Jump to content

Laide Bakare

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Laide Bakare
Ọjọ́ìbí7th October 1980
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iléẹ̀kọ́ gígaIfáfitì Ìbàdàn
Iṣẹ́òṣèré . olóòtú
Ìgbà iṣẹ́1999 - till present
Notable workJẹjẹrẹ

Laide Bakare tí wọ́n bí ní Ọjọ́ keje oṣù kẹwàá ọdún 1980 (7th October 1980) jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré, olóòtú àti oníṣòwò ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà. [1]


Ìgbà èwe àti aáyan ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ ṣáájú, Láídé Bákàrè jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní Nàìjíríà. Lẹ́yìn tí ó parí ẹ̀kọ́ gírámà rẹ̀, Ó kàwé gbàwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ Ìtàn àti ẹ̀kọ́ nípa ète (History and Strategic Studies) ní Ifáfitì ìjọba Àpapọ̀ tí ó wà ní ìlú Èkó. Bákan náà, ó kàwé gbàwé ẹ̀rí Dípólómà nínú ìmọ̀ iṣẹ́ Tíátà ní Ifáfitì Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Iṣẹ́ tíátà rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láídé bẹ̀rẹ̀ sí ní nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò nígbà tí àwọn oníṣẹ́ tíátà máa wá ń lo ilé ìtura bàbá rẹ̀ fún sinimá àgbéléwò. Bàbá rẹ̀ jẹ́ pàràkòyí oníṣòwò tí ó ní ilé-ìtura tó lẹ́wà. Láídé bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ sinimá àgbéléwò lọ́dún 1999 nígbà tí ó kópa nínú sinimá àgbéléwò kan tí Muka Ray kọ tí àkọ́lé rẹ̀ ń "Adéyẹmí". Lẹ́yìn ìgbà náà, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò tí ó ju àádọ́ta lọ.

Àtòjọ díè nínú àwọn sinimá-àgbéléwò tí ó ti kópa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Jẹjẹrẹ
  • Ẹnu Ọpẹ́ mi
  • Money Bag
  • Orí owó
  • Òkun ọmọ ìyá
  • Ọrẹ mẹta
  • Àṣírí owó [2]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Laide Bakare Biography: Age, Family & Pictures". 360dopes. 2018-07-10. Retrieved 2020-02-18. 
  2. [/laide-bakare-biography-profile-fabwoman/ "Laide Bakare Biography - Profile"] Check |url= value (help). FabWoman | News, Style, Living Content For The Nigerian Woman. 2018-10-08. Retrieved 2020-02-18.