Maryam Yahaya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Maryam Yahaya
Maryam Yahya
Ọjọ́ìbíMaryam Yahaya
17 Oṣù Keje 1997 (1997-07-17) (ọmọ ọdún 26)
Kano, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Òṣèré
Ìgbà iṣẹ́2016 - Present
Gbajúmọ̀ fúnHer appearance in Mansoor
Parent(s)Ibrahim bello (father), Rukayya bello (mother)

Maryam Yahaya jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó maá n ṣe àwọn eré Kannywood. Ó gbajúmọ̀ fún kíkópa rẹ̀ nínu fíìmù Taraddadi, tí elnass ajenda jẹ́ olùdarí.[1] Wọ́n yan Maryam Yahaya gẹ́gẹ́ bi òṣèré tí yóó gòkè àgbà lọ́jọwájú níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards ní ọdún 2017[2]. Ó tún rí yíyàn lẹ́ẹ̀kan si fún àmì ẹ̀yẹ ti òṣèré tí ó dára jùlọ níbi ayẹyẹ City People Entertainment Awards ti ọdún 2018.[3]

Iṣẹ́ ìṣe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Yahaya ti ní ìpinnu láti ìgbà èwe rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ òṣèré, nípasẹ̀ àwọn eré kannywood tí ó ti maá n wò nígbà tó wà lọ́mọdé. Ó ṣe àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu fíìmù tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Gidan Abinci, ṣáájú àwọn fíìmù míràn bi Barauniya àti Tabo níbi tí ó ti kó àwọn ipa kékéèké.[4] Ó di gbajúmọ̀ lẹ́yin kíkó ipa aṣáájú nínu eré tí àkọ́lé rẹ̀ jé Mansoor[5], fíìmù kan tí Ali Nuhu jẹ́ olùdarí rẹ.[6]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkọ́lé Ọdún
Gidan Abinci 2016
Barauniya 2016
Tabo 2017
Mijin Yarinya 2017
Mansoor 2017
Mariya 2018
Wutar Kara 2018
Jummai Ko Larai 2018
Matan Zamani 2018
Hafiz 2018
Gidan Kashe Awo 2018
Gurguwa 2018
Mujadala 2018
Sareenah 2019

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Ngbokai, Richard P. (20 July 2018). "Young artistes making waves in Kannywood". Daily Trust. Retrieved 2 August 2019. 
  2. Lere, Muhammad (9 October 2017). "Ali Nuhu, son win at City People Awards 2017 - Premium Times Nigeria". Premium Times. Premium Time Newspaper. Retrieved 2 August 2019. 
  3. "KANO & KADUNA Actors To Storm City People Movie Awards". City People Magazine. Citi people magazine. 28 August 2018. Retrieved 2 August 2019. 
  4. "Maryam Yahaya Biography: Age & Photos". 360dopes. 360dopes. 13 May 2018. Archived from the original on 23 July 2019. Retrieved 2 August 2019. 
  5. Matazu, Hafsah Abubakar (8 March 2019). "Kannywood’s 7 youngest stars". Daily Trust. Archived from the original on 2 August 2019. Retrieved 2 August 2019. 
  6. Ngbokai, Richard P. (20 July 2018). "Young artistes making waves in Kannywood". Daily Trust. Retrieved 2 August 2019.