Matilda Kerry
Ìrísí
Matilda Kerry jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó[1] àti asọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìmóhùn máwòrán, ó wà lára àwọn tí ó ń ṣe ètò The Doctors. Ó gbajúmọ̀ nígbà tí ó gba àmì-ẹ̀yẹ obìnrin tó rẹwà jù ní Nàìjíríà ní ọdún 2000.[2]
Ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kerry lọ ilé ìwé Federal Girls College, ti Benin, ibẹ̀ ni ó ti gba ìwé ẹrí WAEC rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó parí ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ndìrì rẹ̀, ó tẹ ẹ̀kọ́ rẹ̀ síwájú ní Yunifásítì ìlú Èkó láti kọ́ nípa ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Kerry kàwé gboyè ní Yunifásitì ìlú Èkó ní ọdún 2006 láti di Dókítà alábẹ́rẹ́. Òun ni Ààrẹ George Kerry Life foundation,[3] àjọ tí ó ń kọ́ àwọn ènìyàn nípa àwọn àìsàn tí kò sé kó ràn.[4][5]
Ó wà lára àwọn Young African Leaders Initiative, ètò tí ààrẹ Amerika tẹ́lẹ̀rí, Barack Obama dá kalẹ̀.
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Nigerian public health doctors - FamousFix.com list". FamousFix.com. Retrieved 2022-04-26.
- ↑ "Search | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-04-26.
- ↑ "Dr. Matilda Kerry | Docsays". www.docsays.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2017-08-29. Retrieved 2017-08-29.
- ↑ I am not conscious of fashion –Matilda Kerry Archived 2012-11-19 at the Wayback Machine.
- ↑ "GEORGE KERRY LIFE FOUNDATION". GEORGE KERRY LIFE FOUNDATION. Archived from the original on 2017-08-29. Retrieved 2017-08-29.