Jump to content

Lateef Adedimeji

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lateef Adedimeji
Adedimeji at AMAA 2021
Ìbí1 Oṣù Kejì 1984 (1984-02-01) (ọmọ ọdún 40)
Isolo, Lagos State, Nigeria
Iṣẹ́
  • Renowned Actor
  • filmmaker
(Àwọn) ìyàwó
Oyebade Adebimpe (m. 2021)

Adetola Abdullateef Adedimeji Yo-Adetola Abdulateef Adedimeji.ogg Listen (wọ́n bí i ní February 1, 1984) ó jẹ́ ọmọ orílẹ́-èdè Nigerian òṣèré àti Agbéréjáde. [1][2] Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni wọ́n mọ̀ ọ́n fún ipa gbòógì rẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó kó nínú eré Yéwándé (Yewande Adekoya)'s ní ọdún 2013 èyí tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní Kudi Klepto bẹ́ẹ̀ ni ó ti kó ipa takuntakun nínú àwọn eré tí wọ́n lé ní ọgọ́rùn-ún (100) [3] Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ipa nínú eré orí ìtàgé àti àgbéléwò láti bí ọdún mẹ́ẹ̀dógún. Òun ni ó jẹ́ aṣojú ìpolówó brand ambassador fún ilé iṣẹ́ Airtel àti Numatville Megacity.[4]

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Lateef Adedimeji ní ọjọ́ kì-ín-ní, oṣù kejì, ọdún 1984 ni agbegbe kan tí wọ́n ń pè ní Isolo, Lagos State. Ó jẹ́ ọmọ Abeokuta, ní Ìpínlẹ̀ Ògùn Ogun State.[5]

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lateef bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Ire Akari Primary School, Isolo, Lagos State, bẹ́ẹ̀ ni ó lọ sí Ilamoye Grammar School Okota ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State fún ètò ẹ̀kọ́ girama. [1] Bẹ́ẹ̀ ni ó kẹ́kọ̀ọ́ ní Onikan tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó Lagos State níbi tí ó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣeré orí ìtàgé. [1] Ẹ̀bùn ìkọ̀wé rẹ̀ àti bí a ṣe ń ṣeré orí ìtàgé gbèrú si lábẹ́ àjọ kan tí kìí ṣe ti ìjọba Non-governmental organization (NGO) èyí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ (Community Life Project). [1] Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ní ilé ẹ̀kọ́ Olabisi Onabanjo University, níbi tí ó ti gba oyè ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ bachelor's degree nínú Mass Communication.[6]

Lateef Adedimeji bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa lórí ìtàgé láti ọdún 2007, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ijó jíjó, [1] tí ó sì tún lọ ilé ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́ nípa ijó jíjó. Ó jẹ́ òṣèré Actor tí ó ti kó ipa onírúurú lórí ìtàgé láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ṣùgbọ́n tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe eré ní ọdún 2007 nígbà tí ó dara pọ̀ mọ́ Orisun TV. Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi atọ́kùn ètò ní ilé iṣẹ́ agbóhùngbójìjí ti Orísun TV, orúkọ ètò tí ó máa ń ṣe nípa à ń ṣe eré orí ìtàgé ni Sábàbí. Ní ìgbà tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gírámà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti ń ṣe eré orí ìtàgé, àwọn àjọ kan tí wọn kì í ṣe ti ìjọba yàn án gẹ́gẹ́ bíi aṣojú àti olúdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àìsàn kògbóògùn HIV/AIDS èyí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń kó láti ara ìbálòpọ̀ akọ sí abo lọ́nà tí kò ní ìdáàbò bò. Iṣẹ́ Lateef Adedimeji ni láti kó ipa nínú eré tí ó máa dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ààrùn tí a le kó láti ara ìbálòpọ̀, àwọn ewu tó wà nínú kí á má tọ́jú ààrùn náà àti bí wọ́n ṣe le di ààrùn kògbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni ó tún kópa nínú jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn ó mọn ẹ̀tọ́ àti ojúṣe wọn lábẹ́ òfin. Lateef jẹ́ ẹnìkan tí ó tètè ṣe àwárí ara rẹ̀ nínú kíkópa nínú eré orí ìtàgé tí ó sì gbé ìgbésẹ̀ láti wọ ẹgbẹ́ àwọn òǹṣèré. Ó ti kó ipa onírúurú bẹ́ẹ̀ ni ó ti bá àwọn òṣèré jàǹkànjàǹkàn ṣe eré àgbéléwò papọ̀ láti ìgbà tí ó ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn òṣèré tíátà. Ọ̀pọ̀ ni ó mọ̀ ọ́n fún ipa tí ó máa ń kó gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí omi ẹkún kò jìnnà sí lójú. Ní ọdún 2016, ó gba àmì ẹ̀yẹ 2016 Best of Nollywood Awards fún òṣèré tí ó léwájú jùlọ nínú eré Yorùbá. [7] In 2015, he was nominated for City People Entertainment Awards for the 2015 Most Promising Actor of the year. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn a tilẹ̀ máa ń pè é ní àbúrò òṣèré kùnrin n nì ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọ̀dúnladé Adékọ́lá ṣùgbọ́n èyí tí kò rí bẹ̀. Ẹ̀bùn ìkọ̀wé tí ó ní ti mú un bá àjọ àgbáyé UNICEF dá iṣẹ́ papọ̀ rí. [8] He was awarded the face of Nollywood male[9] during the ENigeria Newspaper Night of Honour on 30 October 2021.

