Jump to content

Ladapo Ademola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ladapo Ademola
Reign 1920–1962
Coronation 24 September 1920
Predecessor Oba Gbadebo I
Successor Oba Adesina Samuel Gbadebo II
Spouse Olori Tejumade Alakija Ademola, Lady Ademola
Issue
Omoba Sir Adetokunbo Ademola and Omoba Adenrele Ademola, amongst others
Father Oba Ademola I
Mother Olori Hannah Adeyombo Ademola
Born 1872
Abeokuta
Died December 27, 1962
Burial December 31, 1962

Ladapo Samuel Ademola KBE, CMG (1872-1962), tí a tún mọ̀ sí Ademola II (kejì), ni ó jẹ́ Aláké ti Abẹ́òkúta láti ọdún 1920 sí 1962. Ṣáájú kí a tó dé e ládé Aláké, Ọba Ademola wà nínú ètò Ẹgbẹ́ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ìjọba Ẹ̀gbá. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ Ẹ̀gbá, ó jẹ́ olórí olùkópa nínú ìjíròrò pẹ̀lú ìjọba amúnisìn ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní ọdún 1889 fún ẹ̀tọ́ láti ṣe òpópónà ọkọ̀ ojú irin tí ń gba Egbaland kọjá.[1]

  1. The Christmas number of the Nigerian Daily Times, 1932. (1932). Lagos, Nigeria: W.A. P. 8