Mariam Kaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mariam Kaba

Mariam Kaba (tí a bí ní 9 Oṣù Kẹẹ̀jọ Ọdún 1961) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Fránsì àti Guinea.

Ìsẹ̀mí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Kaba ní ìlú Kankan, orílẹ̀-èdè Guinea. Ó jẹ́ ọmọbìnrin Mohamed Ba Kaba. Ó kó lọ sí orílẹ̀-èdè Fránsì ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980. Lẹ́hìn tí ó parí ẹ̀kọ́ girama rẹ̀, Kaba forúkọsílẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ École des nouveaux métiers de la communication ní àtẹ̀lé àṣẹ bàbá rẹ̀. Ó lọ ilé-ẹ̀kọ́ náà fún ọdún kan ṣoṣo, tó sì n lo owó tí bàbá rẹ̀ fi ránṣẹ́ si láti fi kẹ́kọ̀ọ́ eré ṣíṣe lábẹ́ olùkọ́ Isabelle Sadoyan.[1]

Àkọ́kọ́ ipa Kaba lóri ìpele wáyé gẹ́gẹ́ bi ìyàwó fún Toussaint Louverture, ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Benjamin Jules-Rosette, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí. Lẹ́hìn ìgbà náà, ó tún kó ipa kan nínu eré tẹlifíṣònù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Marc and Sophie. Ní ọdún 1989, Kaba kó àkọ́kọ́ ipa sinimá àgbéléwò rẹ̀ nínu fíìmù táa pe àkọ́lé rẹ̀ ní Périgord noir, èyí tí Nicolas Ribowski darí. Ó kópa gẹ́gẹ́ bi Maina nínu eré náà, ọ̀dọ́bìnrin kan tí ó n ṣiṣẹ́ ní agbègbè Périgord. Ní ọdún 1992, ó kó àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu sinimá àgbéléwò ti ilẹ̀ Áfíríkà, èyí tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Blanc d'ébène. Eré náà dá lóri Ogun Àgbáyé Ẹlẹ́ẹ̀kejì, tí olùdarí rẹ̀ sìì jẹ́ Cheik Doukouré, níbití òún ti kó ipa nọ́ọ̀sì kan tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú olùkọ́ni Lancéi Kanté. Kaba tún hàn nínu eré Idrissa Ouedraogo kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Samba Traoré ní ọdún 1992 bákan náà.[1] Ó tún bá Doukouré ṣiṣẹ́ pọ̀ lẹ́ẹ̀kansi ní ọdún 1994 nínu eré Le Ballon d'or.[2]

Kaba bí ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọdún 1999, ṣùgbọ́n ní ọdún 2000, Kaba tún hàn nínu eré gẹ́gẹ́ bi Pauline Lumumba, ìyàwó olóṣèlú Patrice Lumumba, nínu eré Raoul Peck kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Lumumba. Ó jà fún ipa náà nítorí wípé ó ní ìfẹ́ sí ìtàn-àkọọ́lẹ̀ náà.[3]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 1989 : Périgord noir
  • 1989 : Vanille Fraise
  • 1992 : Blanc d'ébène
  • 1992 : Samba Traoré
  • 1994 : Le Ballon d'or
  • 1995 : Pullman paradis
  • 1997 : Saraka bô
  • 1999 : Haut les cœurs!
  • 2000 : Lumumba
  • 2001 : Quand on sera grand
  • 2001 : Paris selon Moussa
  • 2005 : Africa Paradis Assembly
  • 2006 : Le Grand Appartement Oussamba
  • 2009 : La Journée de la jupe
  • 2010 : Turk's Head
  • 2011 : Un Pas en avant
  • 2011 : Polisse station
  • 2014 : Valentin Valentin
  • 2016 : The Wedding Ring
  • 2017 : Il a déjà tes yeux
  • 2018 : Vaurien

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 Diallo, Bios (12 January 2004). "Du théâtre à la réalité sociale" (in French). Jeune Afrique. https://www.jeuneafrique.com/114645/archives-thematique/du-th-tre-la-r-alit-sociale/. Retrieved 6 October 2020. 
  2. "Mariam Kaba, une femme de caractère". Clap Noir (in French). 5 January 2007. Retrieved 6 October 2020. 
  3. Ngoma, Hermione (11 January 2016). "Mariam Kaba : Lumumba fait partie de notre patrimoine.". Agence D'Information D'Afrique Centrale. http://www.adiac-congo.com/content/mariam-kaba-lumumba-fait-partie-de-notre-patrimoine-44207. Retrieved 6 October 2020. 

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]