Lateef Adedimeji
Lateef Adedimeji | |
---|---|
Adedimeji at AMAA 2021 | |
Ìbí | 1 Oṣù Kejì 1984 Isolo, Lagos State, Nigeria |
Iṣẹ́ |
|
(Àwọn) ìyàwó | Oyebade Adebimpe (m. 2021) |
Adetola Abdullateef Adedimeji Listen (wọ́n bí i ní February 1, 1984) ó jẹ́ ọmọ orílẹ́-èdè Nigerian òṣèré àti Agbéréjáde. [1][2] Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n mọ̀ ọ́n fún ipa gbòógì rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó kó nínú eré Yéwándé (Yewande Adekoya)'s ní ọdún 2013 èyí tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní Kudi Klepto bẹ́ẹ̀ ni ó ti kó ipa takuntakun nínú àwọn eré tí wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún (100) [3] Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ipa nínú eré orí ìtàgé àti àgbéléwò láti bí ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Òun ni ó jẹ́ aṣojú ìpolówó brand ambassador fún ilé iṣẹ́ Airtel àti Numatville Megacity.[4]
Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Lateef Adedimeji ní ọjọ́ kì-ín-ní, oṣù kejì, ọdún 1984 ni agbegbe kan tí wọ́n ń pè ní Isolo, Lagos State. Ó jẹ́ ọmọ Abeokuta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn Ogun State.[5]
Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lateef bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ire Akari Primary School, Isolo, Lagos State, bẹ́ẹ̀ ni ó lọ sí Ilamoye Grammar School Okota ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State fún ètò ẹ̀kọ́ girama. [1] Bẹ́ẹ̀ ni ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Onikan tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣeré orí ìtàgé. [1] Ẹ̀bùn ìkọ̀wé rẹ̀ àti bí a ṣe ń ṣeré orí ìtàgé gbèrú si lábẹ́ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba Non-governmental organization (NGO) èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ (Community Life Project). [1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Olabisi Onabanjo University, níbi tí ó ti gba oyè ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ bachelor's degree nínú Mass Communication.[6]
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Lateef Adedimeji bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa lórí ìtàgé láti ọdún 2007, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ijó jíjó, [1] tí ó sì tún lọ ilé ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́ nípa ijó jíjó. Ó jẹ́ òṣèré Actor tí ó ti kó ipa onírúurú lórí ìtàgé láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ṣùgbọ́n tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré ní ọdún 2007 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ Orisun TV. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi atọ́kùn ètò ní ilé iṣẹ́ agbóhùngbójìjí ti Orísun TV, orúkọ ètò tí ó máa ń ṣe nípa à ń ṣe eré orí ìtàgé ni Sábàbí. Ní ìgbà tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gírámà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti ń ṣe eré orí ìtàgé, àwọn àjọ kan tí wọn kì í ṣe ti ìjọba yàn án gẹ́gẹ́ bíi aṣojú àti olúdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àìsàn kògbóògùn HIV/AIDS èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń kó láti ara ìbálòpọ̀ akọ sí abo lọ́nà tí kò ní ìdáàbò bò. Iṣẹ́ Lateef Adedimeji ni láti kó ipa nínú eré tí ó máa dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ààrùn tí a le kó láti ara ìbálòpọ̀, àwọn ewu tó wà nínú kí á má tọ́jú ààrùn náà àti bí wọ́n ṣe le di ààrùn kògbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni ó tún kópa nínú jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn ó mọn ẹ̀tọ́ àti ojúṣe wọn lábẹ́ òfin. Lateef jẹ́ ẹnìkan tí ó tètè ṣe àwárí ara rẹ̀ nínú kíkópa nínú eré orí ìtàgé tí ó sì gbé ìgbésẹ̀ láti wọ ẹgbẹ́ àwọn òǹṣèré. Ó ti kó ipa onírúurú bẹ́ẹ̀ ni ó ti bá àwọn òṣèré jàǹkànjàǹkàn ṣe eré àgbéléwò papọ̀ láti ìgbà tí ó ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà. Ọ̀pọ̀ ni ó mọ̀ ọ́n fún ipa tí ó máa ń kó gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí omi ẹkún kò jìnnà sí lójú. Ní ọdún 2016, ó gba àmì ẹ̀yẹ 2016 Best of Nollywood Awards fún òṣèré tí ó léwájú jùlọ nínú eré Yorùbá. [7] In 2015, he was nominated for City People Entertainment Awards for the 2015 Most Promising Actor of the year. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn a tilẹ̀ máa ń pè é ní àbúrò òṣèré kùnrin n nì ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀dúnladé Adékọ́lá ṣùgbọ́n èyí tí kò rí bẹ̀. Ẹ̀bùn ìkọ̀wé tí ó ní ti mú un bá àjọ àgbáyé UNICEF dá iṣẹ́ papọ̀ rí. [8] He was awarded the face of Nollywood male[9] during the ENigeria Newspaper Night of Honour on 30 October 2021.
