Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta
Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ohun t’ó bá gba ni lọ́jọ́ ogun
Òun l’ó yẹ ká wárí fún bíi gbanigbani
Ohun t’ó bá gba ni sìlẹ̀ lọ́jọ̀ ọ̀ràn
Òun ló yẹ ká sátọ̀ bíi olùgbèjà
Ṣéb’Olùfọ̀n ni kò jógun ó jà l’Ẹ́rìn
Ṣeb’Ájàlá Ṣàngó ni kò jógun ó kó Kòso
Àní ‘hun t’ó bá gba ni làá sin
Ṣùgbọ́n Òbìrí ayé ti yí bìrí
Ọmọ adáríhunrun ò níran olóore ...
Àṣírí alábòsí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ là ń ṣèké
Ojo t’ó bá tọ́kọ́ rọ ni í pa ni
B’írọ́ bá fẹ́ k’ó máa báfẹ́fẹ́ siré
Òtìítọ́ ò ní gbé ‘ṣè t’ó sì dunra
Òtíìtọ́ kò ní sáré jù ‘gbín
Ibi t’írọ́ bá ṣubú sí l’òtíìtọ́ ó ti kì í mọ́lẹ̀
Ẹ má jẹ ń f’àkàwé gbàgbé alábòsí
Ẹ má jẹ ń sàròyé gbàgbé oníṣẹ́ ibi
Bàbá àlùsì tí mo fẹ sọ̀rọ̀ bá l’Obìnrin ti jàrábà
Wọn gba ṣòkòtò nídìí àgbààyà tán ...
Èyí fàrà tọ̀hún fòró
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìran ajá kan kìí mọ baba t’ó bá wáyé
Ẹjọ́ ajá kọ́, ohun a dá májá ni
Ìran òbúkọ kì í m’ọkọ iyá rẹ̀
Itú ò lẹ́ṣẹ̀ rárá, kádàrá ìran wọn ni
Ọmọ adáríhunrun tí kò lólú ni wọn ń pè ní t’àlè
Baba alábẹ́ oró t’idìí Obìnrin jẹ lógún
B’óo bá ti r’ábo l’abẹ́ẹ̀ rẹ ń dide
Aya aláya lo wò lásán loò gbádùn
Ọjọ ọ̀kẹ́rẹ́ ti ń fọ epo...
Ọ̀sọ́ òdì.
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìran ajá kan kì í mọ baba t’ó bá wáyé
Ẹjọ́ ajá kọ́, ohun a dá májá ni
Ìran òbúkọ kì í m’ọkọ ìyá rẹ̀
Itú ò lẹ́ṣẹ̀ ràrá, kádàrá ìran wọn ni
Ọmọ adáríhunrun tí kò lólú ni wọn ń pè ní t’àlè
Baba alábẹ́ oró t’ídìí Obìnrin jẹ lógún
B’óo bá ti r’ábo l’abẹ́ẹ̀ rẹ ń dide
Aye aláya lo wò lásán loò gbádùn
Ọjọ ọ̀kẹ́rẹ́ ti ń fọ epo
Epo rẹ̀ ò kún ‘kòkò kan ṣoṣo
Ọjọ́ t’ólógbò ti ń gbówùú arúgbó...
Akẹ́kọ̀ọ́ t’ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Yunifásítì
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gbogbo ẹní ṣẹ̀ṣẹ̀ dé
Ẹ kú ewu odò láì fara b’omi
Ẹ kú oríire
Ẹ kú àjàyè tẹ́ẹ mọ̀ ọ́n jà
Àlááfíà kọ́ lẹ wà bí?
Ará le tàbí kò le?
Ṣ’ẹ́ṣin ń joko koro koro
Ṣé bàbà rẹ̀ ò yéé mì làbà làbà?
Ede Yorùbá ti t’ámòójútó
Nítorí afárá ìjọ́sí ti yí padà
Afárá sì ti d’okinni ...
Ọ̀gágun Múrítàlá dẹni àgbégbè
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mo dé ‘gbó mọláró
N ò róye ọba Aláró
Mo dé ‘gbó Màkẹfun
N ò róye Ọba Ẹlẹ́fun
Mo dé ‘gbó Màkosùn
N ò róye Ọba Afosùndárà.
Dọ̀dàani ni mo dé
Mo ní Múrítàlá ńkọ́
Ẹ jọ̀wọ̀, ẹ bá mi wọ́gàá àwa lọ
Ẹ bá ní wá Múrítàlá ọmọ Mọ̀nmọ́dù ...
Iwe ti a yewo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọlátunjí Ọ́pédọ̀tun (2000), Àròfọ̀ Eléwì-odò Oníbonoje Press ISBN 978-145-069-X, oju-iwe 17-32.
link title Archived 2007-08-07 at the Wayback Machine.