Jump to content

Lamidi Adeyemi III

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lamidi Adeyemi III
Aláàfin ti Ọ̀yọ́; Ikú Bàbá Yèyé

Reign 18 Oṣù Kọkànlá 1970 – 22 Oṣù Kẹrin 2022
Coronation 18 Oṣù Kọkànlá 1970
Predecessor Gbadegesin Ladigbolu II
Successor Abimbola Owoade
Spouse
House Ọ̀rànmíyàn
Born 15 Oṣù Kẹ̀wá 1938
Ọ̀yọ́, Nàìjíríà
Died 22 Oṣù Kẹrin 2022 (ọmọ ọdún 83)
Adó-Èkìtì, Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Nàìjíríà
Religion Ìsìláàmù

Lamidi Olayiwola Adeyemi III (Lamidi_Olayiwola_Adeyemi_III.wav Gbọ́ ; 15 Oṣù Kẹ̀wá 1938 – 22 Oṣù Kẹrin 2022) jẹ́ Aláàfin, tàbí ọba aládé ti ìlú Yorùbá ti Ọ̀yọ́ àti arole tí ó lẹ́tọ̀ọ́ sí orí-ìtẹ́ ilẹ̀ Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ ti ìtàn.[1][2]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ìtàn ìdílé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Lámídì Ọláyíwọlá Àtàndá Adéyẹmí ní ọjọ́ kẹdógún Oṣù Kẹ̀wá ọdún 1938 (15 October 1938)[3] sínú Ilé Ọba Alowolodu (Alowolodu Royal House), àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ilé Ọ̀rànmíyàn fún Alhaji Kareem Adeniran Adeyemi (tí a bí ní 1871–1960), ẹni tí ó padà di Aláàfin ní ọdún 1945, àti Ibironke ti Epo-Gingin, ẹni tí ó wàjà nígbà tí ó ṣì wà ní kékeré. Wọ́n sọ pé bàbá rẹ̀ ní ìyàwó tó lé ní igba (200). Bàbá bàbá rẹ̀[4] ni Aláàfin Adeyemi I Alowolodu, ẹni tí ó jẹ ọba nígbà Ogun Kìrìjí, tí ó sì jẹ́ ọba tó dá dúró kẹyìn ní Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ ṣáájú ìmúnisìn gẹ̀ẹ́sì. Bàbá Aláàfin Adeyemi I, tí ó jẹ́ bàbá ńlá bàbá rẹ̀ ni Ọba Atiba Atobatele, ẹni tí ó tẹ Ọ̀yọ́ Tuntun (New Oyo) dó.[5] Bàbá Atiba, tí í ṣe bàbá ńláńlá bàbá rẹ̀, ni Aláàfin Abíọ́dún,[6] ó sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ tààrà látọ̀dọ̀ Ọ̀rànmíyàn, ẹni tó tẹ Ilẹ̀ Ọba Ọ̀yọ́ dó.

Bàbá Lámídì, Aláàfin Ọ̀yọ́ Ọba Adeyemi II Adeniran, ni wọ́n yọ lórí oyè tí wọ́n sì lé kúrò nínú ìlú ní ọdún 1954 nítorí pé ó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣèlú National Council of Nigerian Citizens (NCNC). Ó ti ní aáwọ̀ pẹ̀lú Bode Thomas, igbá-kejì adarí fún ẹgbẹ́ òṣèlú Action Group.[7]

