Lauren Liebenberg
{Use dmy dates|date=February 2014}}
Lauren Liebenberg | |
---|---|
Ọjọ́ ìbí | 3 Oṣù Kẹjọ 1972[1] Zimbabwe |
Iṣẹ́ | Writer |
Ọmọ orílẹ̀-èdè | South African |
Notable works | The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam The West Rand Jive Cats Boxing Club Cry Baby |
Lauren Liebenberg (a bii ni ojo keta, osu ogun,odun 1972) jẹ́ òǹkọ̀we omo orile ede South Africa tí wọ́n bí sí Zimbabwe . Ìwe rẹ̀ àkọ́kọ́ ti akori re n jeThe Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam gba àmi ìdánimọ̀ ti Orange Prize for Fiction ní ọduń 2008.[2] Àwọn ìwé re tí ó kọ lẹ́yin ti akoko rẹ̀ ni;The West Rand Jive Cats Boxing Club àti Cry Baby, náà ni awon lameeto ti se agbeyewo re káàkiri àgbáyé.[citation needed]
Ìpìlẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Liebenberg ni Rhodesia sugbon gegebi omode láti kékeré ni ó ti fi ilu Zimbabwe silẹ lọ sí ilẹ olòmìnira ti South Africa; eléyìí tí wọ́n jọ pín ààlà . Ó lọ sí Brescia House; èyi tí ó jẹ́ ilé-eko ijo Aguda fún àwọn obìrin ni Johannesburg. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́-gboyè kín-ní ní University of South Africa, ó gbé ní orílẹ̀-ède England fún ọdún díẹ̀, kí ó tó padà sí South Africa, níbití ó ti kẹ́kọ̀ọ́-gboyè ní ilé-ìwe akọ́nilókòòwò ti University of the Witwatersrand níbití ó ti gba ìwe-ẹ̀ri masita digiri (MBA). Ó ṣiṣẹ́ ni ilé-ìfowopamọ́ adánilókòwo;tí ó sì ṣe àtẹ̀jáde ní ẹ̀ka ètò ìṣúná owó, àti ị̀we atọ́ka tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́The Electronic Financial Markets of the Future; tí ó ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọdún 2002. [3][4][5][6]
Ìwe rẹ̀ àkọ́kọ́ The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam tí ó jẹ́ lára ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọdé ní Rhodesia ni ́ àkókò Rhodesian Bush War, gba ìfiyèsí púpọ̀ láti ọ̀dọ àwọn lámèétọ́ nígbàti wọ́n ṣe àtẹ̀jáde rẹ̀ ní ọdún 2008. The Guardian ṣe àpèjúwe rẹ̀ ni "ayanilẹ́nu lóòtọ́ " tí ó sì tẹ̀síwájú láti sọ pé "Rhodesia súyọ bíi ilẹ̀ tútù ní ojú ènìyaǹ kúrò nínu ayé òórùn wá... gẹ́gẹ́ bíi ọkàn rírọ̀ ọmọdé... tí kìí dánilẹ́jọ́ ... aláìlágbèé-sọ́kàn, amúnibínú tị́ ó ṣe àjèjì ... tí ó múnilọ́kàn".[7]Financial Times ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi "ìwe kín-ní ajọmárò tí ó sọ nípa àìlègbèra-ẹni níjà ọdọ́mọdé Áfírikà ní ilẹ̀ aláwọ̀-funfun.The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam Archived 2011-09-01 at the Wayback Machine.
- ↑ Interview with Lauren Liebenberg by Amanda Patterson Archived 25 September 2010 at the Wayback Machine. Writers Write. 25 June 2008.
- ↑ "Novelist who faced trial in Turkey makes long list for Orange Prize", The Independent, 18 March 2008.
- ↑ Liebenberg, Lauren (2002) (in en-gb). The Electronic Financial Markets of the Future. doi:10.1057/9781403946065. ISBN 978-1-349-43314-8.
- ↑ An Evocative Debut from Lauren Liebenberg Archived 4 January 2011 at the Wayback Machine. Penguin. 7 April 2008
- ↑ The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam Orange Prize. Retrieved on 6 November 2010
- ↑ Lauren Liebenberg, author of The Voluptuous Delights of Peanut Butter and Jam, in conversation with Janet van Eeden Archived 27 September 2011 at the Wayback Machine. Litnet. 14 May 2008
- ↑ Danger in the veld The Guardian. 5 April 2008