Jump to content

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Leyin odun meta

Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ohun t’ó bá gba ni lọ́jọ́ ogun

Òun l’ó yẹ ká wárí fún bíi gbanigbani

Ohun t’ó bá gba ni sìlẹ̀ lọ́jọ̀ ọ̀ràn

Òun ló yẹ ká sátọ̀ bíi olùgbèjà

Ṣéb’Olùfọ̀n ni kò jógun ó jà l’Ẹ́rìn

Ṣeb’Ájàlá Ṣàngó ni kò jógun ó kó Kòso

Àní ‘hun t’ó bá gba ni làá sin

Ṣùgbọ́n Òbìrí ayé ti yí bìrí

Ọmọ adáríhunrun ò níran olóore ...

Asiri alabosi

Àṣírí alábòsí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ là ń ṣèké

Ojo t’ó bá tọ́kọ́ rọ ni í pa ni

B’írọ́ bá fẹ́ k’ó máa báfẹ́fẹ́ siré

Òtìítọ́ ò ní gbé ‘ṣè t’ó sì dunra

Òtíìtọ́ kò ní sáré jù ‘gbín

Ibi t’írọ́ bá ṣubú sí l’òtíìtọ́ ó ti kì í mọ́lẹ̀

Ẹ má jẹ ń f’àkàwé gbàgbé alábòsí

Ẹ má jẹ ń sàròyé gbàgbé oníṣẹ́ ibi

Bàbá àlùsì tí mo fẹ sọ̀rọ̀ bá l’Obìnrin ti jàrábà

Wọn gba ṣòkòtò nídìí àgbààyà tán ...

Eyi fara, eyi foro

Èyí fàrà tọ̀hún fòró

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìran ajá kan kìí mọ baba t’ó bá wáyé

Ẹjọ́ ajá kọ́, ohun a dá májá ni

Ìran òbúkọ kì í m’ọkọ iyá rẹ̀

Itú ò lẹ́ṣẹ̀ rárá, kádàrá ìran wọn ni

Ọmọ adáríhunrun tí kò lólú ni wọn ń pè ní t’àlè

Baba alábẹ́ oró t’idìí Obìnrin jẹ lógún

B’óo bá ti r’ábo l’abẹ́ẹ̀ rẹ ń dide

Aya aláya lo wò lásán loò gbádùn

Ọjọ ọ̀kẹ́rẹ́ ti ń fọ epo...

Ìran ajá kan kì í mọ baba t’ó bá wáyé

Ẹjọ́ ajá kọ́, ohun a dá májá ni

Ìran òbúkọ kì í m’ọkọ ìyá rẹ̀

Itú ò lẹ́ṣẹ̀ ràrá, kádàrá ìran wọn ni

Ọmọ adáríhunrun tí kò lólú ni wọn ń pè ní t’àlè

Baba alábẹ́ oró t’ídìí Obìnrin jẹ lógún

B’óo bá ti r’ábo l’abẹ́ẹ̀ rẹ ń dide

Aye aláya lo wò lásán loò gbádùn

Ọjọ ọ̀kẹ́rẹ́ ti ń fọ epo

Epo rẹ̀ ò kún ‘kòkò kan ṣoṣo

Ọjọ́ t’ólógbò ti ń gbówùú arúgbó...

Akẹ́kọ̀ọ́ t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Yunifásítì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gbogbo ẹní ṣẹ̀ṣẹ̀ dé

Ẹ kú ewu odò láì fara b’omi

Ẹ kú oríire

Ẹ kú àjàyè tẹ́ẹ mọ̀ ọ́n jà

Àlááfíà kọ́ lẹ wà bí?

Ará le tàbí kò le?

Ṣ’ẹ́ṣin ń joko koro koro

Ṣé bàbà rẹ̀ ò yéé mì làbà làbà?

Ede Yorùbá ti t’ámòójútó

Nítorí afárá ìjọ́sí ti yí padà

Afárá sì ti d’okinni ...

Ọ̀gágun Múrítàlá dẹni àgbégbè

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mo dé ‘gbó mọláró

N ò róye ọba Aláró

Mo dé ‘gbó Màkẹfun

N ò róye Ọba Ẹlẹ́fun

Mo dé ‘gbó Màkosùn

N ò róye Ọba Afosùndárà.

Dọ̀dàani ni mo dé

Mo ní Múrítàlá ńkọ́

Ẹ jọ̀wọ̀, ẹ bá mi wọ́gàá àwa lọ

Ẹ bá ní wá Múrítàlá ọmọ Mọ̀nmọ́dù ...

Ọlátunjí Ọ́pédọ̀tun (2000), Àròfọ̀ Eléwì-odò Oníbonoje Press ISBN 978-145-069-X, oju-iwe 17-32.

Olatunji Opadotun

link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.