Gẹ́gẹ́ bí agbasọ, Bode Thomas pariwo mọ́ ọn fún àìdìde láti kí i gẹ́gẹ́ bí alága NCNC nígbà ìpàdé òṣèlú kan níbi ayẹyẹ. Ọba Adeyemi II Adeniran, nítorí àbùkù yìí, dìde, ó sì sọ fún Bode Thomas pé kí ó lọ sí ilé kí ó lọ máa gbó bí ajá. Ní kété lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wújẹ̀ (coughing blood), ó sì kú nígbà tí ó ń rìn padà lọ sí ilé, tí ó kọ àwọn sàràkí rẹ̀ sílẹ̀. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Herbert Macaulay gbọ́ nípa àjálù yìí, pẹ̀lú Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, wọ́n fẹ̀sùn kan Ọba Adeyemi II pé ó fi oró pa Thomas, lẹ́yìn náà ni wọ́n lé e kúrò nínú ìjọba rẹ̀. Ó lo ìyókù ọjọ́ ayé rẹ̀ ní Èkó, níbi tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣì máa ń bẹ̀ ẹ́ wò títí tí ó fi wàjà ní ọdún 1960.

Lámídì Adéyẹmí gorí ìtẹ́ rọ́pò Aláàfin Gbadegesin Ladigbolu II ní ọdún 1970, nígbà àkóso gómìnà Kọ́nelì Robert Adeyinka Adebayo, lẹ́yìn òpin Ogun Abẹ́lé Nàìjíríà. Ní ọdún 1975, adarí orílẹ̀-èdè, Ọ̀gágun Murtala Ramat Muhammed fi Ọba Adéyẹmí kún àwọn aṣojú tó tẹ̀lé e lọ fún ìrìn-àjò Hajj. Ó jẹ́ gíwá (chancellor) fún Ilé-ìwé gíga Uthman dan Fodiyo University ní Sókótó láti ọdún 1980 títí di 1992. Ní ọdún 1990, Ààrẹ Ibrahim Babangida yàn án ní Amir-ul-Hajj gẹ́gẹ́ bí ìdánimọ̀ fún ìfarajìn rẹ̀ sí ìmúgbòòrò ẹ̀sìn Ìsìláàmù ní Nàìjíríà.[7] Ní ọdún 2021, Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn án gẹ́gẹ́ bí Gíwá (Chancellor) fún Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Maiduguri[8]

Ìdáwọ́lé rẹ̀ nínú ìṣèlú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún 2011 (3 May 2011), Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ó ń parí sáà rẹ̀, Adebayo Alao-Akala kéde pé Aláàfin Ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyemi III kì í ṣe Alága pípẹ́ mọ́ fún Ìgbìmọ̀ àwọn Ọba àti Ìjòyè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Ìjọba ìpínlẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fọwọ́sí òfin kan tí ó fi àyè gba yíyípo ipò alága láàárín Aláàfin àti àwọn abánidí-ìjọba rẹ̀ méjì, Olúbàdàn ti Ìbàdàn àti Sọ̀ún ti Ògbómọ̀ṣọ́. Wọ́n sọ pé ìgbésẹ̀ yìí, tí ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tí ó kún fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ People's Democratic Party (PDP) gbé kalẹ̀, jẹ́ ẹ̀san fún ìtìlẹ́yìn tí Ọba náà fún ẹgbẹ́ Action Congress of Nigeria (ACN) lásìkò ìdìbò Oṣù Kẹrin ọdún 2011. ACN ṣẹ́gun PDP pátápátá nínú ìdìbò yẹn.[9]

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ní Oṣù Kẹ̀sán ọdún 1984, ó sọ pé: "Ó yẹ kí a rí àwọn ọba aládé gẹ́gẹ́ bí àwòkẹ́kọ̀ọ́ pípé fún àṣà ìlú, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n tún jẹ́ àkójọpọ̀ ìfojúsùn àti ète orílẹ̀-èdè. Èyí kò mọ ní oní ti ìlànà láwùjọ nìkan fún ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìmúbágbọgba, ìdájọ́ òdodo àti ti ìjọba àwa-arawa; ṣùgbọ́n nínú ìmúra, ọ̀rọ̀ sísọ àti ìwùwà; kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké to pọn dandan tí ó sọ Nàìjíríà àti agbègbè rẹ̀ di ohun tí ó dáyàtọ̀."[10]

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó fẹ́ Ayaba Abibat Adeyemi, ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́ (Olorì).[11] Ó máa ń lọ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ pẹ̀lú rẹ̀ tàbí pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó kékeré méjìlá mìíràn tí ó fẹ́.