Ìgbésí ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọjọ́ kejìdínlógún, 18 December 2021, Adedimeji gbé akẹgbẹ́ rẹ̀ níyàwó, ẹni tí òun náà jẹ́ òṣèré eré orí ìtàgé, Oyebade Adebimpe pẹ̀lú ìgbéyàwó alárinrin. [10][11]
Àwọn eré tí ó ti kó ipa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Kudi Klepto (2015)
- Yeye Oge (2016)
- Once Upon a Time (2017)
- Ilu Ominira (2018)[12]
- Bipolar (Àmódí) (2018)
- Bina Baku (2019)
- Depth (2019)
- Koto (2019)
- Igi Aladi (2019)
- Adebimpe Omooba (2019)
- Sugar Rush (2019) as Kpala
- Olokiki Oru (2019)
- The New Patriots (2020) as Fred
- Rugudu (2020) as Chibuzor
- Veil (2020)
- Soole (2021) as Julius
- Beauty and the Beast (2021)
- Breaded Life (2021)[13] as Jugunu
- Dwindle (2021)[14] as Fuku
- Ayinla (2021)[15] as Ayinla
- Progressive Tailors Club (2021) as Saheed
- Love Castle (2021) as Chi Joshua
- A Naija Christmas (2021) as Tony Torpedo
- Prophetess (2021) as Ezekiel
- That One Time (2022)
- King of Thieves (2022 film) (2022) as Abegunde
- Order of Things (2022) as Larry
- Strangers (2022)[16]
- Romeo (2022) as Anjola
- Ojukoro (2022) as Bayo
- Ile Alayo (2022)[17]
- Different Strokes (2023) as Tade
- The Last Man Standing (2023)
- Jagun Jagun (2023) as Gbotija
- 5 Billion Reasons (2023) as Maximus
- Imade (2023) as Pastor
- She Must Be Obeyed (2023) as Bayo
- Hotel Labamba (2024)
- Anikulapo (Rise of Spectre) (2024) as Awolaran
- House of Ga'a (2024) as Lubu
- Lisabi: The Uprising (2024) as Lisabi Agbongbo Akala
Àmì ẹ̀yẹ àti ìfidánilọ́lá
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Award ceremony | Prize | Result | Ref |
---|---|---|---|---|
2014 | Odua Movie Awards | Best Actor | Gbàá | [18] |
2015 | Gbàá | |||
Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
City People Entertainment Awards | Most Promising Actor of the Year (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2016 | Best Supporting Actor Of The Year (Yoruba) | Gbàá | ||
Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2018 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Gbàá | [19] |
City People Movie Awards | Best Actor Of The Year (Yoruba) | Wọ́n pèé | ||
2019 | Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead Role (Yoruba) | Wọ́n pèé | [20] |
Best Supporting Actor (Yoruba) | Gbàá | |||
2020 | 2020 Best of Nollywood Awards | Best Actor in a Lead role –Yoruba | Wọ́n pèé | [21] |
2021 | Africa Movie Academy Awards | Best Actor in a Leading Role | Wọ́n pèé | [22] |
2022 | Hollywood and African Prestigious Awards (HAPA Awards) | Best Actor in Africa | Gbàá | [23] |
See also
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 The360reporters (18 July 2021). "Lateef Adedimeji Net Worth: Lateef Adedimeji Biography, Age, Career And Net Worth.". The360Report (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021.
