Jump to content

Omo-Oba Adenrele Ademola

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Omo-Oba Adenrele Ademola

Princess Adenrele Ademola tàbí Omo-Oba Adenrele Ademola (tí a bí ní ọdún 1916) jẹ́ ọmọ-ọba kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti òṣìṣẹ́ ìlera.[1][2] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè gẹ́gẹ́ bíi nọ́ọ̀sì ní ìlú London ní ọdún 1930, ó sì ń ṣiṣẹ́ rẹ̀ lọ nígbà ogun àgbáyé kejì.[3] Wọ́n fi ṣe orí-ọ̀rọ̀ fún fíìmù àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́, Nurse Ademola, tí àwọn Colonial Film Unit ṣe àmọ́ tí wọn ò rí mọ́ báyìí.[4]

A bí Omo-Oba Adenrele Ademola ní ọjọ́ kejì, oṣù kìíní, ọdún 1916.[5] Òun ni ọmọ-ọba Ladapo Ademola, tó jẹ́ Alake ìlú Abeokuta.[1] Ó dé sí Britain ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù kẹfà, ọdún 1935, ó sì kọ́kọ́ dúró sí ilé-ìgbé West African Students’ Union's ní Camden Town. Ní ọdún 1937, ó lọ sí àpérò ọlọ́lá kan ní Britain pẹ̀lú bàbá àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Adetokunbo Ademola. Ó lọ sí ilé-ìwé kan ní Somerset fún ọdún méjì.

Àwòrán Ademola kan hàn nínú ìwé kan ní ọdún1942 nípa àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn lágbàáyé lórí BBC. George Pearson ṣe fíìmù kan nípa rẹ̀, ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní, Nurse Ademola, àmọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a ò ri mọ́.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 AFRICAN PRINCESS AS NURSE. British Journal of Nursing: With which is Incorporated the Nursing Record, Volume 86. 1938. p. 16. https://books.google.com/books?id=4RkNx48e6-kC&q=nurse+princess+adenrele+ademola. 
  2. Olufunmilayo Adebonojo; Badejo Oluremi Adebonojo (1990) (in Yoruba). Itan ido Ijebu (English translation: Ijebu History). John West Publications. p. 101. ISBN 9789781630804. Archived on June 20, 2011. Error: If you specify |archivedate=, you must also specify |archiveurl=. https://books.google.com/books?id=iRYkAQAAMAAJ&q=nurse+adenrele+ademola. 
  3. Leila Hawkins. "Nurse Ademola". Top 10 black British healthcare pioneers (Healthcare Global). BizClick Media Limited. Retrieved December 24, 2020. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. 4.0 4.1 Montaz Marché, African Princess in Guy’s: The story of Princess Adenrele Ademola, The National Archives, 13 May 2020. Accessed 14 December 2020.
  5. Stephen Bourne (2010). Mother Country: Britain's Black Community on the Home Front, 1939-45. History Press. pp. 19, 104. ISBN 978-0-7524-9681-8. https://books.google.com/books?id=XTM9AwAAQBAJ&pg=PT104.