Àwọn ìyàwó rẹ̀ yòókù ni Ayaba Rahmat Adedayo Adeyemi, Ayaba Suliat Motunrayo Adeyemi, Ayaba Mujidat Adeyemi, Ayaba Rukayat Adeyemi, Ayaba Folashade Adeyemi, Ayaba Badirat Ajoke Adeyemi, Ayaba Memunat Omowunmi Adeyemi, Ayaba Omobolanle Adeyemi, Ayaba Moji Adeyemi, Ayaba Anuoluwapo Adeyemi, àti Ayaba Damilola Adeyemi.

Ó jẹ́ olólùfẹ́ eré ẹ̀ṣẹ́ kíkàn (boxing), gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ afẹ́ṣẹ́kàn ṣáájú kí ó tó gorí ìtẹ́ àwọn bàbá rẹ̀.[12]

Aláàfin wàjà[13] ní ẹni ọdún mẹ́talélọ́gọ́rin (83)[14] ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù Kẹrin ọdún 2022 (22 April 2022) ní ilé-ìwòsàn Afe Babalola University Teaching Hospital, Adó Èkìtì ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, lẹ́yìn ìṣòro àìsàn pùrọ́sítéètì (prostate enlargement) rẹ̀.[15][16][17] Ìjọba rẹ̀ tí ó ṣe fún ọdún mọ́kànléláàádọ́ta (51 years) ni ó pẹ́ jùlọ fún èyíkéyìí Aláàfin Ọ̀yọ́ nínú ìtàn àkọsílẹ̀ òde-òní.[18][16] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ àti ìròyìn káàkiri Nàìjíríà ni wọ́n kéde ikú rẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kejì, níbi tí wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ padà sí Ọ̀yọ́ fún ìbẹ̀rẹ̀ ètò rírú-ẹbọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú pípa ewúrẹ́ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ààfin, tí wọ́n ń pè ní Ojú Àbàtà, láti fi hàn pé ọba ti wàjà.[15] Ikú rẹ̀ ni ó jẹ́ ẹ̀kẹta fún àwọn ọba ńlá ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láàárín oṣù márùn-ún.[19][20][1] Wọ́n yan Abimbola Owoade tí wọ́n sì fọwọ́sí i gẹ́gẹ́ bí àrọ́pò rẹ̀.[21]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1 2 "The Life and Times of Oba Adeyemi - THISDAYLIVE" (in en). This Day. https://www.thisdaylive.com/index.php/2022/04/24/the-life-and-times-of-oba-adeyemi.
  2. ↑ Awosika, Tomisin (2022-04-25). "The Alaafin of Oyo Has 'Joined His Ancestors' Aged 83". The Republic (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-07-06.
  3. ↑ "Between Alaafin Adeniran Adeyemi II and Alaafin Lamidi Adeyemi III" (in en-US). Vanguard (Lagos, Nigeria). 20 October 2018. https://www.vanguardngr.com/2018/10/between-alaafin-adeniran-adeyemi-ii-and-alaafin-lamidi-adeyemi-iii/.
  4. ↑ Adebayo, Musliudeen (24 December 2017). "Alaafin presents Oyo monarch beaded crown 37 years after coronation [PHOTOS"] (in en-US). Daily Post (Lagos, Nigeria). https://dailypost.ng/2017/12/24/alaafin-presents-oyo-monarch-beaded-crown-37-years-coronation-photos/.
  5. ↑ Falola, Toyin (1999). Yoruba Gurus: Indigenous Production of Knowledge in Africa. Africa World Press. ISBN 9780865436992. https://books.google.com/books?id=aO8a3aqA0VkC&pg=PA66.
  6. ↑ "#FlashBack: The Shocking Story of How Alaafin Adeyemi II Adeniran, Was Dethroned & Banished from Oyo Kingdom by Obafemi Awolowo". 20 April 2017.
  7. 1 2 "Alaafin of Oyo Oba Lamidi Adeyemi Turns 70". The Nation (Nigeria). 3 November 2009. Retrieved 18 September 2011.