- ↑ "Lateef Adedimeji: The more the fame, the more we need a lot of improvement". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-21. Retrieved 2022-07-17.
- ↑ Mbuthia, Mercy (1 February 2021). "Lateef Adedimeji biography: age, wife, children, net worth, songs". Legit.ng – Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021.
- ↑ "Biography and net worth of Lateef Adedimeji". Archived from the original on 7 October 2019. Retrieved 24 October 2024.
- ↑ Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; no text was provided for refs namedtheinfopro.com.ng
- ↑ "7 emerging Yoruba movie stars you need to know". Pulse.ng. 16 April 2019.
- ↑ "Lateef Adedimeji Biography". quopedia.blogspot.com.
- ↑ "Lateef Adedimeji Biography and Network 2019". theinfopro.com. Archived from the original on 6 October 2019. Retrieved 7 December 2019.
- ↑ "Premium Times – Nigeria leading newspaper for news, investigations" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021.
- ↑ "See photos from actor Lateef Adedimeji wedding wit colleague Adebimpe Oyebade". 18 December 2021.
- ↑ "Lateef Adedimeji clinches international award - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-02.
- ↑ "Movies Featuring Lateef Adedimeji". ibakatv.com. Archived from the original on 6 October 2019. Retrieved 24 October 2024.
- ↑ "New Nollywood comedy 'Breaded Life' hits cinemas" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 16 April 2021. Retrieved 20 April 2021.
- ↑ Nwogu, Precious (3 June 2021). "Check out the new teaser for Kayode Kasum & Dare Olaitan's 'Dwindle!'". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 10 June 2021.
- ↑ Nwogu, Precious (14 December 2020). "Tunde Kelani announces production of Ayinla Omowura biopic titled 'Ayinla'". Pulse Nigeria. Retrieved 12 May 2021.
- ↑ Nwogu, Precious 'Mamazeus' (2022-04-04). "Biodun Stephen's movie 'Strangers' based on true events set for April release". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-19.
- ↑ "Ile Alayo: Lateef Adedimeji leaves viewers amused in season 2". Vanguard News. July 17, 2022. Retrieved July 29, 2022.
- ↑ "Lateef Adedimeji: Biography, Career, Movies & More". 24 May 2018.
- ↑ Augoye, Jayne (10 December 2018). "BON Awards 2018: Tope Oshin, Tana Adelana win big" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 9 October 2021.
- ↑ Bada, Gbenga (15 December 2019). "BON Awards 2019: 'Gold Statue', Gabriel Afolayan win big at 11th edition". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 10 October 2021.
- ↑ "Behold hot steppers and winners at BON awards 2020". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 12 December 2020. Retrieved 11 October 2021.
- ↑ Banjo, Noah (29 October 2021). "FULL LIST: Ayinla, Omo Ghetto: The Saga bag multiple nominations at AMAA 2021". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 30 October 2021.
- ↑ Online, Tribune (June 7, 2022). "Nollywood actor Lateef Adedimeji bags international award". Tribune Online. Retrieved August 2, 2022.
- Pages with reference errors
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- Living people
- 1986 births
- Nigerian Muslims
- Nigerian male film actors
- Male actors from Abeokuta
- Male actors in Yoruba cinema
- Yoruba male actors
- 21st-century Nigerian male actors
- Olabisi Onabanjo University alumni
- Yoruba filmmakers
- Yoruba-language film directors
- Entertainers from Ogun State
- Nigerian film producers
- Nigerian media personalities