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọjọ́ kejìdínlógún, 18 December 2021, Adedimeji gbé akẹgbẹ́ rẹ̀ níyàwó, ẹni tí òun náà jẹ́ òṣèré eré orí ìtàgé, Oyebade Adebimpe pẹ̀lú ìgbéyàwó alárinrin. [10][11]

Àwọn eré tí ó ti kó ipa

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àmì ẹ̀yẹ àti ìfidánilọ́lá

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Year Award ceremony Prize Result Ref
2014 Odua Movie Awards Best Actor Gbàá [18]
2015 Gbàá
Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead Role (Yoruba) Wọ́n pèé
City People Entertainment Awards Most Promising Actor of the Year (Yoruba) Wọ́n pèé
2016 Best Supporting Actor Of The Year (Yoruba) Gbàá
Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead Role (Yoruba) Wọ́n pèé
2018 Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead Role (Yoruba) Gbàá [19]
City People Movie Awards Best Actor Of The Year (Yoruba) Wọ́n pèé
2019 Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead Role (Yoruba) Wọ́n pèé [20]
Best Supporting Actor (Yoruba) Gbàá
2020 2020 Best of Nollywood Awards Best Actor in a Lead role –Yoruba Wọ́n pèé [21]
2021 Africa Movie Academy Awards Best Actor in a Leading Role Wọ́n pèé [22]
2022 Hollywood and African Prestigious Awards (HAPA Awards) Best Actor in Africa Gbàá [23]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 The360reporters (18 July 2021). "Lateef Adedimeji Net Worth: Lateef Adedimeji Biography, Age, Career And Net Worth.". The360Report (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021. 
  2. "Lateef Adedimeji: The more the fame, the more we need a lot of improvement". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2022-05-21. Retrieved 2022-07-17. 
  3. Mbuthia, Mercy (1 February 2021). "Lateef Adedimeji biography: age, wife, children, net worth, songs". Legit.ng – Nigeria news. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021. 
  4. "Biography and net worth of Lateef Adedimeji". Archived from the original on 7 October 2019. Retrieved 24 October 2024. 
  5. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named theinfopro.com.ng
  6. "7 emerging Yoruba movie stars you need to know". Pulse.ng. 16 April 2019. 
  7. "Lateef Adedimeji Biography". quopedia.blogspot.com. 
  8. "Lateef Adedimeji Biography and Network 2019". theinfopro.com. Archived from the original on 6 October 2019. Retrieved 7 December 2019. 
  9. "Premium Times – Nigeria leading newspaper for news, investigations" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 20 November 2021. 
  10. "See photos from actor Lateef Adedimeji wedding wit colleague Adebimpe Oyebade". 18 December 2021. 
  11. "Lateef Adedimeji clinches international award - P.M. News" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-08-02. 
  12. "Movies Featuring Lateef Adedimeji". ibakatv.com. Archived from the original on 6 October 2019. Retrieved 24 October 2024. 
  13. "New Nollywood comedy 'Breaded Life' hits cinemas" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 16 April 2021. Retrieved 20 April 2021. 
  14. Nwogu, Precious (3 June 2021). "Check out the new teaser for Kayode Kasum & Dare Olaitan's 'Dwindle!'". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 10 June 2021. 
  15. Nwogu, Precious (14 December 2020). "Tunde Kelani announces production of Ayinla Omowura biopic titled 'Ayinla'". Pulse Nigeria. Retrieved 12 May 2021. 
  16. Nwogu, Precious 'Mamazeus' (2022-04-04). "Biodun Stephen's movie 'Strangers' based on true events set for April release". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-19. 
  17. "Ile Alayo: Lateef Adedimeji leaves viewers amused in season 2". Vanguard News. July 17, 2022. Retrieved July 29, 2022. 
  18. "Lateef Adedimeji: Biography, Career, Movies & More". 24 May 2018. 
  19. Augoye, Jayne (10 December 2018). "BON Awards 2018: Tope Oshin, Tana Adelana win big" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 9 October 2021. 
  20. Bada, Gbenga (15 December 2019). "BON Awards 2019: 'Gold Statue', Gabriel Afolayan win big at 11th edition". Pulse Nigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 10 October 2021. 
  21. "Behold hot steppers and winners at BON awards 2020". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 12 December 2020. Retrieved 11 October 2021. 
  22. Banjo, Noah (29 October 2021). "FULL LIST: Ayinla, Omo Ghetto: The Saga bag multiple nominations at AMAA 2021". Punch Newspapers (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 30 October 2021. 
  23. Online, Tribune (June 7, 2022). "Nollywood actor Lateef Adedimeji bags international award". Tribune Online. Retrieved August 2, 2022. 

Àdàkọ:Authority control