  8. ↑ "Ooni, Alaafin, Sultan named Chancellors of UNN, UNIMAID, UI as FG announces councils for 42 universities". Nigerian Tribune. 8 July 2021. https://tribuneonlineng.com/ooni-alaafin-sultan-named-chancellors-of-unn-unimaid-ui-as-fg-announces-councils-for-42-universities/.
  9. ↑ YINKA FABOWALE (8 May 2011). "Real reasons Akala sacked Alaafin". The Sun (Lagos, Nigeria). http://www.sunnewsonline.com/webpages/features/powergame/2011/may/08/powergame-may-08-2011-004.htm. Retrieved 18 September 2011.
  10. ↑ Reinwald, Brigitte (2001). Afrikanische Beziehungen, Netzwerke und Räume: African networks, exchange and spatial dynamics. LIT Verlag Münster. p. 271. ISBN 3-8258-5705-0. https://books.google.com/books?id=0b_MzqtMeBkC&pg=PA271.
  11. ↑ "See The Alaafin Of Oyo's First Wife, She's The Same Age As Her Husband". Information Nigeria. https://www.informationng.com/2016/01/see-alaafin-of-oyos-first-wife-shes-same-age-as-her-husband-photos.html. Retrieved 25 April 2020.
  12. ↑ "Alaafin of oyo fights for boxing title". Vanguard (Lagos, Nigeria). 15 October 2016. https://www.vanguardngr.com/2016/10/alaafin-oyo-fights-boxing-title/.
  13. ↑ "The death of Alaafin Adeyemi III and a glimpse into the old Oyo empire" (in en-US). The Informant247 (Kwara, Nigeria). 2022-04-29. https://theinformant247.com/the-death-of-alaafin-adeyemi-iii-and-a-glimpse-into-the-old-oyo-empire/.
  14. ↑ "BREAKING: Alaafin of Oyo, top Yoruba monarch dies at 83" (in en-US). The Informant247 (Kwara, Nigeria). 2022-04-23. https://theinformant247.com/breaking-alaafin-of-oyo-top-yoruba-monarch-dies-at-83/.
  15. 1 2 "How Alaafin of Oyo passed away, predicted source of death" (in en-GB). Premium Times. 2022-04-24. https://www.premiumtimesng.com/news/headlines/525493-how-alaafin-of-oyo-passed-away-predicted-source-of-death.html.
  16. 1 2 "Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, is dead" (in en-GB). Premium Times. 23 April 2022. https://www.premiumtimesng.com/news/headlines/525342-alaafin-of-oyo-oba-lamidi-adeyemi-is-dead.html.
  17. ↑ "Oba Adeyemi's passage like a dream, Obasanjo mourns" (in en-US). The Punch. 23 April 2022. https://punchng.com/oba-adeyemis-passage-like-a-dream-obasanjo-mourns/.
  18. ↑ "Just In: Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, joins ancestors at 83". Vanguard (Lagos, Nigeria). 23 April 2022. https://www.vanguardngr.com/2022/04/just-in-alaafin-of-oyo-oba-lamidi-adeyemi-joins-ancestors-at-83/./
  19. ↑ "Alaafin of Oyo death: Oba Lamidi Adeyemi die at di age of 83". BBC News Pidgin. 23 April 2022. https://www.bbc.com/pidgin/tori-61075915./
  20. ↑ "Alaafin Of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi, Is Dead". Channels Television. Retrieved 23 April 2022.
  21. ↑ "Prince Abimbola Owoade: Governor Seyi Makinde confam appointment of new Alaafin of Oyo". BBC News Pidgin. 2025-01-10. Retrieved 2025-01-10.

Àwọn ìjápọ̀ ìta

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]