹ́ ẹni Abiyì, arẹwà, onímọ́-tótó àti akínkankú obìnrin. Gẹ́gẹ́ bí àjogúnbá àṣà àti ìṣe, àwọn Yorùbá gbà wípé ọmọ ọkùnrin níyì wọ́n sì tọ́ nípò àṣà ju obìnrin lọ ; nítorí wípé ọmọ obìnrin yóò relé ọkọ bópẹ́ bóyá, àmọ́ ọmọ ọkùnrin ni yóò jẹ́ òpómúléró tí kò sì níbì kan tí yóò filé baba rẹ̀ síléẹ̀ lọ. Ìtàn fi ye ni wípé Lúwòó jẹ́ ọmọ bíbí Ọ̀táátàá nínú agbolé ẹbí Ọba Owódé Okèréwé ní ìlú Ilé-Ifẹ̀. Ó fẹ́ Ọbalọ̀ràn ti Ìlú Ilode tí ó sì bí ọmọ kan ṣoṣo Adékọ́lá Telu tí ó jẹ́ Olúwòó ti Ìwó àkọ́kọ́ tí ó sì ta ìlú Ìwó dó.[2] Lúwòó ni obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò tẹ́rí gbadé gẹ́gẹ́bí Ọọ̀ni obìnrin àkọ́kọ́ lẹ́yìn iku Ọọ̀ni Gíẹ̀sí ní ònkà ẹ̀ẹ́ẹ́gbẹ̀fà ọdún, ìyẹn (1100 AD), tí Ọọ̀ni Lúmọ̀bí sì jẹ lẹ́yìn rẹ̀. Ònkà àwọn Ọba Ifẹ̀ to Lúwòó sí ipò kọkàndínlógún nínú àtò Ọba jíjẹ ní Ilé-Ifẹ̀.[3]

Àwọn ohun mánigbàgbé Lúwòó Gbàgídà[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lúwòó jẹ́ arẹwà obìnrin tí ó kórira ìdíọ̀tí òun ẹ̀gbin, èyí ni ó jẹ́ kí ó pọn ọ́n ní dandan fún gbogbo ọmọ ìlú láti ma tún àyíká àti agbègbè wọn ṣe kí ó lè dùn ún wò. Gbàgídà kórira láti ma rìn wàṣà wàṣà nílẹ̀ lásán, yálà nílé ni tàbí ní àjò. Èyí ni ó mu pàá láṣe kí wọ́n ma fọ́ ìkòkò sílẹ̀ kí ó lè ma rí ohun gbẹ́sẹ̀ lé gẹ́gẹ́ bí àwo àlẹ̀mọ́lẹ̀ ode òní. Gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí ọ̀daràn ni ó ma ń pàṣẹ fún kí wọ́n mọ Èkó kò kínwọ́n sì ma tòó ìkòkò náà sílẹ̀ káàkiri ìlú lẹ́yìn tí wọ́n bá fe tán gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbogbo ibi tí ó bá ń lọ. Àwọn akoko tí wọ́n fọ́nsílẹ̀ kiri Ààfin Ọọ̀ni igbá náà ni wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ̀ sí Àárín náà títí dòní. Iya tún sè fún wa pe gbogbo ènìyàn ni wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ tó fi mọ́ àwọn olóyè láàfin, nítorí wípé ó kórira iwà imẹ́lẹ́, tí ó sì kórira àwọn arúfin gbogbo. Wọ́n tún fi kun wípé kò fi àyè sílẹ̀ kí ẹnìkẹ́ni ónfìyà jẹ ẹrú, nítorí ibi kò jùbí. Àwọn àgbààgbà ìlú wòye wípé agbára rẹ̀ ti pọ̀jù, kò sì sẹ́ni tó lè fọwọ́ padà rẹ̀ lójúni wọ́n ṣe pinu láti má fi obìnrin jẹ Ọọ̀ni ti Ifẹ̀ mọ́ láé láé. Ìtàn àtẹnudẹ́nu àdáyébá ẹnu àwọn bàbá ńlá wa fo orúkọ Lúwòó Gbàgídà gẹ́gẹ́ bí Ọ̀ọ̀ni obìnrin.[4]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "The Ooni of Ife / Iwo ties relived as new Oluwo takes the crown". Vanguard News. 2015-12-26. Retrieved 2020-02-11. 
  2. "Queen Lúwo Gbàgìdá, the first and only female Ooni of Ife.". SwiftTalk Limited. 2019-09-27. Retrieved 2020-02-11. 
  3. Author (2016-08-05). "Luwo Gbagida – Channels Television". Channels Television – Breaking Nigerian News, Today's News & Headlines – Latest updates in Nigeria. Retrieved 2020-02-11. 
  4. "Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn". BBC News Yorùbá (in Èdè Latini). 2019-09-13. Retrieved 2020-02-11.